Psalms 104 (BOYCB)
1 Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi. OLÚWA Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ. 2 Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní, 3 ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́. 4 Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ. 5 O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;tí a kò le è mì láéláé. 6 Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá. 7 Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ. 8 wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn. 9 Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. 10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì;tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè. 11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omiàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn. 12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omiwọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka. 13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹàti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò,kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá. 15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,òróró láti mú ojú rẹ̀ tan,àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà. 16 Àwọn igi OLÚWA ni a bu omi rin dáradára,kedari ti Lebanoni tí ó gbìn. 17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọnbí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀. 18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro. 19 Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókòoòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀. 20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri. 21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọnwọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 22 Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ,wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn. 23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́. 24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, OLÚWA!Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ. 25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníyeohun alààyè tí tóbi àti kékeré. 26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀. 27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀. 28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,wọn yóò kó jọ;nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere. 29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́ara kò rọ̀ wọ́nnígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀. 30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,ni a dá wọn,ìwọ sì tún ojú ayé ṣe. 31 Jẹ́ kí ògo OLÚWA wà pẹ́ títí láé;kí inú OLÚWA kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀, 32 ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín. 33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí OLÚWA:èmi ó kọrin ìyìn sí OLÚWAníwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè. 34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùnbí mo ti ń yọ̀ nínú OLÚWA. 35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyékí ènìyàn búburú má sì sí mọ́. Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi. Yin OLÚWA.
In Other Versions
Psalms 104 in the ANGEFD
Psalms 104 in the ANTPNG2D
Psalms 104 in the AS21
Psalms 104 in the BAGH
Psalms 104 in the BBPNG
Psalms 104 in the BBT1E
Psalms 104 in the BDS
Psalms 104 in the BEV
Psalms 104 in the BHAD
Psalms 104 in the BIB
Psalms 104 in the BLPT
Psalms 104 in the BNT
Psalms 104 in the BNTABOOT
Psalms 104 in the BNTLV
Psalms 104 in the BOATCB
Psalms 104 in the BOATCB2
Psalms 104 in the BOBCV
Psalms 104 in the BOCNT
Psalms 104 in the BOECS
Psalms 104 in the BOGWICC
Psalms 104 in the BOHCB
Psalms 104 in the BOHCV
Psalms 104 in the BOHLNT
Psalms 104 in the BOHNTLTAL
Psalms 104 in the BOICB
Psalms 104 in the BOILNTAP
Psalms 104 in the BOITCV
Psalms 104 in the BOKCV
Psalms 104 in the BOKCV2
Psalms 104 in the BOKHWOG
Psalms 104 in the BOKSSV
Psalms 104 in the BOLCB
Psalms 104 in the BOLCB2
Psalms 104 in the BOMCV
Psalms 104 in the BONAV
Psalms 104 in the BONCB
Psalms 104 in the BONLT
Psalms 104 in the BONUT2
Psalms 104 in the BOPLNT
Psalms 104 in the BOSCB
Psalms 104 in the BOSNC
Psalms 104 in the BOTLNT
Psalms 104 in the BOVCB
Psalms 104 in the BPBB
Psalms 104 in the BPH
Psalms 104 in the BSB
Psalms 104 in the CCB
Psalms 104 in the CUV
Psalms 104 in the CUVS
Psalms 104 in the DBT
Psalms 104 in the DGDNT
Psalms 104 in the DHNT
Psalms 104 in the DNT
Psalms 104 in the ELBE
Psalms 104 in the EMTV
Psalms 104 in the ESV
Psalms 104 in the FBV
Psalms 104 in the FEB
Psalms 104 in the GGMNT
Psalms 104 in the GNT
Psalms 104 in the HARY
Psalms 104 in the HNT
Psalms 104 in the IRVA
Psalms 104 in the IRVB
Psalms 104 in the IRVG
Psalms 104 in the IRVH
Psalms 104 in the IRVK
Psalms 104 in the IRVM
Psalms 104 in the IRVM2
Psalms 104 in the IRVO
Psalms 104 in the IRVP
Psalms 104 in the IRVT
Psalms 104 in the IRVT2
Psalms 104 in the IRVU
Psalms 104 in the ISVN
Psalms 104 in the JSNT
Psalms 104 in the KAPI
Psalms 104 in the KBT1ETNIK
Psalms 104 in the KBV
Psalms 104 in the KJV
Psalms 104 in the KNFD
Psalms 104 in the LBA
Psalms 104 in the LBLA
Psalms 104 in the LNT
Psalms 104 in the LSV
Psalms 104 in the MAAL
Psalms 104 in the MBV
Psalms 104 in the MBV2
Psalms 104 in the MHNT
Psalms 104 in the MKNFD
Psalms 104 in the MNG
Psalms 104 in the MNT
Psalms 104 in the MNT2
Psalms 104 in the MRS1T
Psalms 104 in the NAA
Psalms 104 in the NASB
Psalms 104 in the NBLA
Psalms 104 in the NBS
Psalms 104 in the NBVTP
Psalms 104 in the NET2
Psalms 104 in the NIV11
Psalms 104 in the NNT
Psalms 104 in the NNT2
Psalms 104 in the NNT3
Psalms 104 in the PDDPT
Psalms 104 in the PFNT
Psalms 104 in the RMNT
Psalms 104 in the SBIAS
Psalms 104 in the SBIBS
Psalms 104 in the SBIBS2
Psalms 104 in the SBICS
Psalms 104 in the SBIDS
Psalms 104 in the SBIGS
Psalms 104 in the SBIHS
Psalms 104 in the SBIIS
Psalms 104 in the SBIIS2
Psalms 104 in the SBIIS3
Psalms 104 in the SBIKS
Psalms 104 in the SBIKS2
Psalms 104 in the SBIMS
Psalms 104 in the SBIOS
Psalms 104 in the SBIPS
Psalms 104 in the SBISS
Psalms 104 in the SBITS
Psalms 104 in the SBITS2
Psalms 104 in the SBITS3
Psalms 104 in the SBITS4
Psalms 104 in the SBIUS
Psalms 104 in the SBIVS
Psalms 104 in the SBT
Psalms 104 in the SBT1E
Psalms 104 in the SCHL
Psalms 104 in the SNT
Psalms 104 in the SUSU
Psalms 104 in the SUSU2
Psalms 104 in the SYNO
Psalms 104 in the TBIAOTANT
Psalms 104 in the TBT1E
Psalms 104 in the TBT1E2
Psalms 104 in the TFTIP
Psalms 104 in the TFTU
Psalms 104 in the TGNTATF3T
Psalms 104 in the THAI
Psalms 104 in the TNFD
Psalms 104 in the TNT
Psalms 104 in the TNTIK
Psalms 104 in the TNTIL
Psalms 104 in the TNTIN
Psalms 104 in the TNTIP
Psalms 104 in the TNTIZ
Psalms 104 in the TOMA
Psalms 104 in the TTENT
Psalms 104 in the UBG
Psalms 104 in the UGV
Psalms 104 in the UGV2
Psalms 104 in the UGV3
Psalms 104 in the VBL
Psalms 104 in the VDCC
Psalms 104 in the YALU
Psalms 104 in the YAPE
Psalms 104 in the YBVTP
Psalms 104 in the ZBP