Psalms 120 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. 1 Èmi ké pe OLÚWA nínú ìpọ́njú mi,ó sì dá mi lóhùn. 2 Gbà mí, OLÚWA, kúrò lọ́wọ́ ètè èkéàti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn. 3 Kí ni kí a fi fún ọ?Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn? 4 Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀. 5 Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari! 6 Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbéláàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà. 7 Ènìyàn àlàáfíà ni mí;ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.