Psalms 121 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. 1 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá? 2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ OLÚWA wá,ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. 3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé. 4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn. 5 OLÚWA ni olùpamọ́ rẹ; OLÚWA ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. 6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sántàbí òṣùpá ní ìgbà òru. 7 OLÚWA yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogboyóò pa ọkàn rẹ mọ́ 8 OLÚWA yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.