Psalms 131 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. 1 OLÚWA àyà mi kò gbéga,bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ. 2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú. 3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti OLÚWAláti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.