Psalms 133 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. 1 Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fúnàwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀. 2 Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀. 3 Bí ìrì Hermonití o sàn sórí òkè Sioni.Nítorí níbẹ̀ ní OLÚWA gbé pàṣẹ ìbùkún,àní ìyè láéláé.