Psalms 142 (BOYCB)
undefined Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà. 1 Èmi kígbe sókè sí OLÚWA;èmi gbé ohùn mi sókè sí OLÚWA fún àánú. 2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀. 3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìnènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀. 4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì ikò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mièmi kò ní ààbò;kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi. 5 Èmi kígbe sí ọ, OLÚWA:èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi,ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.” 6 Fi etí sí igbe mi,nítorí tí èmi wà nínú àìnírètígbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ. 7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkirinítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.