Psalms 82 (BOYCB)
undefined Saamu ti Asafu. 1 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”. 2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodokí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú? 3 Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára. 4 Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú. 5 “Wọn kò mọ̀ ohun kankan,wọn kò lóye ohun kankan.Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé. 6 “Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’ 7 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.” 8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.