Revelation 1 (BOYCB)
1 Ìfihàn ti Jesu Kristi, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fihàn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìṣẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fún Johanu, ìránṣẹ́ rẹ̀, 2 ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí, èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jesu Kristi. 3 Ẹni ìbùkún ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́, nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀. 4 Johanu, Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia: Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀; 5 àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé. Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, 6 tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín. 7 “Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀,gbogbo ojú ni yóò sì rí i,àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú”;àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni“yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.”Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín. 8 “Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.” 9 Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. 10 Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi, bí ìró ìpè, 11 Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.” 12 Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje, 13 àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. 14 Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná. 15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. 16 Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde. Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn. 17 Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18 Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́. 19 “Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; 20 ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.
In Other Versions
Revelation 1 in the ANGEFD
Revelation 1 in the ANTPNG2D
Revelation 1 in the AS21
Revelation 1 in the BAGH
Revelation 1 in the BBPNG
Revelation 1 in the BBT1E
Revelation 1 in the BDS
Revelation 1 in the BEV
Revelation 1 in the BHAD
Revelation 1 in the BIB
Revelation 1 in the BLPT
Revelation 1 in the BNT
Revelation 1 in the BNTABOOT
Revelation 1 in the BNTLV
Revelation 1 in the BOATCB
Revelation 1 in the BOATCB2
Revelation 1 in the BOBCV
Revelation 1 in the BOCNT
Revelation 1 in the BOECS
Revelation 1 in the BOGWICC
Revelation 1 in the BOHCB
Revelation 1 in the BOHCV
Revelation 1 in the BOHLNT
Revelation 1 in the BOHNTLTAL
Revelation 1 in the BOICB
Revelation 1 in the BOILNTAP
Revelation 1 in the BOITCV
Revelation 1 in the BOKCV
Revelation 1 in the BOKCV2
Revelation 1 in the BOKHWOG
Revelation 1 in the BOKSSV
Revelation 1 in the BOLCB
Revelation 1 in the BOLCB2
Revelation 1 in the BOMCV
Revelation 1 in the BONAV
Revelation 1 in the BONCB
Revelation 1 in the BONLT
Revelation 1 in the BONUT2
Revelation 1 in the BOPLNT
Revelation 1 in the BOSCB
Revelation 1 in the BOSNC
Revelation 1 in the BOTLNT
Revelation 1 in the BOVCB
Revelation 1 in the BPBB
Revelation 1 in the BPH
Revelation 1 in the BSB
Revelation 1 in the CCB
Revelation 1 in the CUV
Revelation 1 in the CUVS
Revelation 1 in the DBT
Revelation 1 in the DGDNT
Revelation 1 in the DHNT
Revelation 1 in the DNT
Revelation 1 in the ELBE
Revelation 1 in the EMTV
Revelation 1 in the ESV
Revelation 1 in the FBV
Revelation 1 in the FEB
Revelation 1 in the GGMNT
Revelation 1 in the GNT
Revelation 1 in the HARY
Revelation 1 in the HNT
Revelation 1 in the IRVA
Revelation 1 in the IRVB
Revelation 1 in the IRVG
Revelation 1 in the IRVH
Revelation 1 in the IRVK
Revelation 1 in the IRVM
Revelation 1 in the IRVM2
Revelation 1 in the IRVO
Revelation 1 in the IRVP
Revelation 1 in the IRVT
Revelation 1 in the IRVT2
Revelation 1 in the IRVU
Revelation 1 in the ISVN
Revelation 1 in the JSNT
Revelation 1 in the KAPI
Revelation 1 in the KBT1ETNIK
Revelation 1 in the KBV
Revelation 1 in the KJV
Revelation 1 in the KNFD
Revelation 1 in the LBA
Revelation 1 in the LBLA
Revelation 1 in the LNT
Revelation 1 in the LSV
Revelation 1 in the MAAL
Revelation 1 in the MBV
Revelation 1 in the MBV2
Revelation 1 in the MHNT
Revelation 1 in the MKNFD
Revelation 1 in the MNG
Revelation 1 in the MNT
Revelation 1 in the MNT2
Revelation 1 in the MRS1T
Revelation 1 in the NAA
Revelation 1 in the NASB
Revelation 1 in the NBLA
Revelation 1 in the NBS
Revelation 1 in the NBVTP
Revelation 1 in the NET2
Revelation 1 in the NIV11
Revelation 1 in the NNT
Revelation 1 in the NNT2
Revelation 1 in the NNT3
Revelation 1 in the PDDPT
Revelation 1 in the PFNT
Revelation 1 in the RMNT
Revelation 1 in the SBIAS
Revelation 1 in the SBIBS
Revelation 1 in the SBIBS2
Revelation 1 in the SBICS
Revelation 1 in the SBIDS
Revelation 1 in the SBIGS
Revelation 1 in the SBIHS
Revelation 1 in the SBIIS
Revelation 1 in the SBIIS2
Revelation 1 in the SBIIS3
Revelation 1 in the SBIKS
Revelation 1 in the SBIKS2
Revelation 1 in the SBIMS
Revelation 1 in the SBIOS
Revelation 1 in the SBIPS
Revelation 1 in the SBISS
Revelation 1 in the SBITS
Revelation 1 in the SBITS2
Revelation 1 in the SBITS3
Revelation 1 in the SBITS4
Revelation 1 in the SBIUS
Revelation 1 in the SBIVS
Revelation 1 in the SBT
Revelation 1 in the SBT1E
Revelation 1 in the SCHL
Revelation 1 in the SNT
Revelation 1 in the SUSU
Revelation 1 in the SUSU2
Revelation 1 in the SYNO
Revelation 1 in the TBIAOTANT
Revelation 1 in the TBT1E
Revelation 1 in the TBT1E2
Revelation 1 in the TFTIP
Revelation 1 in the TFTU
Revelation 1 in the TGNTATF3T
Revelation 1 in the THAI
Revelation 1 in the TNFD
Revelation 1 in the TNT
Revelation 1 in the TNTIK
Revelation 1 in the TNTIL
Revelation 1 in the TNTIN
Revelation 1 in the TNTIP
Revelation 1 in the TNTIZ
Revelation 1 in the TOMA
Revelation 1 in the TTENT
Revelation 1 in the UBG
Revelation 1 in the UGV
Revelation 1 in the UGV2
Revelation 1 in the UGV3
Revelation 1 in the VBL
Revelation 1 in the VDCC
Revelation 1 in the YALU
Revelation 1 in the YAPE
Revelation 1 in the YBVTP
Revelation 1 in the ZBP