Revelation 11 (BOYCB)
1 A sì fi ìfèéfèé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá-ìwọ̀n: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹmpili Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀. 2 Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì (42). 3 Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta (1,260) nínú aṣọ ọ̀fọ̀.” 4 Wọ̀nyí ni igi olifi méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé. 5 Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lára, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀tá wọn run, báyìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run. 6 Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn. Wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-ààrùn kọlu ayé, nígbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́. 7 Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n. 8 Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sodomu àti Ejibiti nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú. 9 Fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì. 10 Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró. 11 Àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹsẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn. 12 Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀; lójú àwọn ọ̀tá wọn. 13 Ní wákàtí náà omìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ́wàá ìlú náà sì wó, àti nínú omìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run. 14 Ègbé kejì kọjá; sì kíyèsi i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán. 15 Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀;òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!” 16 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17 wí pé:“Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,ìwọ sì ti jẹ ọba. 18 Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé,àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́,àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀,àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá;àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.” 19 A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.
In Other Versions
Revelation 11 in the ANGEFD
Revelation 11 in the ANTPNG2D
Revelation 11 in the AS21
Revelation 11 in the BAGH
Revelation 11 in the BBPNG
Revelation 11 in the BBT1E
Revelation 11 in the BDS
Revelation 11 in the BEV
Revelation 11 in the BHAD
Revelation 11 in the BIB
Revelation 11 in the BLPT
Revelation 11 in the BNT
Revelation 11 in the BNTABOOT
Revelation 11 in the BNTLV
Revelation 11 in the BOATCB
Revelation 11 in the BOATCB2
Revelation 11 in the BOBCV
Revelation 11 in the BOCNT
Revelation 11 in the BOECS
Revelation 11 in the BOGWICC
Revelation 11 in the BOHCB
Revelation 11 in the BOHCV
Revelation 11 in the BOHLNT
Revelation 11 in the BOHNTLTAL
Revelation 11 in the BOICB
Revelation 11 in the BOILNTAP
Revelation 11 in the BOITCV
Revelation 11 in the BOKCV
Revelation 11 in the BOKCV2
Revelation 11 in the BOKHWOG
Revelation 11 in the BOKSSV
Revelation 11 in the BOLCB
Revelation 11 in the BOLCB2
Revelation 11 in the BOMCV
Revelation 11 in the BONAV
Revelation 11 in the BONCB
Revelation 11 in the BONLT
Revelation 11 in the BONUT2
Revelation 11 in the BOPLNT
Revelation 11 in the BOSCB
Revelation 11 in the BOSNC
Revelation 11 in the BOTLNT
Revelation 11 in the BOVCB
Revelation 11 in the BPBB
Revelation 11 in the BPH
Revelation 11 in the BSB
Revelation 11 in the CCB
Revelation 11 in the CUV
Revelation 11 in the CUVS
Revelation 11 in the DBT
Revelation 11 in the DGDNT
Revelation 11 in the DHNT
Revelation 11 in the DNT
Revelation 11 in the ELBE
Revelation 11 in the EMTV
Revelation 11 in the ESV
Revelation 11 in the FBV
Revelation 11 in the FEB
Revelation 11 in the GGMNT
Revelation 11 in the GNT
Revelation 11 in the HARY
Revelation 11 in the HNT
Revelation 11 in the IRVA
Revelation 11 in the IRVB
Revelation 11 in the IRVG
Revelation 11 in the IRVH
Revelation 11 in the IRVK
Revelation 11 in the IRVM
Revelation 11 in the IRVM2
Revelation 11 in the IRVO
Revelation 11 in the IRVP
Revelation 11 in the IRVT
Revelation 11 in the IRVT2
Revelation 11 in the IRVU
Revelation 11 in the ISVN
Revelation 11 in the JSNT
Revelation 11 in the KAPI
Revelation 11 in the KBT1ETNIK
Revelation 11 in the KBV
Revelation 11 in the KJV
Revelation 11 in the KNFD
Revelation 11 in the LBA
Revelation 11 in the LBLA
Revelation 11 in the LNT
Revelation 11 in the LSV
Revelation 11 in the MAAL
Revelation 11 in the MBV
Revelation 11 in the MBV2
Revelation 11 in the MHNT
Revelation 11 in the MKNFD
Revelation 11 in the MNG
Revelation 11 in the MNT
Revelation 11 in the MNT2
Revelation 11 in the MRS1T
Revelation 11 in the NAA
Revelation 11 in the NASB
Revelation 11 in the NBLA
Revelation 11 in the NBS
Revelation 11 in the NBVTP
Revelation 11 in the NET2
Revelation 11 in the NIV11
Revelation 11 in the NNT
Revelation 11 in the NNT2
Revelation 11 in the NNT3
Revelation 11 in the PDDPT
Revelation 11 in the PFNT
Revelation 11 in the RMNT
Revelation 11 in the SBIAS
Revelation 11 in the SBIBS
Revelation 11 in the SBIBS2
Revelation 11 in the SBICS
Revelation 11 in the SBIDS
Revelation 11 in the SBIGS
Revelation 11 in the SBIHS
Revelation 11 in the SBIIS
Revelation 11 in the SBIIS2
Revelation 11 in the SBIIS3
Revelation 11 in the SBIKS
Revelation 11 in the SBIKS2
Revelation 11 in the SBIMS
Revelation 11 in the SBIOS
Revelation 11 in the SBIPS
Revelation 11 in the SBISS
Revelation 11 in the SBITS
Revelation 11 in the SBITS2
Revelation 11 in the SBITS3
Revelation 11 in the SBITS4
Revelation 11 in the SBIUS
Revelation 11 in the SBIVS
Revelation 11 in the SBT
Revelation 11 in the SBT1E
Revelation 11 in the SCHL
Revelation 11 in the SNT
Revelation 11 in the SUSU
Revelation 11 in the SUSU2
Revelation 11 in the SYNO
Revelation 11 in the TBIAOTANT
Revelation 11 in the TBT1E
Revelation 11 in the TBT1E2
Revelation 11 in the TFTIP
Revelation 11 in the TFTU
Revelation 11 in the TGNTATF3T
Revelation 11 in the THAI
Revelation 11 in the TNFD
Revelation 11 in the TNT
Revelation 11 in the TNTIK
Revelation 11 in the TNTIL
Revelation 11 in the TNTIN
Revelation 11 in the TNTIP
Revelation 11 in the TNTIZ
Revelation 11 in the TOMA
Revelation 11 in the TTENT
Revelation 11 in the UBG
Revelation 11 in the UGV
Revelation 11 in the UGV2
Revelation 11 in the UGV3
Revelation 11 in the VBL
Revelation 11 in the VDCC
Revelation 11 in the YALU
Revelation 11 in the YAPE
Revelation 11 in the YBVTP
Revelation 11 in the ZBP