Revelation 16 (BOYCB)

1 Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹmpili wá, ń wí fún àwọn angẹli, méje nì pé, “Ẹ lọ, ẹ sì tú ago ìbínú Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì sí orí ayé.” 2 Èkínní sì lọ, ó sì tú ago tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní àmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀. 3 Èkejì sì tú ago sínú Òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn, gbogbo ọkàn alààyè sì kú nínú Òkun. 4 Ẹ̀kẹta sì tú ago tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀. 5 Mo sì gbọ́ angẹli tí ó n wí pé:“Olódodo ni ìwọ ninu gbogbo ìdájọ́ wọ̀nyí,ìwọ ẹni tí ó n bẹ àti tí ó tí wa, Ẹni Mímọ́nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ bẹ́ẹ̀. 6 Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀,ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.” 7 Mo sì gbọ́ ti pẹpẹ ń ké wí pé:“Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.” 8 Ẹ̀kẹrin sì tú ago tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára. 9 A sì fi ooru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un. 10 Ẹ̀karùnún sì tú ago tirẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora. 11 Wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn. 12 Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Eufurate; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèsè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà-oòrùn wá. 13 Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dragoni náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá. 14 Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè. 15 “Kíyèsi i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń ṣọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó má bá a rìn ni ìhòhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.” 16 Ó sì gbá wọn jọ́ sí ibìkan tí a ń pè ní Amagedoni ní èdè Heberu. 17 Èkeje si tú ago tirẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹmpili jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!” 18 Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò ṣẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tó bẹ́ẹ̀. 19 Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Babeli ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un. 20 Olúkúlùkù erékùṣù sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́. 21 Yìnyín ńlá, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tó tálẹ́ǹtì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà, àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.

In Other Versions

Revelation 16 in the ANGEFD

Revelation 16 in the ANTPNG2D

Revelation 16 in the AS21

Revelation 16 in the BAGH

Revelation 16 in the BBPNG

Revelation 16 in the BBT1E

Revelation 16 in the BDS

Revelation 16 in the BEV

Revelation 16 in the BHAD

Revelation 16 in the BIB

Revelation 16 in the BLPT

Revelation 16 in the BNT

Revelation 16 in the BNTABOOT

Revelation 16 in the BNTLV

Revelation 16 in the BOATCB

Revelation 16 in the BOATCB2

Revelation 16 in the BOBCV

Revelation 16 in the BOCNT

Revelation 16 in the BOECS

Revelation 16 in the BOGWICC

Revelation 16 in the BOHCB

Revelation 16 in the BOHCV

Revelation 16 in the BOHLNT

Revelation 16 in the BOHNTLTAL

Revelation 16 in the BOICB

Revelation 16 in the BOILNTAP

Revelation 16 in the BOITCV

Revelation 16 in the BOKCV

Revelation 16 in the BOKCV2

Revelation 16 in the BOKHWOG

Revelation 16 in the BOKSSV

Revelation 16 in the BOLCB

Revelation 16 in the BOLCB2

Revelation 16 in the BOMCV

Revelation 16 in the BONAV

Revelation 16 in the BONCB

Revelation 16 in the BONLT

Revelation 16 in the BONUT2

Revelation 16 in the BOPLNT

Revelation 16 in the BOSCB

Revelation 16 in the BOSNC

Revelation 16 in the BOTLNT

Revelation 16 in the BOVCB

Revelation 16 in the BPBB

Revelation 16 in the BPH

Revelation 16 in the BSB

Revelation 16 in the CCB

Revelation 16 in the CUV

Revelation 16 in the CUVS

Revelation 16 in the DBT

Revelation 16 in the DGDNT

Revelation 16 in the DHNT

Revelation 16 in the DNT

Revelation 16 in the ELBE

Revelation 16 in the EMTV

Revelation 16 in the ESV

Revelation 16 in the FBV

Revelation 16 in the FEB

Revelation 16 in the GGMNT

Revelation 16 in the GNT

Revelation 16 in the HARY

Revelation 16 in the HNT

Revelation 16 in the IRVA

Revelation 16 in the IRVB

Revelation 16 in the IRVG

Revelation 16 in the IRVH

Revelation 16 in the IRVK

Revelation 16 in the IRVM

Revelation 16 in the IRVM2

Revelation 16 in the IRVO

Revelation 16 in the IRVP

Revelation 16 in the IRVT

Revelation 16 in the IRVT2

Revelation 16 in the IRVU

Revelation 16 in the ISVN

Revelation 16 in the JSNT

Revelation 16 in the KAPI

Revelation 16 in the KBT1ETNIK

Revelation 16 in the KBV

Revelation 16 in the KJV

Revelation 16 in the KNFD

Revelation 16 in the LBA

Revelation 16 in the LBLA

Revelation 16 in the LNT

Revelation 16 in the LSV

Revelation 16 in the MAAL

Revelation 16 in the MBV

Revelation 16 in the MBV2

Revelation 16 in the MHNT

Revelation 16 in the MKNFD

Revelation 16 in the MNG

Revelation 16 in the MNT

Revelation 16 in the MNT2

Revelation 16 in the MRS1T

Revelation 16 in the NAA

Revelation 16 in the NASB

Revelation 16 in the NBLA

Revelation 16 in the NBS

Revelation 16 in the NBVTP

Revelation 16 in the NET2

Revelation 16 in the NIV11

Revelation 16 in the NNT

Revelation 16 in the NNT2

Revelation 16 in the NNT3

Revelation 16 in the PDDPT

Revelation 16 in the PFNT

Revelation 16 in the RMNT

Revelation 16 in the SBIAS

Revelation 16 in the SBIBS

Revelation 16 in the SBIBS2

Revelation 16 in the SBICS

Revelation 16 in the SBIDS

Revelation 16 in the SBIGS

Revelation 16 in the SBIHS

Revelation 16 in the SBIIS

Revelation 16 in the SBIIS2

Revelation 16 in the SBIIS3

Revelation 16 in the SBIKS

Revelation 16 in the SBIKS2

Revelation 16 in the SBIMS

Revelation 16 in the SBIOS

Revelation 16 in the SBIPS

Revelation 16 in the SBISS

Revelation 16 in the SBITS

Revelation 16 in the SBITS2

Revelation 16 in the SBITS3

Revelation 16 in the SBITS4

Revelation 16 in the SBIUS

Revelation 16 in the SBIVS

Revelation 16 in the SBT

Revelation 16 in the SBT1E

Revelation 16 in the SCHL

Revelation 16 in the SNT

Revelation 16 in the SUSU

Revelation 16 in the SUSU2

Revelation 16 in the SYNO

Revelation 16 in the TBIAOTANT

Revelation 16 in the TBT1E

Revelation 16 in the TBT1E2

Revelation 16 in the TFTIP

Revelation 16 in the TFTU

Revelation 16 in the TGNTATF3T

Revelation 16 in the THAI

Revelation 16 in the TNFD

Revelation 16 in the TNT

Revelation 16 in the TNTIK

Revelation 16 in the TNTIL

Revelation 16 in the TNTIN

Revelation 16 in the TNTIP

Revelation 16 in the TNTIZ

Revelation 16 in the TOMA

Revelation 16 in the TTENT

Revelation 16 in the UBG

Revelation 16 in the UGV

Revelation 16 in the UGV2

Revelation 16 in the UGV3

Revelation 16 in the VBL

Revelation 16 in the VDCC

Revelation 16 in the YALU

Revelation 16 in the YAPE

Revelation 16 in the YBVTP

Revelation 16 in the ZBP