Revelation 21 (BOYCB)
1 Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan, nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́. 2 Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerusalẹmu tuntun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. 3 Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn. 4 Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́, nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.” 5 Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.” 6 Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. 7 Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi. 8 Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.” 9 Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.” 10 Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fi ìlú náà hàn mi, Jerusalẹmu mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, 11 tí ó ní ògo Ọlọ́run, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta jasperi, ó mọ́ bí kirisitali; 12 Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli. 13 Ní ìhà ìlà-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà gúúsù ẹnu ibodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta. 14 Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn. 15 Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, àti odi rẹ̀. 16 Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba: ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba. 17 Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ́ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òsùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí angẹli náà. 18 A sì fi jasperi mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere. 19 A fi onírúurú òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ èkínní jẹ́ jasperi; èkejì, safiru; ẹ̀kẹta, kalkedoni; ẹ̀kẹrin, emeradi; 20 ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, berili; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti. 21 Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ perli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán. 22 Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn. 23 Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i, nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀. 24 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀. 25 A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu ibodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀. 26 Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀. 27 Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.
In Other Versions
Revelation 21 in the ANGEFD
Revelation 21 in the ANTPNG2D
Revelation 21 in the AS21
Revelation 21 in the BAGH
Revelation 21 in the BBPNG
Revelation 21 in the BBT1E
Revelation 21 in the BDS
Revelation 21 in the BEV
Revelation 21 in the BHAD
Revelation 21 in the BIB
Revelation 21 in the BLPT
Revelation 21 in the BNT
Revelation 21 in the BNTABOOT
Revelation 21 in the BNTLV
Revelation 21 in the BOATCB
Revelation 21 in the BOATCB2
Revelation 21 in the BOBCV
Revelation 21 in the BOCNT
Revelation 21 in the BOECS
Revelation 21 in the BOGWICC
Revelation 21 in the BOHCB
Revelation 21 in the BOHCV
Revelation 21 in the BOHLNT
Revelation 21 in the BOHNTLTAL
Revelation 21 in the BOICB
Revelation 21 in the BOILNTAP
Revelation 21 in the BOITCV
Revelation 21 in the BOKCV
Revelation 21 in the BOKCV2
Revelation 21 in the BOKHWOG
Revelation 21 in the BOKSSV
Revelation 21 in the BOLCB
Revelation 21 in the BOLCB2
Revelation 21 in the BOMCV
Revelation 21 in the BONAV
Revelation 21 in the BONCB
Revelation 21 in the BONLT
Revelation 21 in the BONUT2
Revelation 21 in the BOPLNT
Revelation 21 in the BOSCB
Revelation 21 in the BOSNC
Revelation 21 in the BOTLNT
Revelation 21 in the BOVCB
Revelation 21 in the BPBB
Revelation 21 in the BPH
Revelation 21 in the BSB
Revelation 21 in the CCB
Revelation 21 in the CUV
Revelation 21 in the CUVS
Revelation 21 in the DBT
Revelation 21 in the DGDNT
Revelation 21 in the DHNT
Revelation 21 in the DNT
Revelation 21 in the ELBE
Revelation 21 in the EMTV
Revelation 21 in the ESV
Revelation 21 in the FBV
Revelation 21 in the FEB
Revelation 21 in the GGMNT
Revelation 21 in the GNT
Revelation 21 in the HARY
Revelation 21 in the HNT
Revelation 21 in the IRVA
Revelation 21 in the IRVB
Revelation 21 in the IRVG
Revelation 21 in the IRVH
Revelation 21 in the IRVK
Revelation 21 in the IRVM
Revelation 21 in the IRVM2
Revelation 21 in the IRVO
Revelation 21 in the IRVP
Revelation 21 in the IRVT
Revelation 21 in the IRVT2
Revelation 21 in the IRVU
Revelation 21 in the ISVN
Revelation 21 in the JSNT
Revelation 21 in the KAPI
Revelation 21 in the KBT1ETNIK
Revelation 21 in the KBV
Revelation 21 in the KJV
Revelation 21 in the KNFD
Revelation 21 in the LBA
Revelation 21 in the LBLA
Revelation 21 in the LNT
Revelation 21 in the LSV
Revelation 21 in the MAAL
Revelation 21 in the MBV
Revelation 21 in the MBV2
Revelation 21 in the MHNT
Revelation 21 in the MKNFD
Revelation 21 in the MNG
Revelation 21 in the MNT
Revelation 21 in the MNT2
Revelation 21 in the MRS1T
Revelation 21 in the NAA
Revelation 21 in the NASB
Revelation 21 in the NBLA
Revelation 21 in the NBS
Revelation 21 in the NBVTP
Revelation 21 in the NET2
Revelation 21 in the NIV11
Revelation 21 in the NNT
Revelation 21 in the NNT2
Revelation 21 in the NNT3
Revelation 21 in the PDDPT
Revelation 21 in the PFNT
Revelation 21 in the RMNT
Revelation 21 in the SBIAS
Revelation 21 in the SBIBS
Revelation 21 in the SBIBS2
Revelation 21 in the SBICS
Revelation 21 in the SBIDS
Revelation 21 in the SBIGS
Revelation 21 in the SBIHS
Revelation 21 in the SBIIS
Revelation 21 in the SBIIS2
Revelation 21 in the SBIIS3
Revelation 21 in the SBIKS
Revelation 21 in the SBIKS2
Revelation 21 in the SBIMS
Revelation 21 in the SBIOS
Revelation 21 in the SBIPS
Revelation 21 in the SBISS
Revelation 21 in the SBITS
Revelation 21 in the SBITS2
Revelation 21 in the SBITS3
Revelation 21 in the SBITS4
Revelation 21 in the SBIUS
Revelation 21 in the SBIVS
Revelation 21 in the SBT
Revelation 21 in the SBT1E
Revelation 21 in the SCHL
Revelation 21 in the SNT
Revelation 21 in the SUSU
Revelation 21 in the SUSU2
Revelation 21 in the SYNO
Revelation 21 in the TBIAOTANT
Revelation 21 in the TBT1E
Revelation 21 in the TBT1E2
Revelation 21 in the TFTIP
Revelation 21 in the TFTU
Revelation 21 in the TGNTATF3T
Revelation 21 in the THAI
Revelation 21 in the TNFD
Revelation 21 in the TNT
Revelation 21 in the TNTIK
Revelation 21 in the TNTIL
Revelation 21 in the TNTIN
Revelation 21 in the TNTIP
Revelation 21 in the TNTIZ
Revelation 21 in the TOMA
Revelation 21 in the TTENT
Revelation 21 in the UBG
Revelation 21 in the UGV
Revelation 21 in the UGV2
Revelation 21 in the UGV3
Revelation 21 in the VBL
Revelation 21 in the VDCC
Revelation 21 in the YALU
Revelation 21 in the YAPE
Revelation 21 in the YBVTP
Revelation 21 in the ZBP