Romans 14 (BOYCB)
1 Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má ṣe tọpinpin ìṣeyèméjì rẹ̀. 2 Ẹnìkan gbàgbọ́ pé òun lè máa jẹ ohun gbogbo: ṣùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan. 3 Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi nítorí Ọlọ́run ti gbà á. 4 Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró. 5 Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. 6 Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. 7 Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀. 8 Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe. 9 Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè. 10 Èéṣe nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èéṣe tí ìwọ fi ń gàn wọn? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 11 A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:“ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí,‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ” 12 Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run. 13 Nítorí náà, ẹ má ṣe tún jẹ́ kí a máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arákùnrin tàbí arábìnrin yín. 14 Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún. 15 Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé. 16 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí ẹ mọ̀ sí rere ní búburú. 17 Nítorí ìjọba ọ̀run kì í ṣe jíjẹ àti mímu, bí kò ṣe nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Ẹ̀mí Mímọ́, 18 nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró. 20 Má ṣe bi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣubú nítorí oúnjẹ. Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, ṣùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú ẹlòmíràn kọsẹ̀. 21 Ó dára kí a má tilẹ̀ jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ṣubú. 22 Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nínú ohun tí ó yàn. 23 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣe iyèméjì, ó jẹ̀bi bí ó ba jẹ ẹ́, nítorí jíjẹ ẹ́ rẹ̀ kò ti inú ìgbàgbọ́ wá; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni.
In Other Versions
Romans 14 in the ANGEFD
Romans 14 in the ANTPNG2D
Romans 14 in the AS21
Romans 14 in the BAGH
Romans 14 in the BBPNG
Romans 14 in the BBT1E
Romans 14 in the BDS
Romans 14 in the BEV
Romans 14 in the BHAD
Romans 14 in the BIB
Romans 14 in the BLPT
Romans 14 in the BNT
Romans 14 in the BNTABOOT
Romans 14 in the BNTLV
Romans 14 in the BOATCB
Romans 14 in the BOATCB2
Romans 14 in the BOBCV
Romans 14 in the BOCNT
Romans 14 in the BOECS
Romans 14 in the BOGWICC
Romans 14 in the BOHCB
Romans 14 in the BOHCV
Romans 14 in the BOHLNT
Romans 14 in the BOHNTLTAL
Romans 14 in the BOICB
Romans 14 in the BOILNTAP
Romans 14 in the BOITCV
Romans 14 in the BOKCV
Romans 14 in the BOKCV2
Romans 14 in the BOKHWOG
Romans 14 in the BOKSSV
Romans 14 in the BOLCB
Romans 14 in the BOLCB2
Romans 14 in the BOMCV
Romans 14 in the BONAV
Romans 14 in the BONCB
Romans 14 in the BONLT
Romans 14 in the BONUT2
Romans 14 in the BOPLNT
Romans 14 in the BOSCB
Romans 14 in the BOSNC
Romans 14 in the BOTLNT
Romans 14 in the BOVCB
Romans 14 in the BPBB
Romans 14 in the BPH
Romans 14 in the BSB
Romans 14 in the CCB
Romans 14 in the CUV
Romans 14 in the CUVS
Romans 14 in the DBT
Romans 14 in the DGDNT
Romans 14 in the DHNT
Romans 14 in the DNT
Romans 14 in the ELBE
Romans 14 in the EMTV
Romans 14 in the ESV
Romans 14 in the FBV
Romans 14 in the FEB
Romans 14 in the GGMNT
Romans 14 in the GNT
Romans 14 in the HARY
Romans 14 in the HNT
Romans 14 in the IRVA
Romans 14 in the IRVB
Romans 14 in the IRVG
Romans 14 in the IRVH
Romans 14 in the IRVK
Romans 14 in the IRVM
Romans 14 in the IRVM2
Romans 14 in the IRVO
Romans 14 in the IRVP
Romans 14 in the IRVT
Romans 14 in the IRVT2
Romans 14 in the IRVU
Romans 14 in the ISVN
Romans 14 in the JSNT
Romans 14 in the KAPI
Romans 14 in the KBT1ETNIK
Romans 14 in the KBV
Romans 14 in the KJV
Romans 14 in the KNFD
Romans 14 in the LBA
Romans 14 in the LBLA
Romans 14 in the LNT
Romans 14 in the LSV
Romans 14 in the MAAL
Romans 14 in the MBV
Romans 14 in the MBV2
Romans 14 in the MHNT
Romans 14 in the MKNFD
Romans 14 in the MNG
Romans 14 in the MNT
Romans 14 in the MNT2
Romans 14 in the MRS1T
Romans 14 in the NAA
Romans 14 in the NASB
Romans 14 in the NBLA
Romans 14 in the NBS
Romans 14 in the NBVTP
Romans 14 in the NET2
Romans 14 in the NIV11
Romans 14 in the NNT
Romans 14 in the NNT2
Romans 14 in the NNT3
Romans 14 in the PDDPT
Romans 14 in the PFNT
Romans 14 in the RMNT
Romans 14 in the SBIAS
Romans 14 in the SBIBS
Romans 14 in the SBIBS2
Romans 14 in the SBICS
Romans 14 in the SBIDS
Romans 14 in the SBIGS
Romans 14 in the SBIHS
Romans 14 in the SBIIS
Romans 14 in the SBIIS2
Romans 14 in the SBIIS3
Romans 14 in the SBIKS
Romans 14 in the SBIKS2
Romans 14 in the SBIMS
Romans 14 in the SBIOS
Romans 14 in the SBIPS
Romans 14 in the SBISS
Romans 14 in the SBITS
Romans 14 in the SBITS2
Romans 14 in the SBITS3
Romans 14 in the SBITS4
Romans 14 in the SBIUS
Romans 14 in the SBIVS
Romans 14 in the SBT
Romans 14 in the SBT1E
Romans 14 in the SCHL
Romans 14 in the SNT
Romans 14 in the SUSU
Romans 14 in the SUSU2
Romans 14 in the SYNO
Romans 14 in the TBIAOTANT
Romans 14 in the TBT1E
Romans 14 in the TBT1E2
Romans 14 in the TFTIP
Romans 14 in the TFTU
Romans 14 in the TGNTATF3T
Romans 14 in the THAI
Romans 14 in the TNFD
Romans 14 in the TNT
Romans 14 in the TNTIK
Romans 14 in the TNTIL
Romans 14 in the TNTIN
Romans 14 in the TNTIP
Romans 14 in the TNTIZ
Romans 14 in the TOMA
Romans 14 in the TTENT
Romans 14 in the UBG
Romans 14 in the UGV
Romans 14 in the UGV2
Romans 14 in the UGV3
Romans 14 in the VBL
Romans 14 in the VDCC
Romans 14 in the YALU
Romans 14 in the YAPE
Romans 14 in the YBVTP
Romans 14 in the ZBP