Romans 4 (BOYCB)
1 Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Abrahamu, baba wa ti o ṣàwárí èyí? Májẹ̀mú láéláé jẹ́rìí sí i wí pé, a gba Abrahamu là nípa ìgbàgbọ́. 2 Nítorí bí a bá dá Abrahamu láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run. 3 Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.” 4 Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore-ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀. 5 Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo. 6 Gẹ́gẹ́ bí Dafidi pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́. 7 Wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọnẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì,tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. 8 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náàẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.” 9 Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. 10 Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni. 11 Ó sì gbé àmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú. 12 Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà. 13 Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́. 14 Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá jẹ ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára. 15 Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú, ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀. 16 Nítorí náà ni ó ṣe gbé e ka orí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-ọ̀fẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú-ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Abrahamu, ẹni tí í ṣe baba gbogbo wa pátápátá, 17 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ ṣe baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà. 18 Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.” 19 Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó mọ pe ara òun tìkára rẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sara. 20 Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run, 21 pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀. 22 Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un. 23 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe nítorí tirẹ̀ nìkan. 24 Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jesu Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́. 25 Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.
In Other Versions
Romans 4 in the ANGEFD
Romans 4 in the ANTPNG2D
Romans 4 in the AS21
Romans 4 in the BAGH
Romans 4 in the BBPNG
Romans 4 in the BBT1E
Romans 4 in the BDS
Romans 4 in the BEV
Romans 4 in the BHAD
Romans 4 in the BIB
Romans 4 in the BLPT
Romans 4 in the BNT
Romans 4 in the BNTABOOT
Romans 4 in the BNTLV
Romans 4 in the BOATCB
Romans 4 in the BOATCB2
Romans 4 in the BOBCV
Romans 4 in the BOCNT
Romans 4 in the BOECS
Romans 4 in the BOGWICC
Romans 4 in the BOHCB
Romans 4 in the BOHCV
Romans 4 in the BOHLNT
Romans 4 in the BOHNTLTAL
Romans 4 in the BOICB
Romans 4 in the BOILNTAP
Romans 4 in the BOITCV
Romans 4 in the BOKCV
Romans 4 in the BOKCV2
Romans 4 in the BOKHWOG
Romans 4 in the BOKSSV
Romans 4 in the BOLCB
Romans 4 in the BOLCB2
Romans 4 in the BOMCV
Romans 4 in the BONAV
Romans 4 in the BONCB
Romans 4 in the BONLT
Romans 4 in the BONUT2
Romans 4 in the BOPLNT
Romans 4 in the BOSCB
Romans 4 in the BOSNC
Romans 4 in the BOTLNT
Romans 4 in the BOVCB
Romans 4 in the BPBB
Romans 4 in the BPH
Romans 4 in the BSB
Romans 4 in the CCB
Romans 4 in the CUV
Romans 4 in the CUVS
Romans 4 in the DBT
Romans 4 in the DGDNT
Romans 4 in the DHNT
Romans 4 in the DNT
Romans 4 in the ELBE
Romans 4 in the EMTV
Romans 4 in the ESV
Romans 4 in the FBV
Romans 4 in the FEB
Romans 4 in the GGMNT
Romans 4 in the GNT
Romans 4 in the HARY
Romans 4 in the HNT
Romans 4 in the IRVA
Romans 4 in the IRVB
Romans 4 in the IRVG
Romans 4 in the IRVH
Romans 4 in the IRVK
Romans 4 in the IRVM
Romans 4 in the IRVM2
Romans 4 in the IRVO
Romans 4 in the IRVP
Romans 4 in the IRVT
Romans 4 in the IRVT2
Romans 4 in the IRVU
Romans 4 in the ISVN
Romans 4 in the JSNT
Romans 4 in the KAPI
Romans 4 in the KBT1ETNIK
Romans 4 in the KBV
Romans 4 in the KJV
Romans 4 in the KNFD
Romans 4 in the LBA
Romans 4 in the LBLA
Romans 4 in the LNT
Romans 4 in the LSV
Romans 4 in the MAAL
Romans 4 in the MBV
Romans 4 in the MBV2
Romans 4 in the MHNT
Romans 4 in the MKNFD
Romans 4 in the MNG
Romans 4 in the MNT
Romans 4 in the MNT2
Romans 4 in the MRS1T
Romans 4 in the NAA
Romans 4 in the NASB
Romans 4 in the NBLA
Romans 4 in the NBS
Romans 4 in the NBVTP
Romans 4 in the NET2
Romans 4 in the NIV11
Romans 4 in the NNT
Romans 4 in the NNT2
Romans 4 in the NNT3
Romans 4 in the PDDPT
Romans 4 in the PFNT
Romans 4 in the RMNT
Romans 4 in the SBIAS
Romans 4 in the SBIBS
Romans 4 in the SBIBS2
Romans 4 in the SBICS
Romans 4 in the SBIDS
Romans 4 in the SBIGS
Romans 4 in the SBIHS
Romans 4 in the SBIIS
Romans 4 in the SBIIS2
Romans 4 in the SBIIS3
Romans 4 in the SBIKS
Romans 4 in the SBIKS2
Romans 4 in the SBIMS
Romans 4 in the SBIOS
Romans 4 in the SBIPS
Romans 4 in the SBISS
Romans 4 in the SBITS
Romans 4 in the SBITS2
Romans 4 in the SBITS3
Romans 4 in the SBITS4
Romans 4 in the SBIUS
Romans 4 in the SBIVS
Romans 4 in the SBT
Romans 4 in the SBT1E
Romans 4 in the SCHL
Romans 4 in the SNT
Romans 4 in the SUSU
Romans 4 in the SUSU2
Romans 4 in the SYNO
Romans 4 in the TBIAOTANT
Romans 4 in the TBT1E
Romans 4 in the TBT1E2
Romans 4 in the TFTIP
Romans 4 in the TFTU
Romans 4 in the TGNTATF3T
Romans 4 in the THAI
Romans 4 in the TNFD
Romans 4 in the TNT
Romans 4 in the TNTIK
Romans 4 in the TNTIL
Romans 4 in the TNTIN
Romans 4 in the TNTIP
Romans 4 in the TNTIZ
Romans 4 in the TOMA
Romans 4 in the TTENT
Romans 4 in the UBG
Romans 4 in the UGV
Romans 4 in the UGV2
Romans 4 in the UGV3
Romans 4 in the VBL
Romans 4 in the VDCC
Romans 4 in the YALU
Romans 4 in the YAPE
Romans 4 in the YBVTP
Romans 4 in the ZBP