1 Peter 3 (BOYCB)
1 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn. 2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín. 3 Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; 4 ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run. 5 Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn. 6 Gẹ́gẹ́ bí Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín. 7 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà. 8 Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. 9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10 Nítorí,“Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,ti yóò sì rí ọjọ́ rere,kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. 11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀. 12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn,ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.” 13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. 18 Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí. 19 Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú, 20 àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ. 21 Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi. 22 Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
In Other Versions
1 Peter 3 in the ANGEFD
1 Peter 3 in the ANTPNG2D
1 Peter 3 in the AS21
1 Peter 3 in the BAGH
1 Peter 3 in the BBPNG
1 Peter 3 in the BBT1E
1 Peter 3 in the BDS
1 Peter 3 in the BEV
1 Peter 3 in the BHAD
1 Peter 3 in the BIB
1 Peter 3 in the BLPT
1 Peter 3 in the BNT
1 Peter 3 in the BNTABOOT
1 Peter 3 in the BNTLV
1 Peter 3 in the BOATCB
1 Peter 3 in the BOATCB2
1 Peter 3 in the BOBCV
1 Peter 3 in the BOCNT
1 Peter 3 in the BOECS
1 Peter 3 in the BOGWICC
1 Peter 3 in the BOHCB
1 Peter 3 in the BOHCV
1 Peter 3 in the BOHLNT
1 Peter 3 in the BOHNTLTAL
1 Peter 3 in the BOICB
1 Peter 3 in the BOILNTAP
1 Peter 3 in the BOITCV
1 Peter 3 in the BOKCV
1 Peter 3 in the BOKCV2
1 Peter 3 in the BOKHWOG
1 Peter 3 in the BOKSSV
1 Peter 3 in the BOLCB
1 Peter 3 in the BOLCB2
1 Peter 3 in the BOMCV
1 Peter 3 in the BONAV
1 Peter 3 in the BONCB
1 Peter 3 in the BONLT
1 Peter 3 in the BONUT2
1 Peter 3 in the BOPLNT
1 Peter 3 in the BOSCB
1 Peter 3 in the BOSNC
1 Peter 3 in the BOTLNT
1 Peter 3 in the BOVCB
1 Peter 3 in the BPBB
1 Peter 3 in the BPH
1 Peter 3 in the BSB
1 Peter 3 in the CCB
1 Peter 3 in the CUV
1 Peter 3 in the CUVS
1 Peter 3 in the DBT
1 Peter 3 in the DGDNT
1 Peter 3 in the DHNT
1 Peter 3 in the DNT
1 Peter 3 in the ELBE
1 Peter 3 in the EMTV
1 Peter 3 in the ESV
1 Peter 3 in the FBV
1 Peter 3 in the FEB
1 Peter 3 in the GGMNT
1 Peter 3 in the GNT
1 Peter 3 in the HARY
1 Peter 3 in the HNT
1 Peter 3 in the IRVA
1 Peter 3 in the IRVB
1 Peter 3 in the IRVG
1 Peter 3 in the IRVH
1 Peter 3 in the IRVK
1 Peter 3 in the IRVM
1 Peter 3 in the IRVM2
1 Peter 3 in the IRVO
1 Peter 3 in the IRVP
1 Peter 3 in the IRVT
1 Peter 3 in the IRVT2
1 Peter 3 in the IRVU
1 Peter 3 in the ISVN
1 Peter 3 in the JSNT
1 Peter 3 in the KAPI
1 Peter 3 in the KBT1ETNIK
1 Peter 3 in the KBV
1 Peter 3 in the KJV
1 Peter 3 in the KNFD
1 Peter 3 in the LBA
1 Peter 3 in the LBLA
1 Peter 3 in the LNT
1 Peter 3 in the LSV
1 Peter 3 in the MAAL
1 Peter 3 in the MBV
1 Peter 3 in the MBV2
1 Peter 3 in the MHNT
1 Peter 3 in the MKNFD
1 Peter 3 in the MNG
1 Peter 3 in the MNT
1 Peter 3 in the MNT2
1 Peter 3 in the MRS1T
1 Peter 3 in the NAA
1 Peter 3 in the NASB
1 Peter 3 in the NBLA
1 Peter 3 in the NBS
1 Peter 3 in the NBVTP
1 Peter 3 in the NET2
1 Peter 3 in the NIV11
1 Peter 3 in the NNT
1 Peter 3 in the NNT2
1 Peter 3 in the NNT3
1 Peter 3 in the PDDPT
1 Peter 3 in the PFNT
1 Peter 3 in the RMNT
1 Peter 3 in the SBIAS
1 Peter 3 in the SBIBS
1 Peter 3 in the SBIBS2
1 Peter 3 in the SBICS
1 Peter 3 in the SBIDS
1 Peter 3 in the SBIGS
1 Peter 3 in the SBIHS
1 Peter 3 in the SBIIS
1 Peter 3 in the SBIIS2
1 Peter 3 in the SBIIS3
1 Peter 3 in the SBIKS
1 Peter 3 in the SBIKS2
1 Peter 3 in the SBIMS
1 Peter 3 in the SBIOS
1 Peter 3 in the SBIPS
1 Peter 3 in the SBISS
1 Peter 3 in the SBITS
1 Peter 3 in the SBITS2
1 Peter 3 in the SBITS3
1 Peter 3 in the SBITS4
1 Peter 3 in the SBIUS
1 Peter 3 in the SBIVS
1 Peter 3 in the SBT
1 Peter 3 in the SBT1E
1 Peter 3 in the SCHL
1 Peter 3 in the SNT
1 Peter 3 in the SUSU
1 Peter 3 in the SUSU2
1 Peter 3 in the SYNO
1 Peter 3 in the TBIAOTANT
1 Peter 3 in the TBT1E
1 Peter 3 in the TBT1E2
1 Peter 3 in the TFTIP
1 Peter 3 in the TFTU
1 Peter 3 in the TGNTATF3T
1 Peter 3 in the THAI
1 Peter 3 in the TNFD
1 Peter 3 in the TNT
1 Peter 3 in the TNTIK
1 Peter 3 in the TNTIL
1 Peter 3 in the TNTIN
1 Peter 3 in the TNTIP
1 Peter 3 in the TNTIZ
1 Peter 3 in the TOMA
1 Peter 3 in the TTENT
1 Peter 3 in the UBG
1 Peter 3 in the UGV
1 Peter 3 in the UGV2
1 Peter 3 in the UGV3
1 Peter 3 in the VBL
1 Peter 3 in the VDCC
1 Peter 3 in the YALU
1 Peter 3 in the YAPE
1 Peter 3 in the YBVTP
1 Peter 3 in the ZBP