2 Chronicles 13 (BOYCB)
1 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jeroboamu, Abijah di ọba Juda. 2 Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mikaiah, ọmọbìnrin Urieli ti Gibeah.Ogun wà láàrín Abijah àti Jeroboamu. 3 Abijah lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin alágbára, Jeroboamu kó ogun jọ pẹ̀lú ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára. 4 Abijah dúró lórí òkè Semaraimu ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, ó sì wí pé, Jeroboamu àti gbogbo Israẹli, ẹ gbọ́ mi! 5 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé OLÚWA Ọlọ́run Israẹli ti fún Dafidi àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀? 6 Síbẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, oníṣẹ́ Solomoni ọmọ Dafidi, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀. 7 Àwọn ènìyàn lásán sì kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹni búburú, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Rehoboamu ọmọ Solomoni ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fúnra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n. 8 “Nísinsin yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba OLÚWA, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dafidi. Ìwọ jẹ́ ọmọ-ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lú rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jeroboamu dà láti fi ṣe Ọlọ́run yín. 9 Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà OLÚWA jáde, àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ará Lefi. Tí ó sì ṣe àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run. 10 “Ní ti àwa, OLÚWA ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfáà tí ó ń sin OLÚWA jẹ́ àwọn ọmọ Aaroni àwọn ará Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. 11 Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ẹbọ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú OLÚWA. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ OLÚWA Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 12 Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò fọn ìpè ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Israẹli, ẹ má ṣe dojú ìjà kọ OLÚWA Ọlọ́run baba yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.” 13 Nísinsin yìí, Jeroboamu ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn. Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà níwájú Juda, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn. 14 Nígbà tí Juda sì bojú wo ẹ̀yìn, sì kíyèsi i, ogun ń bẹ níwájú àti lẹ́yìn, wọn sì ké pe OLÚWA, àwọn àlùfáà sì fun ìpè. 15 Olúkúlùkù, ọkùnrin Juda sì fún ìpè ogun, ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Juda sì ti fun ìpè ogun, ni Ọlọ́run kọlu Jeroboamu àti gbogbo Israẹli níwájú Abijah àti Juda. 16 Àwọn ọmọ Israẹli sálọ kúrò níwájú Juda, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́. 17 Abijah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdààmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Israẹli. 18 Báyìí ni a rẹ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ ní àkókò náà, àwọn ọmọ Juda sì borí nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba wọn. 19 Abijah sì lépa Jeroboamu, ó sì gba ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Beteli pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Jeṣana pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Efroni pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀. 20 Bẹ́ẹ̀ ní Jeroboamu kò sì tún ní agbára mọ́ ní ọjọ́ Abijah. OLÚWA sì lù ú ó sì kú. 21 Abijah sì di alágbára, ó sì gbé obìnrin mẹ́tàlá ní ìyàwó, ó sì bi ọmọkùnrin méjìlélógún, àti ọmọbìnrin mẹ́rìndínlógún. 22 Àti ìyókù ìṣe Abijah, àti ìwà rẹ̀, àti iṣẹ́ rẹ̀, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtumọ̀, wòlíì Iddo.
In Other Versions
2 Chronicles 13 in the ANGEFD
2 Chronicles 13 in the ANTPNG2D
2 Chronicles 13 in the AS21
2 Chronicles 13 in the BAGH
2 Chronicles 13 in the BBPNG
2 Chronicles 13 in the BBT1E
2 Chronicles 13 in the BDS
2 Chronicles 13 in the BEV
2 Chronicles 13 in the BHAD
2 Chronicles 13 in the BIB
2 Chronicles 13 in the BLPT
2 Chronicles 13 in the BNT
2 Chronicles 13 in the BNTABOOT
2 Chronicles 13 in the BNTLV
2 Chronicles 13 in the BOATCB
2 Chronicles 13 in the BOATCB2
2 Chronicles 13 in the BOBCV
2 Chronicles 13 in the BOCNT
2 Chronicles 13 in the BOECS
2 Chronicles 13 in the BOGWICC
2 Chronicles 13 in the BOHCB
2 Chronicles 13 in the BOHCV
2 Chronicles 13 in the BOHLNT
2 Chronicles 13 in the BOHNTLTAL
2 Chronicles 13 in the BOICB
2 Chronicles 13 in the BOILNTAP
2 Chronicles 13 in the BOITCV
2 Chronicles 13 in the BOKCV
2 Chronicles 13 in the BOKCV2
2 Chronicles 13 in the BOKHWOG
2 Chronicles 13 in the BOKSSV
2 Chronicles 13 in the BOLCB
2 Chronicles 13 in the BOLCB2
2 Chronicles 13 in the BOMCV
2 Chronicles 13 in the BONAV
2 Chronicles 13 in the BONCB
2 Chronicles 13 in the BONLT
2 Chronicles 13 in the BONUT2
2 Chronicles 13 in the BOPLNT
2 Chronicles 13 in the BOSCB
2 Chronicles 13 in the BOSNC
2 Chronicles 13 in the BOTLNT
2 Chronicles 13 in the BOVCB
2 Chronicles 13 in the BPBB
2 Chronicles 13 in the BPH
2 Chronicles 13 in the BSB
2 Chronicles 13 in the CCB
2 Chronicles 13 in the CUV
2 Chronicles 13 in the CUVS
2 Chronicles 13 in the DBT
2 Chronicles 13 in the DGDNT
2 Chronicles 13 in the DHNT
2 Chronicles 13 in the DNT
2 Chronicles 13 in the ELBE
2 Chronicles 13 in the EMTV
2 Chronicles 13 in the ESV
2 Chronicles 13 in the FBV
2 Chronicles 13 in the FEB
2 Chronicles 13 in the GGMNT
2 Chronicles 13 in the GNT
2 Chronicles 13 in the HARY
2 Chronicles 13 in the HNT
2 Chronicles 13 in the IRVA
2 Chronicles 13 in the IRVB
2 Chronicles 13 in the IRVG
2 Chronicles 13 in the IRVH
2 Chronicles 13 in the IRVK
2 Chronicles 13 in the IRVM
2 Chronicles 13 in the IRVM2
2 Chronicles 13 in the IRVO
2 Chronicles 13 in the IRVP
2 Chronicles 13 in the IRVT
2 Chronicles 13 in the IRVT2
2 Chronicles 13 in the IRVU
2 Chronicles 13 in the ISVN
2 Chronicles 13 in the JSNT
2 Chronicles 13 in the KAPI
2 Chronicles 13 in the KBT1ETNIK
2 Chronicles 13 in the KBV
2 Chronicles 13 in the KJV
2 Chronicles 13 in the KNFD
2 Chronicles 13 in the LBA
2 Chronicles 13 in the LBLA
2 Chronicles 13 in the LNT
2 Chronicles 13 in the LSV
2 Chronicles 13 in the MAAL
2 Chronicles 13 in the MBV
2 Chronicles 13 in the MBV2
2 Chronicles 13 in the MHNT
2 Chronicles 13 in the MKNFD
2 Chronicles 13 in the MNG
2 Chronicles 13 in the MNT
2 Chronicles 13 in the MNT2
2 Chronicles 13 in the MRS1T
2 Chronicles 13 in the NAA
2 Chronicles 13 in the NASB
2 Chronicles 13 in the NBLA
2 Chronicles 13 in the NBS
2 Chronicles 13 in the NBVTP
2 Chronicles 13 in the NET2
2 Chronicles 13 in the NIV11
2 Chronicles 13 in the NNT
2 Chronicles 13 in the NNT2
2 Chronicles 13 in the NNT3
2 Chronicles 13 in the PDDPT
2 Chronicles 13 in the PFNT
2 Chronicles 13 in the RMNT
2 Chronicles 13 in the SBIAS
2 Chronicles 13 in the SBIBS
2 Chronicles 13 in the SBIBS2
2 Chronicles 13 in the SBICS
2 Chronicles 13 in the SBIDS
2 Chronicles 13 in the SBIGS
2 Chronicles 13 in the SBIHS
2 Chronicles 13 in the SBIIS
2 Chronicles 13 in the SBIIS2
2 Chronicles 13 in the SBIIS3
2 Chronicles 13 in the SBIKS
2 Chronicles 13 in the SBIKS2
2 Chronicles 13 in the SBIMS
2 Chronicles 13 in the SBIOS
2 Chronicles 13 in the SBIPS
2 Chronicles 13 in the SBISS
2 Chronicles 13 in the SBITS
2 Chronicles 13 in the SBITS2
2 Chronicles 13 in the SBITS3
2 Chronicles 13 in the SBITS4
2 Chronicles 13 in the SBIUS
2 Chronicles 13 in the SBIVS
2 Chronicles 13 in the SBT
2 Chronicles 13 in the SBT1E
2 Chronicles 13 in the SCHL
2 Chronicles 13 in the SNT
2 Chronicles 13 in the SUSU
2 Chronicles 13 in the SUSU2
2 Chronicles 13 in the SYNO
2 Chronicles 13 in the TBIAOTANT
2 Chronicles 13 in the TBT1E
2 Chronicles 13 in the TBT1E2
2 Chronicles 13 in the TFTIP
2 Chronicles 13 in the TFTU
2 Chronicles 13 in the TGNTATF3T
2 Chronicles 13 in the THAI
2 Chronicles 13 in the TNFD
2 Chronicles 13 in the TNT
2 Chronicles 13 in the TNTIK
2 Chronicles 13 in the TNTIL
2 Chronicles 13 in the TNTIN
2 Chronicles 13 in the TNTIP
2 Chronicles 13 in the TNTIZ
2 Chronicles 13 in the TOMA
2 Chronicles 13 in the TTENT
2 Chronicles 13 in the UBG
2 Chronicles 13 in the UGV
2 Chronicles 13 in the UGV2
2 Chronicles 13 in the UGV3
2 Chronicles 13 in the VBL
2 Chronicles 13 in the VDCC
2 Chronicles 13 in the YALU
2 Chronicles 13 in the YAPE
2 Chronicles 13 in the YBVTP
2 Chronicles 13 in the ZBP