Acts 5 (BOYCB)

1 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan. 2 Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli. 3 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà? 4 Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?” 5 Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́. 6 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín. 7 Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé. 8 Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?”Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.” 9 Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.” 10 Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bàá ọkọ rẹ̀. 11 Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. 12 A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni. 13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn. 14 Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i. 15 Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí ibùsùn àti àkéte kí òjìji Peteru ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ. 16 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá. 17 Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀. 18 Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. 19 Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde. 20 Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.” 21 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹmpili lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpéjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn aposteli wá. 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùṣọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn padà wá, wọn sísọ fún wọn pé, 23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.” 24 Nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí. 25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹmpili, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.” 26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́, ó sì mú àwọn aposteli wá. Wọn kò fi ipá mú wọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta. 27 Nígbà tí wọn sì mú àwọn aposteli dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlùfáà sì bi wọ́n léèrè. 28 Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni, síbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerusalẹmu, ẹ sì ń pète àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.” 29 Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ! 30 Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jesu dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. 31 Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aládé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. 32 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ṣe ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fi fún àwọn tí ó gbà á gbọ́.” 33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbèrò láti pa wọ́n. 34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gamalieli, Farisi àti amòfin, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn aposteli bì sẹ́yìn díẹ̀. 35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ kíyèsi ara yín lóhùn tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. 36 Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Teuda dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irinwó (400) ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pa á; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán. 37 Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Judasi ti Galili dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì ni ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká. 38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, ṣọ́ra fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣubú. 39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣubú; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà.” 40 Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n si lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jesu mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ. 41 Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀. 42 Ní ojoojúmọ́ nínú tẹmpili àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kun kíkọ́ni àti láti wàásù ìyìnrere náà pé Jesu ni Kristi.

In Other Versions

Acts 5 in the ANGEFD

Acts 5 in the ANTPNG2D

Acts 5 in the AS21

Acts 5 in the BAGH

Acts 5 in the BBPNG

Acts 5 in the BBT1E

Acts 5 in the BDS

Acts 5 in the BEV

Acts 5 in the BHAD

Acts 5 in the BIB

Acts 5 in the BLPT

Acts 5 in the BNT

Acts 5 in the BNTABOOT

Acts 5 in the BNTLV

Acts 5 in the BOATCB

Acts 5 in the BOATCB2

Acts 5 in the BOBCV

Acts 5 in the BOCNT

Acts 5 in the BOECS

Acts 5 in the BOGWICC

Acts 5 in the BOHCB

Acts 5 in the BOHCV

Acts 5 in the BOHLNT

Acts 5 in the BOHNTLTAL

Acts 5 in the BOICB

Acts 5 in the BOILNTAP

Acts 5 in the BOITCV

Acts 5 in the BOKCV

Acts 5 in the BOKCV2

Acts 5 in the BOKHWOG

Acts 5 in the BOKSSV

Acts 5 in the BOLCB

Acts 5 in the BOLCB2

Acts 5 in the BOMCV

Acts 5 in the BONAV

Acts 5 in the BONCB

Acts 5 in the BONLT

Acts 5 in the BONUT2

Acts 5 in the BOPLNT

Acts 5 in the BOSCB

Acts 5 in the BOSNC

Acts 5 in the BOTLNT

Acts 5 in the BOVCB

Acts 5 in the BPBB

Acts 5 in the BPH

Acts 5 in the BSB

Acts 5 in the CCB

Acts 5 in the CUV

Acts 5 in the CUVS

Acts 5 in the DBT

Acts 5 in the DGDNT

Acts 5 in the DHNT

Acts 5 in the DNT

Acts 5 in the ELBE

Acts 5 in the EMTV

Acts 5 in the ESV

Acts 5 in the FBV

Acts 5 in the FEB

Acts 5 in the GGMNT

Acts 5 in the GNT

Acts 5 in the HARY

Acts 5 in the HNT

Acts 5 in the IRVA

Acts 5 in the IRVB

Acts 5 in the IRVG

Acts 5 in the IRVH

Acts 5 in the IRVK

Acts 5 in the IRVM

Acts 5 in the IRVM2

Acts 5 in the IRVO

Acts 5 in the IRVP

Acts 5 in the IRVT

Acts 5 in the IRVT2

Acts 5 in the IRVU

Acts 5 in the ISVN

Acts 5 in the JSNT

Acts 5 in the KAPI

Acts 5 in the KBT1ETNIK

Acts 5 in the KBV

Acts 5 in the KJV

Acts 5 in the KNFD

Acts 5 in the LBA

Acts 5 in the LBLA

Acts 5 in the LNT

Acts 5 in the LSV

Acts 5 in the MAAL

Acts 5 in the MBV

Acts 5 in the MBV2

Acts 5 in the MHNT

Acts 5 in the MKNFD

Acts 5 in the MNG

Acts 5 in the MNT

Acts 5 in the MNT2

Acts 5 in the MRS1T

Acts 5 in the NAA

Acts 5 in the NASB

Acts 5 in the NBLA

Acts 5 in the NBS

Acts 5 in the NBVTP

Acts 5 in the NET2

Acts 5 in the NIV11

Acts 5 in the NNT

Acts 5 in the NNT2

Acts 5 in the NNT3

Acts 5 in the PDDPT

Acts 5 in the PFNT

Acts 5 in the RMNT

Acts 5 in the SBIAS

Acts 5 in the SBIBS

Acts 5 in the SBIBS2

Acts 5 in the SBICS

Acts 5 in the SBIDS

Acts 5 in the SBIGS

Acts 5 in the SBIHS

Acts 5 in the SBIIS

Acts 5 in the SBIIS2

Acts 5 in the SBIIS3

Acts 5 in the SBIKS

Acts 5 in the SBIKS2

Acts 5 in the SBIMS

Acts 5 in the SBIOS

Acts 5 in the SBIPS

Acts 5 in the SBISS

Acts 5 in the SBITS

Acts 5 in the SBITS2

Acts 5 in the SBITS3

Acts 5 in the SBITS4

Acts 5 in the SBIUS

Acts 5 in the SBIVS

Acts 5 in the SBT

Acts 5 in the SBT1E

Acts 5 in the SCHL

Acts 5 in the SNT

Acts 5 in the SUSU

Acts 5 in the SUSU2

Acts 5 in the SYNO

Acts 5 in the TBIAOTANT

Acts 5 in the TBT1E

Acts 5 in the TBT1E2

Acts 5 in the TFTIP

Acts 5 in the TFTU

Acts 5 in the TGNTATF3T

Acts 5 in the THAI

Acts 5 in the TNFD

Acts 5 in the TNT

Acts 5 in the TNTIK

Acts 5 in the TNTIL

Acts 5 in the TNTIN

Acts 5 in the TNTIP

Acts 5 in the TNTIZ

Acts 5 in the TOMA

Acts 5 in the TTENT

Acts 5 in the UBG

Acts 5 in the UGV

Acts 5 in the UGV2

Acts 5 in the UGV3

Acts 5 in the VBL

Acts 5 in the VDCC

Acts 5 in the YALU

Acts 5 in the YAPE

Acts 5 in the YBVTP

Acts 5 in the ZBP