Exodus 15 (BOYCB)
1 Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLÚWA,Èmi yóò kọrin sí OLÚWA,nítorí òun pọ̀ ní ògo.Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn únni ó ti sọ sínú Òkun. 2 OLÚWA ni agbára àti orin mi;òun ti di Olùgbàlà mi,òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín,Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. 3 Ológun ni OLÚWA, OLÚWA ni orúkọ rẹ, 4 kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ni ó mú wọ inú Òkun.Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọni ó rì sínú Òkun Pupa. 5 Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta. 6 “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLÚWA,pọ̀ ní agbára.Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLÚWA,fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú. 7 “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbiìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko. 8 Pẹ̀lú èémí imú rẹ niomi fi ń wọ́jọ pọ̀.Ìṣàn omi dìde dúró bí odi;ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun. 9 Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé,‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn.èmi ó pín ìkógun;èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn.Èmi yóò fa idà mi yọ,ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’ 10 Ìwọ fẹ́ èémí rẹ,òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀.Wọ́n rì bí òjéni àárín omi ńlá. 11 Ta ni nínú àwọn òrìṣàtó dàbí rẹ, OLÚWA?Ta ló dàbí rẹ:ní títóbi,ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn,tí ń ṣe ohun ìyanu? 12 “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ,ilẹ̀ si gbé wọn mì. 13 Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í sákí Ìwọ ṣe amọ̀nààwọn ènìyàn náà tí Ìwọ ti rà padà.Nínú agbára rẹ Ìwọ yóò tọ́ wọn,lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́. 14 Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì.Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia. 15 Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu,àwọn olórí Moabu yóò wárìrì.Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù. 16 Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n, nítorínína títóbi apá rẹ̀wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta,títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, OLÚWA,títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá. 17 Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́nni orí òkè ti ìwọ jogún,ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, OLÚWA.Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, OLÚWA. 18 “OLÚWA yóò jẹ ọbaláé àti láéláé.” 19 Nígbà ti ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ inú Òkun, OLÚWA mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá. 20 Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó. 21 Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé,“Ẹ kọrin sí OLÚWA,nítorí òun ni ológo jùlọ.Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún,ni òun bi ṣubú sínú Òkun.” 22 Nígbà náà ni Mose ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Òkun Pupa lọ sínú ijù Ṣuri. Wọ́n lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi. 23 Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò. (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò.) 24 Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?” 25 Mose sì ké pe OLÚWA, OLÚWA sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn.Níbẹ̀ ni OLÚWA ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò. 26 Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin OLÚWA Ọlọ́run, ti ìwọ sì ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn ààrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Ejibiti wá sí ara rẹ, nítorí Èmi ni OLÚWA ti ó mú ọ láradá.” 27 Nígbà ti wọ́n dé Elimu, níbi ti kànga omi méjìlá àti àádọ́rin ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ni etí omi.
In Other Versions
Exodus 15 in the ANGEFD
Exodus 15 in the ANTPNG2D
Exodus 15 in the AS21
Exodus 15 in the BAGH
Exodus 15 in the BBPNG
Exodus 15 in the BBT1E
Exodus 15 in the BDS
Exodus 15 in the BEV
Exodus 15 in the BHAD
Exodus 15 in the BIB
Exodus 15 in the BLPT
Exodus 15 in the BNT
Exodus 15 in the BNTABOOT
Exodus 15 in the BNTLV
Exodus 15 in the BOATCB
Exodus 15 in the BOATCB2
Exodus 15 in the BOBCV
Exodus 15 in the BOCNT
Exodus 15 in the BOECS
Exodus 15 in the BOGWICC
Exodus 15 in the BOHCB
Exodus 15 in the BOHCV
Exodus 15 in the BOHLNT
Exodus 15 in the BOHNTLTAL
Exodus 15 in the BOICB
Exodus 15 in the BOILNTAP
Exodus 15 in the BOITCV
Exodus 15 in the BOKCV
Exodus 15 in the BOKCV2
Exodus 15 in the BOKHWOG
Exodus 15 in the BOKSSV
Exodus 15 in the BOLCB
Exodus 15 in the BOLCB2
Exodus 15 in the BOMCV
Exodus 15 in the BONAV
Exodus 15 in the BONCB
Exodus 15 in the BONLT
Exodus 15 in the BONUT2
Exodus 15 in the BOPLNT
Exodus 15 in the BOSCB
Exodus 15 in the BOSNC
Exodus 15 in the BOTLNT
Exodus 15 in the BOVCB
Exodus 15 in the BPBB
Exodus 15 in the BPH
Exodus 15 in the BSB
Exodus 15 in the CCB
Exodus 15 in the CUV
Exodus 15 in the CUVS
Exodus 15 in the DBT
Exodus 15 in the DGDNT
Exodus 15 in the DHNT
Exodus 15 in the DNT
Exodus 15 in the ELBE
Exodus 15 in the EMTV
Exodus 15 in the ESV
Exodus 15 in the FBV
Exodus 15 in the FEB
Exodus 15 in the GGMNT
Exodus 15 in the GNT
Exodus 15 in the HARY
Exodus 15 in the HNT
Exodus 15 in the IRVA
Exodus 15 in the IRVB
Exodus 15 in the IRVG
Exodus 15 in the IRVH
Exodus 15 in the IRVK
Exodus 15 in the IRVM
Exodus 15 in the IRVM2
Exodus 15 in the IRVO
Exodus 15 in the IRVP
Exodus 15 in the IRVT
Exodus 15 in the IRVT2
Exodus 15 in the IRVU
Exodus 15 in the ISVN
Exodus 15 in the JSNT
Exodus 15 in the KAPI
Exodus 15 in the KBT1ETNIK
Exodus 15 in the KBV
Exodus 15 in the KJV
Exodus 15 in the KNFD
Exodus 15 in the LBA
Exodus 15 in the LBLA
Exodus 15 in the LNT
Exodus 15 in the LSV
Exodus 15 in the MAAL
Exodus 15 in the MBV
Exodus 15 in the MBV2
Exodus 15 in the MHNT
Exodus 15 in the MKNFD
Exodus 15 in the MNG
Exodus 15 in the MNT
Exodus 15 in the MNT2
Exodus 15 in the MRS1T
Exodus 15 in the NAA
Exodus 15 in the NASB
Exodus 15 in the NBLA
Exodus 15 in the NBS
Exodus 15 in the NBVTP
Exodus 15 in the NET2
Exodus 15 in the NIV11
Exodus 15 in the NNT
Exodus 15 in the NNT2
Exodus 15 in the NNT3
Exodus 15 in the PDDPT
Exodus 15 in the PFNT
Exodus 15 in the RMNT
Exodus 15 in the SBIAS
Exodus 15 in the SBIBS
Exodus 15 in the SBIBS2
Exodus 15 in the SBICS
Exodus 15 in the SBIDS
Exodus 15 in the SBIGS
Exodus 15 in the SBIHS
Exodus 15 in the SBIIS
Exodus 15 in the SBIIS2
Exodus 15 in the SBIIS3
Exodus 15 in the SBIKS
Exodus 15 in the SBIKS2
Exodus 15 in the SBIMS
Exodus 15 in the SBIOS
Exodus 15 in the SBIPS
Exodus 15 in the SBISS
Exodus 15 in the SBITS
Exodus 15 in the SBITS2
Exodus 15 in the SBITS3
Exodus 15 in the SBITS4
Exodus 15 in the SBIUS
Exodus 15 in the SBIVS
Exodus 15 in the SBT
Exodus 15 in the SBT1E
Exodus 15 in the SCHL
Exodus 15 in the SNT
Exodus 15 in the SUSU
Exodus 15 in the SUSU2
Exodus 15 in the SYNO
Exodus 15 in the TBIAOTANT
Exodus 15 in the TBT1E
Exodus 15 in the TBT1E2
Exodus 15 in the TFTIP
Exodus 15 in the TFTU
Exodus 15 in the TGNTATF3T
Exodus 15 in the THAI
Exodus 15 in the TNFD
Exodus 15 in the TNT
Exodus 15 in the TNTIK
Exodus 15 in the TNTIL
Exodus 15 in the TNTIN
Exodus 15 in the TNTIP
Exodus 15 in the TNTIZ
Exodus 15 in the TOMA
Exodus 15 in the TTENT
Exodus 15 in the UBG
Exodus 15 in the UGV
Exodus 15 in the UGV2
Exodus 15 in the UGV3
Exodus 15 in the VBL
Exodus 15 in the VDCC
Exodus 15 in the YALU
Exodus 15 in the YAPE
Exodus 15 in the YBVTP
Exodus 15 in the ZBP