Galatians 3 (BOYCB)
1 Ẹ̀yin aláìnírònú ará Galatia! Ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jesu Kristi hàn gbangba láàrín yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 2 Kìkì èyí ni mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ yín, nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mí bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́? 3 Báyìí ni ẹ̀yin ṣe jẹ òmùgọ̀ tó bí? Ẹ̀yin tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ yín nípa ti Ẹ̀mí, ṣé a ti wá sọ yín di pípé nípa ti ara ni? 4 Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni. 5 Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́? 6 Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.” 7 Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Abrahamu. 8 Bí ìwé mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìyìnrere ṣáájú fún Abrahamu, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” 9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkún fún pẹ̀lú Abrahamu olódodo. 10 Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n”. 11 Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.” 12 Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” 13 Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.” 14 Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́. 15 Ará, èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ènìyàn ti a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́. 16 Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣọ wí pé, “fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀,” bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, “àti fún irú-ọmọ rẹ̀,” èyí tí í ṣe Kristi. 17 Èyí tí mò ń wí ni pé: májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣàájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀nlénírinwó (430) ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, kí ó sì mú ìlérí náà di aláìlágbára. 18 Nítorí bí ogún náà bá dúró lórí ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí í òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Abrahamu nípa ìlérí. 19 Ǹjẹ́ kí ha ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipasẹ̀ àwọn angẹli ṣe ìlànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá. 20 Ǹjẹ́ onílàjà kì í ṣe alárinà ti ẹnìkan, ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run. 21 Nítorí náà òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọ ni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà. 22 Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23 Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fihàn. 24 Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́. 25 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùtọ́jú mọ́. 26 Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 27 Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti bamitiisi sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀. 28 Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu. 29 Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Abrahamu, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.
In Other Versions
Galatians 3 in the ANGEFD
Galatians 3 in the ANTPNG2D
Galatians 3 in the AS21
Galatians 3 in the BAGH
Galatians 3 in the BBPNG
Galatians 3 in the BBT1E
Galatians 3 in the BDS
Galatians 3 in the BEV
Galatians 3 in the BHAD
Galatians 3 in the BIB
Galatians 3 in the BLPT
Galatians 3 in the BNT
Galatians 3 in the BNTABOOT
Galatians 3 in the BNTLV
Galatians 3 in the BOATCB
Galatians 3 in the BOATCB2
Galatians 3 in the BOBCV
Galatians 3 in the BOCNT
Galatians 3 in the BOECS
Galatians 3 in the BOGWICC
Galatians 3 in the BOHCB
Galatians 3 in the BOHCV
Galatians 3 in the BOHLNT
Galatians 3 in the BOHNTLTAL
Galatians 3 in the BOICB
Galatians 3 in the BOILNTAP
Galatians 3 in the BOITCV
Galatians 3 in the BOKCV
Galatians 3 in the BOKCV2
Galatians 3 in the BOKHWOG
Galatians 3 in the BOKSSV
Galatians 3 in the BOLCB
Galatians 3 in the BOLCB2
Galatians 3 in the BOMCV
Galatians 3 in the BONAV
Galatians 3 in the BONCB
Galatians 3 in the BONLT
Galatians 3 in the BONUT2
Galatians 3 in the BOPLNT
Galatians 3 in the BOSCB
Galatians 3 in the BOSNC
Galatians 3 in the BOTLNT
Galatians 3 in the BOVCB
Galatians 3 in the BPBB
Galatians 3 in the BPH
Galatians 3 in the BSB
Galatians 3 in the CCB
Galatians 3 in the CUV
Galatians 3 in the CUVS
Galatians 3 in the DBT
Galatians 3 in the DGDNT
Galatians 3 in the DHNT
Galatians 3 in the DNT
Galatians 3 in the ELBE
Galatians 3 in the EMTV
Galatians 3 in the ESV
Galatians 3 in the FBV
Galatians 3 in the FEB
Galatians 3 in the GGMNT
Galatians 3 in the GNT
Galatians 3 in the HARY
Galatians 3 in the HNT
Galatians 3 in the IRVA
Galatians 3 in the IRVB
Galatians 3 in the IRVG
Galatians 3 in the IRVH
Galatians 3 in the IRVK
Galatians 3 in the IRVM
Galatians 3 in the IRVM2
Galatians 3 in the IRVO
Galatians 3 in the IRVP
Galatians 3 in the IRVT
Galatians 3 in the IRVT2
Galatians 3 in the IRVU
Galatians 3 in the ISVN
Galatians 3 in the JSNT
Galatians 3 in the KAPI
Galatians 3 in the KBT1ETNIK
Galatians 3 in the KBV
Galatians 3 in the KJV
Galatians 3 in the KNFD
Galatians 3 in the LBA
Galatians 3 in the LBLA
Galatians 3 in the LNT
Galatians 3 in the LSV
Galatians 3 in the MAAL
Galatians 3 in the MBV
Galatians 3 in the MBV2
Galatians 3 in the MHNT
Galatians 3 in the MKNFD
Galatians 3 in the MNG
Galatians 3 in the MNT
Galatians 3 in the MNT2
Galatians 3 in the MRS1T
Galatians 3 in the NAA
Galatians 3 in the NASB
Galatians 3 in the NBLA
Galatians 3 in the NBS
Galatians 3 in the NBVTP
Galatians 3 in the NET2
Galatians 3 in the NIV11
Galatians 3 in the NNT
Galatians 3 in the NNT2
Galatians 3 in the NNT3
Galatians 3 in the PDDPT
Galatians 3 in the PFNT
Galatians 3 in the RMNT
Galatians 3 in the SBIAS
Galatians 3 in the SBIBS
Galatians 3 in the SBIBS2
Galatians 3 in the SBICS
Galatians 3 in the SBIDS
Galatians 3 in the SBIGS
Galatians 3 in the SBIHS
Galatians 3 in the SBIIS
Galatians 3 in the SBIIS2
Galatians 3 in the SBIIS3
Galatians 3 in the SBIKS
Galatians 3 in the SBIKS2
Galatians 3 in the SBIMS
Galatians 3 in the SBIOS
Galatians 3 in the SBIPS
Galatians 3 in the SBISS
Galatians 3 in the SBITS
Galatians 3 in the SBITS2
Galatians 3 in the SBITS3
Galatians 3 in the SBITS4
Galatians 3 in the SBIUS
Galatians 3 in the SBIVS
Galatians 3 in the SBT
Galatians 3 in the SBT1E
Galatians 3 in the SCHL
Galatians 3 in the SNT
Galatians 3 in the SUSU
Galatians 3 in the SUSU2
Galatians 3 in the SYNO
Galatians 3 in the TBIAOTANT
Galatians 3 in the TBT1E
Galatians 3 in the TBT1E2
Galatians 3 in the TFTIP
Galatians 3 in the TFTU
Galatians 3 in the TGNTATF3T
Galatians 3 in the THAI
Galatians 3 in the TNFD
Galatians 3 in the TNT
Galatians 3 in the TNTIK
Galatians 3 in the TNTIL
Galatians 3 in the TNTIN
Galatians 3 in the TNTIP
Galatians 3 in the TNTIZ
Galatians 3 in the TOMA
Galatians 3 in the TTENT
Galatians 3 in the UBG
Galatians 3 in the UGV
Galatians 3 in the UGV2
Galatians 3 in the UGV3
Galatians 3 in the VBL
Galatians 3 in the VDCC
Galatians 3 in the YALU
Galatians 3 in the YAPE
Galatians 3 in the YBVTP
Galatians 3 in the ZBP