Hebrews 12 (BOYCB)
1 Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, 2 kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. 3 Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìsọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín. 4 Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. 5 Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,“Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa,kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí, 6 nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí,a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.” 7 Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí, Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? 8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. 9 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n Òun tọ́ wa fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo. 12 Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera, 13 “Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn. 14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa. 15 Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí gbòǹgbò ìkorò kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́. 16 Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀. 17 Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi. 18 Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì. 19 Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ sí i fún wọn mọ́, 20 nítorí pé wọn kò lè gba ohun tí ó paláṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni ó fi ara kan òkè náà, a ó sọ ọ́ ni òkúta.” 21 Ìran náà sì lẹ́rù to bẹ́ẹ̀ tí Mose wí pé, “Ẹ̀rù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.” 22 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Sioni, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerusalẹmu ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn angẹli àìníye, 23 si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, 24 àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ. 25 Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélòó mélòó ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀yìndà sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá, 26 ohùn ẹni tí ó mi ayé nígbà náà, ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.” 27 Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀. 28 Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. 29 Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”
In Other Versions
Hebrews 12 in the ANGEFD
Hebrews 12 in the ANTPNG2D
Hebrews 12 in the AS21
Hebrews 12 in the BAGH
Hebrews 12 in the BBPNG
Hebrews 12 in the BBT1E
Hebrews 12 in the BDS
Hebrews 12 in the BEV
Hebrews 12 in the BHAD
Hebrews 12 in the BIB
Hebrews 12 in the BLPT
Hebrews 12 in the BNT
Hebrews 12 in the BNTABOOT
Hebrews 12 in the BNTLV
Hebrews 12 in the BOATCB
Hebrews 12 in the BOATCB2
Hebrews 12 in the BOBCV
Hebrews 12 in the BOCNT
Hebrews 12 in the BOECS
Hebrews 12 in the BOGWICC
Hebrews 12 in the BOHCB
Hebrews 12 in the BOHCV
Hebrews 12 in the BOHLNT
Hebrews 12 in the BOHNTLTAL
Hebrews 12 in the BOICB
Hebrews 12 in the BOILNTAP
Hebrews 12 in the BOITCV
Hebrews 12 in the BOKCV
Hebrews 12 in the BOKCV2
Hebrews 12 in the BOKHWOG
Hebrews 12 in the BOKSSV
Hebrews 12 in the BOLCB
Hebrews 12 in the BOLCB2
Hebrews 12 in the BOMCV
Hebrews 12 in the BONAV
Hebrews 12 in the BONCB
Hebrews 12 in the BONLT
Hebrews 12 in the BONUT2
Hebrews 12 in the BOPLNT
Hebrews 12 in the BOSCB
Hebrews 12 in the BOSNC
Hebrews 12 in the BOTLNT
Hebrews 12 in the BOVCB
Hebrews 12 in the BPBB
Hebrews 12 in the BPH
Hebrews 12 in the BSB
Hebrews 12 in the CCB
Hebrews 12 in the CUV
Hebrews 12 in the CUVS
Hebrews 12 in the DBT
Hebrews 12 in the DGDNT
Hebrews 12 in the DHNT
Hebrews 12 in the DNT
Hebrews 12 in the ELBE
Hebrews 12 in the EMTV
Hebrews 12 in the ESV
Hebrews 12 in the FBV
Hebrews 12 in the FEB
Hebrews 12 in the GGMNT
Hebrews 12 in the GNT
Hebrews 12 in the HARY
Hebrews 12 in the HNT
Hebrews 12 in the IRVA
Hebrews 12 in the IRVB
Hebrews 12 in the IRVG
Hebrews 12 in the IRVH
Hebrews 12 in the IRVK
Hebrews 12 in the IRVM
Hebrews 12 in the IRVM2
Hebrews 12 in the IRVO
Hebrews 12 in the IRVP
Hebrews 12 in the IRVT
Hebrews 12 in the IRVT2
Hebrews 12 in the IRVU
Hebrews 12 in the ISVN
Hebrews 12 in the JSNT
Hebrews 12 in the KAPI
Hebrews 12 in the KBT1ETNIK
Hebrews 12 in the KBV
Hebrews 12 in the KJV
Hebrews 12 in the KNFD
Hebrews 12 in the LBA
Hebrews 12 in the LBLA
Hebrews 12 in the LNT
Hebrews 12 in the LSV
Hebrews 12 in the MAAL
Hebrews 12 in the MBV
Hebrews 12 in the MBV2
Hebrews 12 in the MHNT
Hebrews 12 in the MKNFD
Hebrews 12 in the MNG
Hebrews 12 in the MNT
Hebrews 12 in the MNT2
Hebrews 12 in the MRS1T
Hebrews 12 in the NAA
Hebrews 12 in the NASB
Hebrews 12 in the NBLA
Hebrews 12 in the NBS
Hebrews 12 in the NBVTP
Hebrews 12 in the NET2
Hebrews 12 in the NIV11
Hebrews 12 in the NNT
Hebrews 12 in the NNT2
Hebrews 12 in the NNT3
Hebrews 12 in the PDDPT
Hebrews 12 in the PFNT
Hebrews 12 in the RMNT
Hebrews 12 in the SBIAS
Hebrews 12 in the SBIBS
Hebrews 12 in the SBIBS2
Hebrews 12 in the SBICS
Hebrews 12 in the SBIDS
Hebrews 12 in the SBIGS
Hebrews 12 in the SBIHS
Hebrews 12 in the SBIIS
Hebrews 12 in the SBIIS2
Hebrews 12 in the SBIIS3
Hebrews 12 in the SBIKS
Hebrews 12 in the SBIKS2
Hebrews 12 in the SBIMS
Hebrews 12 in the SBIOS
Hebrews 12 in the SBIPS
Hebrews 12 in the SBISS
Hebrews 12 in the SBITS
Hebrews 12 in the SBITS2
Hebrews 12 in the SBITS3
Hebrews 12 in the SBITS4
Hebrews 12 in the SBIUS
Hebrews 12 in the SBIVS
Hebrews 12 in the SBT
Hebrews 12 in the SBT1E
Hebrews 12 in the SCHL
Hebrews 12 in the SNT
Hebrews 12 in the SUSU
Hebrews 12 in the SUSU2
Hebrews 12 in the SYNO
Hebrews 12 in the TBIAOTANT
Hebrews 12 in the TBT1E
Hebrews 12 in the TBT1E2
Hebrews 12 in the TFTIP
Hebrews 12 in the TFTU
Hebrews 12 in the TGNTATF3T
Hebrews 12 in the THAI
Hebrews 12 in the TNFD
Hebrews 12 in the TNT
Hebrews 12 in the TNTIK
Hebrews 12 in the TNTIL
Hebrews 12 in the TNTIN
Hebrews 12 in the TNTIP
Hebrews 12 in the TNTIZ
Hebrews 12 in the TOMA
Hebrews 12 in the TTENT
Hebrews 12 in the UBG
Hebrews 12 in the UGV
Hebrews 12 in the UGV2
Hebrews 12 in the UGV3
Hebrews 12 in the VBL
Hebrews 12 in the VDCC
Hebrews 12 in the YALU
Hebrews 12 in the YAPE
Hebrews 12 in the YBVTP
Hebrews 12 in the ZBP