Hebrews 6 (BOYCB)
1 Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run, 2 ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitiisi, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun. 3 Èyí ní àwa yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́. 4 Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́, 5 tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, 6 láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan Ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba. 7 Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hu ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run. 8 Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná. 9 Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀. 10 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. 11 Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin. 12 Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí. 13 Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Abrahamu, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé, 14 “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.” 15 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí Abrahamu fi sùúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà. 16 Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀. 17 Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn. 18 Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin. 19 Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé; 20 níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.
In Other Versions
Hebrews 6 in the ANGEFD
Hebrews 6 in the ANTPNG2D
Hebrews 6 in the AS21
Hebrews 6 in the BAGH
Hebrews 6 in the BBPNG
Hebrews 6 in the BBT1E
Hebrews 6 in the BDS
Hebrews 6 in the BEV
Hebrews 6 in the BHAD
Hebrews 6 in the BIB
Hebrews 6 in the BLPT
Hebrews 6 in the BNT
Hebrews 6 in the BNTABOOT
Hebrews 6 in the BNTLV
Hebrews 6 in the BOATCB
Hebrews 6 in the BOATCB2
Hebrews 6 in the BOBCV
Hebrews 6 in the BOCNT
Hebrews 6 in the BOECS
Hebrews 6 in the BOGWICC
Hebrews 6 in the BOHCB
Hebrews 6 in the BOHCV
Hebrews 6 in the BOHLNT
Hebrews 6 in the BOHNTLTAL
Hebrews 6 in the BOICB
Hebrews 6 in the BOILNTAP
Hebrews 6 in the BOITCV
Hebrews 6 in the BOKCV
Hebrews 6 in the BOKCV2
Hebrews 6 in the BOKHWOG
Hebrews 6 in the BOKSSV
Hebrews 6 in the BOLCB
Hebrews 6 in the BOLCB2
Hebrews 6 in the BOMCV
Hebrews 6 in the BONAV
Hebrews 6 in the BONCB
Hebrews 6 in the BONLT
Hebrews 6 in the BONUT2
Hebrews 6 in the BOPLNT
Hebrews 6 in the BOSCB
Hebrews 6 in the BOSNC
Hebrews 6 in the BOTLNT
Hebrews 6 in the BOVCB
Hebrews 6 in the BPBB
Hebrews 6 in the BPH
Hebrews 6 in the BSB
Hebrews 6 in the CCB
Hebrews 6 in the CUV
Hebrews 6 in the CUVS
Hebrews 6 in the DBT
Hebrews 6 in the DGDNT
Hebrews 6 in the DHNT
Hebrews 6 in the DNT
Hebrews 6 in the ELBE
Hebrews 6 in the EMTV
Hebrews 6 in the ESV
Hebrews 6 in the FBV
Hebrews 6 in the FEB
Hebrews 6 in the GGMNT
Hebrews 6 in the GNT
Hebrews 6 in the HARY
Hebrews 6 in the HNT
Hebrews 6 in the IRVA
Hebrews 6 in the IRVB
Hebrews 6 in the IRVG
Hebrews 6 in the IRVH
Hebrews 6 in the IRVK
Hebrews 6 in the IRVM
Hebrews 6 in the IRVM2
Hebrews 6 in the IRVO
Hebrews 6 in the IRVP
Hebrews 6 in the IRVT
Hebrews 6 in the IRVT2
Hebrews 6 in the IRVU
Hebrews 6 in the ISVN
Hebrews 6 in the JSNT
Hebrews 6 in the KAPI
Hebrews 6 in the KBT1ETNIK
Hebrews 6 in the KBV
Hebrews 6 in the KJV
Hebrews 6 in the KNFD
Hebrews 6 in the LBA
Hebrews 6 in the LBLA
Hebrews 6 in the LNT
Hebrews 6 in the LSV
Hebrews 6 in the MAAL
Hebrews 6 in the MBV
Hebrews 6 in the MBV2
Hebrews 6 in the MHNT
Hebrews 6 in the MKNFD
Hebrews 6 in the MNG
Hebrews 6 in the MNT
Hebrews 6 in the MNT2
Hebrews 6 in the MRS1T
Hebrews 6 in the NAA
Hebrews 6 in the NASB
Hebrews 6 in the NBLA
Hebrews 6 in the NBS
Hebrews 6 in the NBVTP
Hebrews 6 in the NET2
Hebrews 6 in the NIV11
Hebrews 6 in the NNT
Hebrews 6 in the NNT2
Hebrews 6 in the NNT3
Hebrews 6 in the PDDPT
Hebrews 6 in the PFNT
Hebrews 6 in the RMNT
Hebrews 6 in the SBIAS
Hebrews 6 in the SBIBS
Hebrews 6 in the SBIBS2
Hebrews 6 in the SBICS
Hebrews 6 in the SBIDS
Hebrews 6 in the SBIGS
Hebrews 6 in the SBIHS
Hebrews 6 in the SBIIS
Hebrews 6 in the SBIIS2
Hebrews 6 in the SBIIS3
Hebrews 6 in the SBIKS
Hebrews 6 in the SBIKS2
Hebrews 6 in the SBIMS
Hebrews 6 in the SBIOS
Hebrews 6 in the SBIPS
Hebrews 6 in the SBISS
Hebrews 6 in the SBITS
Hebrews 6 in the SBITS2
Hebrews 6 in the SBITS3
Hebrews 6 in the SBITS4
Hebrews 6 in the SBIUS
Hebrews 6 in the SBIVS
Hebrews 6 in the SBT
Hebrews 6 in the SBT1E
Hebrews 6 in the SCHL
Hebrews 6 in the SNT
Hebrews 6 in the SUSU
Hebrews 6 in the SUSU2
Hebrews 6 in the SYNO
Hebrews 6 in the TBIAOTANT
Hebrews 6 in the TBT1E
Hebrews 6 in the TBT1E2
Hebrews 6 in the TFTIP
Hebrews 6 in the TFTU
Hebrews 6 in the TGNTATF3T
Hebrews 6 in the THAI
Hebrews 6 in the TNFD
Hebrews 6 in the TNT
Hebrews 6 in the TNTIK
Hebrews 6 in the TNTIL
Hebrews 6 in the TNTIN
Hebrews 6 in the TNTIP
Hebrews 6 in the TNTIZ
Hebrews 6 in the TOMA
Hebrews 6 in the TTENT
Hebrews 6 in the UBG
Hebrews 6 in the UGV
Hebrews 6 in the UGV2
Hebrews 6 in the UGV3
Hebrews 6 in the VBL
Hebrews 6 in the VDCC
Hebrews 6 in the YALU
Hebrews 6 in the YAPE
Hebrews 6 in the YBVTP
Hebrews 6 in the ZBP