Hebrews 7 (BOYCB)
1 Nítorí Melkisedeki yìí, ọba Salẹmu, àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹni tí ó pàdé Abrahamu bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un, 2 ẹni tí Abrahamu sì pín ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún. Ní ọ̀nà èkínní orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “ọba òdodo”; àti lẹ́yìn náà pẹ̀lú, “ọba Salẹmu,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.” 3 Láìní baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí Ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí. 4 Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Abrahamu baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún. 5 Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Lefi, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Abrahamu jáde. 6 Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Abrahamu, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí, 7 láìsí ìjiyàn rárá ẹni kò tó ẹni tí à ń súre fún láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ju ni. 8 Ni apá kan, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láààyè nì. 9 Àti bí a ti lè wí, Lefi pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Abrahamu. 10 Nítorí o sá à sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melkisedeki pàdé rẹ̀. 11 Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Lefi (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kín ni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melkisedeki, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Aaroni? 12 Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin. 13 Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kò tì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ. 14 Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mose kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà. 15 Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà mìíràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melkisedeki. 16 Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin. 17 Nítorí a jẹ́rìí pé:“Ìwọ ni àlùfáà títí láéní ipasẹ̀ ti Melkisedeki.” 18 Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìlera àti àìlérè rẹ̀. 19 (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run. 20 Níwọ́n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, 21 ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé,“Olúwa búra,kí yóò sì yí padà:‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé.’ ” 22 Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù. 23 Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú. 24 Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ ní ipò. 25 Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láààyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn. 26 Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ. 27 Ẹni tí kò ní láti máa rú ẹbọ lójoojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ́yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ. 28 Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà; ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ́yìn òfin, ó fi ọmọ jẹ; ẹni tí a sọ di pípé títí láé.
In Other Versions
Hebrews 7 in the ANGEFD
Hebrews 7 in the ANTPNG2D
Hebrews 7 in the AS21
Hebrews 7 in the BAGH
Hebrews 7 in the BBPNG
Hebrews 7 in the BBT1E
Hebrews 7 in the BDS
Hebrews 7 in the BEV
Hebrews 7 in the BHAD
Hebrews 7 in the BIB
Hebrews 7 in the BLPT
Hebrews 7 in the BNT
Hebrews 7 in the BNTABOOT
Hebrews 7 in the BNTLV
Hebrews 7 in the BOATCB
Hebrews 7 in the BOATCB2
Hebrews 7 in the BOBCV
Hebrews 7 in the BOCNT
Hebrews 7 in the BOECS
Hebrews 7 in the BOGWICC
Hebrews 7 in the BOHCB
Hebrews 7 in the BOHCV
Hebrews 7 in the BOHLNT
Hebrews 7 in the BOHNTLTAL
Hebrews 7 in the BOICB
Hebrews 7 in the BOILNTAP
Hebrews 7 in the BOITCV
Hebrews 7 in the BOKCV
Hebrews 7 in the BOKCV2
Hebrews 7 in the BOKHWOG
Hebrews 7 in the BOKSSV
Hebrews 7 in the BOLCB
Hebrews 7 in the BOLCB2
Hebrews 7 in the BOMCV
Hebrews 7 in the BONAV
Hebrews 7 in the BONCB
Hebrews 7 in the BONLT
Hebrews 7 in the BONUT2
Hebrews 7 in the BOPLNT
Hebrews 7 in the BOSCB
Hebrews 7 in the BOSNC
Hebrews 7 in the BOTLNT
Hebrews 7 in the BOVCB
Hebrews 7 in the BPBB
Hebrews 7 in the BPH
Hebrews 7 in the BSB
Hebrews 7 in the CCB
Hebrews 7 in the CUV
Hebrews 7 in the CUVS
Hebrews 7 in the DBT
Hebrews 7 in the DGDNT
Hebrews 7 in the DHNT
Hebrews 7 in the DNT
Hebrews 7 in the ELBE
Hebrews 7 in the EMTV
Hebrews 7 in the ESV
Hebrews 7 in the FBV
Hebrews 7 in the FEB
Hebrews 7 in the GGMNT
Hebrews 7 in the GNT
Hebrews 7 in the HARY
Hebrews 7 in the HNT
Hebrews 7 in the IRVA
Hebrews 7 in the IRVB
Hebrews 7 in the IRVG
Hebrews 7 in the IRVH
Hebrews 7 in the IRVK
Hebrews 7 in the IRVM
Hebrews 7 in the IRVM2
Hebrews 7 in the IRVO
Hebrews 7 in the IRVP
Hebrews 7 in the IRVT
Hebrews 7 in the IRVT2
Hebrews 7 in the IRVU
Hebrews 7 in the ISVN
Hebrews 7 in the JSNT
Hebrews 7 in the KAPI
Hebrews 7 in the KBT1ETNIK
Hebrews 7 in the KBV
Hebrews 7 in the KJV
Hebrews 7 in the KNFD
Hebrews 7 in the LBA
Hebrews 7 in the LBLA
Hebrews 7 in the LNT
Hebrews 7 in the LSV
Hebrews 7 in the MAAL
Hebrews 7 in the MBV
Hebrews 7 in the MBV2
Hebrews 7 in the MHNT
Hebrews 7 in the MKNFD
Hebrews 7 in the MNG
Hebrews 7 in the MNT
Hebrews 7 in the MNT2
Hebrews 7 in the MRS1T
Hebrews 7 in the NAA
Hebrews 7 in the NASB
Hebrews 7 in the NBLA
Hebrews 7 in the NBS
Hebrews 7 in the NBVTP
Hebrews 7 in the NET2
Hebrews 7 in the NIV11
Hebrews 7 in the NNT
Hebrews 7 in the NNT2
Hebrews 7 in the NNT3
Hebrews 7 in the PDDPT
Hebrews 7 in the PFNT
Hebrews 7 in the RMNT
Hebrews 7 in the SBIAS
Hebrews 7 in the SBIBS
Hebrews 7 in the SBIBS2
Hebrews 7 in the SBICS
Hebrews 7 in the SBIDS
Hebrews 7 in the SBIGS
Hebrews 7 in the SBIHS
Hebrews 7 in the SBIIS
Hebrews 7 in the SBIIS2
Hebrews 7 in the SBIIS3
Hebrews 7 in the SBIKS
Hebrews 7 in the SBIKS2
Hebrews 7 in the SBIMS
Hebrews 7 in the SBIOS
Hebrews 7 in the SBIPS
Hebrews 7 in the SBISS
Hebrews 7 in the SBITS
Hebrews 7 in the SBITS2
Hebrews 7 in the SBITS3
Hebrews 7 in the SBITS4
Hebrews 7 in the SBIUS
Hebrews 7 in the SBIVS
Hebrews 7 in the SBT
Hebrews 7 in the SBT1E
Hebrews 7 in the SCHL
Hebrews 7 in the SNT
Hebrews 7 in the SUSU
Hebrews 7 in the SUSU2
Hebrews 7 in the SYNO
Hebrews 7 in the TBIAOTANT
Hebrews 7 in the TBT1E
Hebrews 7 in the TBT1E2
Hebrews 7 in the TFTIP
Hebrews 7 in the TFTU
Hebrews 7 in the TGNTATF3T
Hebrews 7 in the THAI
Hebrews 7 in the TNFD
Hebrews 7 in the TNT
Hebrews 7 in the TNTIK
Hebrews 7 in the TNTIL
Hebrews 7 in the TNTIN
Hebrews 7 in the TNTIP
Hebrews 7 in the TNTIZ
Hebrews 7 in the TOMA
Hebrews 7 in the TTENT
Hebrews 7 in the UBG
Hebrews 7 in the UGV
Hebrews 7 in the UGV2
Hebrews 7 in the UGV3
Hebrews 7 in the VBL
Hebrews 7 in the VDCC
Hebrews 7 in the YALU
Hebrews 7 in the YAPE
Hebrews 7 in the YBVTP
Hebrews 7 in the ZBP