Isaiah 28 (BOYCB)

1 Ègbé ni fún adé ìgbéraga,fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu,àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójúàti sí ìlú náàìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀. 2 Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára,gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun,gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá,òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀. 3 Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu,ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. 4 Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórèbí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,òun a sì mì ín. 5 Ní ọjọ́ náà OLÚWA àwọn ọmọ-ogunyóò jẹ́ adé tí ó lógo,àti adé tí ó lẹ́wàfún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù. 6 Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodofún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́àti orísun agbárafún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè. 7 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnìwọ́n pòòrì fún ọtí líle,àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí lílewọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnìwọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle,wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá. 8 Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébìkò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin. 9 “Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún?Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn,sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú. 10 Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí,ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.” 11 Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀ 12 àwọn tí ó sọ fún wí pé,“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;àti pé, “Èyí ni ibi ìsinmi”;ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀. 13 Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ OLÚWA sí wọn yóò di pé,ṣe èyí, ṣe ìyẹn,àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn,bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn,wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú. 14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu. 15 Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,kò le kàn wá lára,nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o waàti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.” 16 Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí:“Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò,òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú;ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lékì yóò ní ìfòyà. 17 Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀nàti òdodo òjé òsùwọ̀n;yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tíẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀. 18 Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé;àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀. 19 Nígbàkígbà tí ó bá ti wá niyóò máa gbé ọ lọ,ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.” Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìíyóò máa mú ìpayà ńlá wá. 20 Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí,ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká. 21 OLÚWA yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣení òkè Perasimuyóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣení àfonífojì Gibeoni—láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀. 22 Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i; OLÚWA, àní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún minípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà. 23 Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ. 24 Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìnyóò ha máa tulẹ̀ títí bi?Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kíó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí? 25 Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹòun kò ha ń fúnrúgbìn dílìkí ó sì fúnrúgbìn kummini ká?Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ,barle tí a yàn,àti spelti ní ipò rẹ̀? 26 Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nàó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́. 27 Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili,bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini;ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde,ọ̀gọ ni a sì lu kummini. 28 A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà;bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé.Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀,àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́. 29 Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wá,oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.

In Other Versions

Isaiah 28 in the ANGEFD

Isaiah 28 in the ANTPNG2D

Isaiah 28 in the AS21

Isaiah 28 in the BAGH

Isaiah 28 in the BBPNG

Isaiah 28 in the BBT1E

Isaiah 28 in the BDS

Isaiah 28 in the BEV

Isaiah 28 in the BHAD

Isaiah 28 in the BIB

Isaiah 28 in the BLPT

Isaiah 28 in the BNT

Isaiah 28 in the BNTABOOT

Isaiah 28 in the BNTLV

Isaiah 28 in the BOATCB

Isaiah 28 in the BOATCB2

Isaiah 28 in the BOBCV

Isaiah 28 in the BOCNT

Isaiah 28 in the BOECS

Isaiah 28 in the BOGWICC

Isaiah 28 in the BOHCB

Isaiah 28 in the BOHCV

Isaiah 28 in the BOHLNT

Isaiah 28 in the BOHNTLTAL

Isaiah 28 in the BOICB

Isaiah 28 in the BOILNTAP

Isaiah 28 in the BOITCV

Isaiah 28 in the BOKCV

Isaiah 28 in the BOKCV2

Isaiah 28 in the BOKHWOG

Isaiah 28 in the BOKSSV

Isaiah 28 in the BOLCB

Isaiah 28 in the BOLCB2

Isaiah 28 in the BOMCV

Isaiah 28 in the BONAV

Isaiah 28 in the BONCB

Isaiah 28 in the BONLT

Isaiah 28 in the BONUT2

Isaiah 28 in the BOPLNT

Isaiah 28 in the BOSCB

Isaiah 28 in the BOSNC

Isaiah 28 in the BOTLNT

Isaiah 28 in the BOVCB

Isaiah 28 in the BPBB

Isaiah 28 in the BPH

Isaiah 28 in the BSB

Isaiah 28 in the CCB

Isaiah 28 in the CUV

Isaiah 28 in the CUVS

Isaiah 28 in the DBT

Isaiah 28 in the DGDNT

Isaiah 28 in the DHNT

Isaiah 28 in the DNT

Isaiah 28 in the ELBE

Isaiah 28 in the EMTV

Isaiah 28 in the ESV

Isaiah 28 in the FBV

Isaiah 28 in the FEB

Isaiah 28 in the GGMNT

Isaiah 28 in the GNT

Isaiah 28 in the HARY

Isaiah 28 in the HNT

Isaiah 28 in the IRVA

Isaiah 28 in the IRVB

Isaiah 28 in the IRVG

Isaiah 28 in the IRVH

Isaiah 28 in the IRVK

Isaiah 28 in the IRVM

Isaiah 28 in the IRVM2

Isaiah 28 in the IRVO

Isaiah 28 in the IRVP

Isaiah 28 in the IRVT

Isaiah 28 in the IRVT2

Isaiah 28 in the IRVU

Isaiah 28 in the ISVN

Isaiah 28 in the JSNT

Isaiah 28 in the KAPI

Isaiah 28 in the KBT1ETNIK

Isaiah 28 in the KBV

Isaiah 28 in the KJV

Isaiah 28 in the KNFD

Isaiah 28 in the LBA

Isaiah 28 in the LBLA

Isaiah 28 in the LNT

Isaiah 28 in the LSV

Isaiah 28 in the MAAL

Isaiah 28 in the MBV

Isaiah 28 in the MBV2

Isaiah 28 in the MHNT

Isaiah 28 in the MKNFD

Isaiah 28 in the MNG

Isaiah 28 in the MNT

Isaiah 28 in the MNT2

Isaiah 28 in the MRS1T

Isaiah 28 in the NAA

Isaiah 28 in the NASB

Isaiah 28 in the NBLA

Isaiah 28 in the NBS

Isaiah 28 in the NBVTP

Isaiah 28 in the NET2

Isaiah 28 in the NIV11

Isaiah 28 in the NNT

Isaiah 28 in the NNT2

Isaiah 28 in the NNT3

Isaiah 28 in the PDDPT

Isaiah 28 in the PFNT

Isaiah 28 in the RMNT

Isaiah 28 in the SBIAS

Isaiah 28 in the SBIBS

Isaiah 28 in the SBIBS2

Isaiah 28 in the SBICS

Isaiah 28 in the SBIDS

Isaiah 28 in the SBIGS

Isaiah 28 in the SBIHS

Isaiah 28 in the SBIIS

Isaiah 28 in the SBIIS2

Isaiah 28 in the SBIIS3

Isaiah 28 in the SBIKS

Isaiah 28 in the SBIKS2

Isaiah 28 in the SBIMS

Isaiah 28 in the SBIOS

Isaiah 28 in the SBIPS

Isaiah 28 in the SBISS

Isaiah 28 in the SBITS

Isaiah 28 in the SBITS2

Isaiah 28 in the SBITS3

Isaiah 28 in the SBITS4

Isaiah 28 in the SBIUS

Isaiah 28 in the SBIVS

Isaiah 28 in the SBT

Isaiah 28 in the SBT1E

Isaiah 28 in the SCHL

Isaiah 28 in the SNT

Isaiah 28 in the SUSU

Isaiah 28 in the SUSU2

Isaiah 28 in the SYNO

Isaiah 28 in the TBIAOTANT

Isaiah 28 in the TBT1E

Isaiah 28 in the TBT1E2

Isaiah 28 in the TFTIP

Isaiah 28 in the TFTU

Isaiah 28 in the TGNTATF3T

Isaiah 28 in the THAI

Isaiah 28 in the TNFD

Isaiah 28 in the TNT

Isaiah 28 in the TNTIK

Isaiah 28 in the TNTIL

Isaiah 28 in the TNTIN

Isaiah 28 in the TNTIP

Isaiah 28 in the TNTIZ

Isaiah 28 in the TOMA

Isaiah 28 in the TTENT

Isaiah 28 in the UBG

Isaiah 28 in the UGV

Isaiah 28 in the UGV2

Isaiah 28 in the UGV3

Isaiah 28 in the VBL

Isaiah 28 in the VDCC

Isaiah 28 in the YALU

Isaiah 28 in the YAPE

Isaiah 28 in the YBVTP

Isaiah 28 in the ZBP