Isaiah 45 (BOYCB)
1 “Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ fún ẹni òróró rẹ̀,sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì múláti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn,láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà. 2 Èmi yóò lọ síwájú rẹ,Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹÈmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹèmi ó sì gé ọ̀pá irin. 3 Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin,tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA,Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ. 4 Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ miàti Israẹli ẹni tí mo yàn,Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lóríbí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí. 5 Èmi ni OLÚWA, àti pé kò sí ẹlòmíràn;yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,Èmi yóò fún ọ ní okun,bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí, 6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùntítí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.Èmi ni OLÚWA, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́. 7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn,Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù;Èmi OLÚWA ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí. 8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;Èmi OLÚWA ni ó ti dá a. 9 “Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,‘Òun kò ní ọwọ́?’ 10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,‘Kí ni o bí?’tàbí sí ìyá rẹ̀,‘Kí ni ìwọ ti bí?’ 11 “Ohun tí OLÚWA wí nìyìí,Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.Nípa ohun tí ó ń bọ̀,ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí? 12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayétí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run;mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta. 13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi.Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.Òun yóò tún ìlú mi kọ́yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.” 14 Ohun tí OLÚWA wí nìyìí:“Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi,àti àwọn Sabeani—wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹwọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn;kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ” 15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli, 16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tìwọn yóò sì kan àbùkù;gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀. 17 Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ OLÚWApẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín,títí ayé àìnípẹ̀kun. 18 Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA wí,ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run,Òun ni Ọlọ́run;ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé,Òun ló ṣe é;Òun kò dá a láti wà lófo,ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀,Òun wí pé:“Èmi ni OLÚWA,kò sì ṣí ẹlòmíràn. 19 Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin,láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn,Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé,‘Ẹ wá mi lórí asán.’Èmi OLÚWA sọ òtítọ́,Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà. 20 “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá;ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá.Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri,tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni. 21 Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá,jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?Kì í ha á ṣe Èmi, OLÚWA?Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;kò sí ẹlòmíràn àfi èmi. 22 “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé;nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn. 23 Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra,ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi,ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́.Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra. 24 Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú OLÚWA nìkan niòdodo àti agbára wà.’ ”Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn. 25 Ṣùgbọ́n nínú OLÚWA gbogbo àwọn ìran Israẹlini a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.