Isaiah 58 (BOYCB)
1 “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn.Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè.Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn,àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 2 Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nàtí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkanwọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. 3 Wọ́n wí pé, ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,tí ìwọ kò sì tí ì rí?Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’ “Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yínẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú. 4 Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu.Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìíkí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga. 5 Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí,ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bíàti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí,ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLÚWA? 6 “Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodoàti láti tú gbogbo okùn àjàgà,láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀àti láti fọ́ gbogbo àjàgà? 7 Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń paàti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri.Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó,àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn? 8 Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ,ògo OLÚWA yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ. 9 Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí OLÚWA yóò sì dáhùn;ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára,nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ, 10 àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń patí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan. 11 OLÚWA yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo;òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀yóò sì fún egungun rẹ lókun.Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára,àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ. 12 Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ róa ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wóàti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀. 13 “Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi,bí ìwọ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ohun dídùnàti ọjọ́ mímọ́ OLÚWA ní ohun ọ̀wọ̀àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọàti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbíkí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí, 14 nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú OLÚWA rẹ,èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé,àti láti máa jàdídùn ìní tiJakọbu baba rẹ.”Ẹnu OLÚWA ni ó ti sọ̀rọ̀.
In Other Versions
Isaiah 58 in the ANGEFD
Isaiah 58 in the ANTPNG2D
Isaiah 58 in the AS21
Isaiah 58 in the BAGH
Isaiah 58 in the BBPNG
Isaiah 58 in the BBT1E
Isaiah 58 in the BDS
Isaiah 58 in the BEV
Isaiah 58 in the BHAD
Isaiah 58 in the BIB
Isaiah 58 in the BLPT
Isaiah 58 in the BNT
Isaiah 58 in the BNTABOOT
Isaiah 58 in the BNTLV
Isaiah 58 in the BOATCB
Isaiah 58 in the BOATCB2
Isaiah 58 in the BOBCV
Isaiah 58 in the BOCNT
Isaiah 58 in the BOECS
Isaiah 58 in the BOGWICC
Isaiah 58 in the BOHCB
Isaiah 58 in the BOHCV
Isaiah 58 in the BOHLNT
Isaiah 58 in the BOHNTLTAL
Isaiah 58 in the BOICB
Isaiah 58 in the BOILNTAP
Isaiah 58 in the BOITCV
Isaiah 58 in the BOKCV
Isaiah 58 in the BOKCV2
Isaiah 58 in the BOKHWOG
Isaiah 58 in the BOKSSV
Isaiah 58 in the BOLCB
Isaiah 58 in the BOLCB2
Isaiah 58 in the BOMCV
Isaiah 58 in the BONAV
Isaiah 58 in the BONCB
Isaiah 58 in the BONLT
Isaiah 58 in the BONUT2
Isaiah 58 in the BOPLNT
Isaiah 58 in the BOSCB
Isaiah 58 in the BOSNC
Isaiah 58 in the BOTLNT
Isaiah 58 in the BOVCB
Isaiah 58 in the BPBB
Isaiah 58 in the BPH
Isaiah 58 in the BSB
Isaiah 58 in the CCB
Isaiah 58 in the CUV
Isaiah 58 in the CUVS
Isaiah 58 in the DBT
Isaiah 58 in the DGDNT
Isaiah 58 in the DHNT
Isaiah 58 in the DNT
Isaiah 58 in the ELBE
Isaiah 58 in the EMTV
Isaiah 58 in the ESV
Isaiah 58 in the FBV
Isaiah 58 in the FEB
Isaiah 58 in the GGMNT
Isaiah 58 in the GNT
Isaiah 58 in the HARY
Isaiah 58 in the HNT
Isaiah 58 in the IRVA
Isaiah 58 in the IRVB
Isaiah 58 in the IRVG
Isaiah 58 in the IRVH
Isaiah 58 in the IRVK
Isaiah 58 in the IRVM
Isaiah 58 in the IRVM2
Isaiah 58 in the IRVO
Isaiah 58 in the IRVP
Isaiah 58 in the IRVT
Isaiah 58 in the IRVT2
Isaiah 58 in the IRVU
Isaiah 58 in the ISVN
Isaiah 58 in the JSNT
Isaiah 58 in the KAPI
Isaiah 58 in the KBT1ETNIK
Isaiah 58 in the KBV
Isaiah 58 in the KJV
Isaiah 58 in the KNFD
Isaiah 58 in the LBA
Isaiah 58 in the LBLA
Isaiah 58 in the LNT
Isaiah 58 in the LSV
Isaiah 58 in the MAAL
Isaiah 58 in the MBV
Isaiah 58 in the MBV2
Isaiah 58 in the MHNT
Isaiah 58 in the MKNFD
Isaiah 58 in the MNG
Isaiah 58 in the MNT
Isaiah 58 in the MNT2
Isaiah 58 in the MRS1T
Isaiah 58 in the NAA
Isaiah 58 in the NASB
Isaiah 58 in the NBLA
Isaiah 58 in the NBS
Isaiah 58 in the NBVTP
Isaiah 58 in the NET2
Isaiah 58 in the NIV11
Isaiah 58 in the NNT
Isaiah 58 in the NNT2
Isaiah 58 in the NNT3
Isaiah 58 in the PDDPT
Isaiah 58 in the PFNT
Isaiah 58 in the RMNT
Isaiah 58 in the SBIAS
Isaiah 58 in the SBIBS
Isaiah 58 in the SBIBS2
Isaiah 58 in the SBICS
Isaiah 58 in the SBIDS
Isaiah 58 in the SBIGS
Isaiah 58 in the SBIHS
Isaiah 58 in the SBIIS
Isaiah 58 in the SBIIS2
Isaiah 58 in the SBIIS3
Isaiah 58 in the SBIKS
Isaiah 58 in the SBIKS2
Isaiah 58 in the SBIMS
Isaiah 58 in the SBIOS
Isaiah 58 in the SBIPS
Isaiah 58 in the SBISS
Isaiah 58 in the SBITS
Isaiah 58 in the SBITS2
Isaiah 58 in the SBITS3
Isaiah 58 in the SBITS4
Isaiah 58 in the SBIUS
Isaiah 58 in the SBIVS
Isaiah 58 in the SBT
Isaiah 58 in the SBT1E
Isaiah 58 in the SCHL
Isaiah 58 in the SNT
Isaiah 58 in the SUSU
Isaiah 58 in the SUSU2
Isaiah 58 in the SYNO
Isaiah 58 in the TBIAOTANT
Isaiah 58 in the TBT1E
Isaiah 58 in the TBT1E2
Isaiah 58 in the TFTIP
Isaiah 58 in the TFTU
Isaiah 58 in the TGNTATF3T
Isaiah 58 in the THAI
Isaiah 58 in the TNFD
Isaiah 58 in the TNT
Isaiah 58 in the TNTIK
Isaiah 58 in the TNTIL
Isaiah 58 in the TNTIN
Isaiah 58 in the TNTIP
Isaiah 58 in the TNTIZ
Isaiah 58 in the TOMA
Isaiah 58 in the TTENT
Isaiah 58 in the UBG
Isaiah 58 in the UGV
Isaiah 58 in the UGV2
Isaiah 58 in the UGV3
Isaiah 58 in the VBL
Isaiah 58 in the VDCC
Isaiah 58 in the YALU
Isaiah 58 in the YAPE
Isaiah 58 in the YBVTP
Isaiah 58 in the ZBP