Jeremiah 13 (BOYCB)
1 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí fún mi: “Lọ kí o sì ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀, kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án.” 2 Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi. 3 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá nígbà kejì, 4 “Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fiwé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Perati, kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta.” 5 Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Perati gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti wí fún mi. 6 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, OLÚWA sọ fún mi, “Lọ sí Perati kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀.” 7 Nígbà náà ni mo lọ sí Perati mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́. 8 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá pé: 9 “Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Juda àti ìgbéraga ńlá ti Jerusalẹmu. 10 Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun. 11 Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Israẹli àti gbogbo ilé Juda mọ́ mi,’ ni OLÚWA wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’ 12 “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’ 13 Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu. 14 Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni OLÚWA wí. Èmi kì yóò dáríjì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti máa pa wọ́n run.’ ” 15 Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀,ẹ má ṣe gbéraga,nítorí OLÚWA ti sọ̀rọ̀. 16 Ẹ fi ògo fún OLÚWA Ọlọ́run yín,kí ó tó mú òkùnkùn wá,àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsélórí òkè tí ó ṣókùnkùn.Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀,òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò sì ṣe bi òkùnkùn biribiri. 17 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀nítorí ìgbéraga yín.Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde,nítorí a kó agbo OLÚWA lọ ìgbèkùn. 18 Sọ fún ọba àti ayaba pé,“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.” 19 Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa,kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn.Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá. 20 Gbé ojú rẹ sókè,kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá.Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà;àgùntàn tí ò ń mú yangàn. 21 Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí OLÚWA bá dúró lórí rẹàwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọbí aboyún tó ń rọbí? 22 Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè,“Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?”Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀ni aṣọ rẹ fi fàyatí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe. 23 Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà?Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà?Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere. 24 “N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbòtí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́. 25 Èyí ni ìpín tìrẹ;tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ,”ni OLÚWA wí,“Nítorí ìwọ ti gbàgbé mio sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì. 26 N ó sí aṣọ lójú rẹ,kí ẹ̀sín rẹ le hàn síta— 27 ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,àìlójútì panṣágà rẹ!Mo ti rí ìwà ìríra rẹ,lórí òkè àti ní pápá.Ègbé ni fún ọ ìwọ Jerusalẹmu!Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”
In Other Versions
Jeremiah 13 in the ANGEFD
Jeremiah 13 in the ANTPNG2D
Jeremiah 13 in the AS21
Jeremiah 13 in the BAGH
Jeremiah 13 in the BBPNG
Jeremiah 13 in the BBT1E
Jeremiah 13 in the BDS
Jeremiah 13 in the BEV
Jeremiah 13 in the BHAD
Jeremiah 13 in the BIB
Jeremiah 13 in the BLPT
Jeremiah 13 in the BNT
Jeremiah 13 in the BNTABOOT
Jeremiah 13 in the BNTLV
Jeremiah 13 in the BOATCB
Jeremiah 13 in the BOATCB2
Jeremiah 13 in the BOBCV
Jeremiah 13 in the BOCNT
Jeremiah 13 in the BOECS
Jeremiah 13 in the BOGWICC
Jeremiah 13 in the BOHCB
Jeremiah 13 in the BOHCV
Jeremiah 13 in the BOHLNT
Jeremiah 13 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 13 in the BOICB
Jeremiah 13 in the BOILNTAP
Jeremiah 13 in the BOITCV
Jeremiah 13 in the BOKCV
Jeremiah 13 in the BOKCV2
Jeremiah 13 in the BOKHWOG
Jeremiah 13 in the BOKSSV
Jeremiah 13 in the BOLCB
Jeremiah 13 in the BOLCB2
Jeremiah 13 in the BOMCV
Jeremiah 13 in the BONAV
Jeremiah 13 in the BONCB
Jeremiah 13 in the BONLT
Jeremiah 13 in the BONUT2
Jeremiah 13 in the BOPLNT
Jeremiah 13 in the BOSCB
Jeremiah 13 in the BOSNC
Jeremiah 13 in the BOTLNT
Jeremiah 13 in the BOVCB
Jeremiah 13 in the BPBB
Jeremiah 13 in the BPH
Jeremiah 13 in the BSB
Jeremiah 13 in the CCB
Jeremiah 13 in the CUV
Jeremiah 13 in the CUVS
Jeremiah 13 in the DBT
Jeremiah 13 in the DGDNT
Jeremiah 13 in the DHNT
Jeremiah 13 in the DNT
Jeremiah 13 in the ELBE
Jeremiah 13 in the EMTV
Jeremiah 13 in the ESV
Jeremiah 13 in the FBV
Jeremiah 13 in the FEB
Jeremiah 13 in the GGMNT
Jeremiah 13 in the GNT
Jeremiah 13 in the HARY
Jeremiah 13 in the HNT
Jeremiah 13 in the IRVA
Jeremiah 13 in the IRVB
Jeremiah 13 in the IRVG
Jeremiah 13 in the IRVH
Jeremiah 13 in the IRVK
Jeremiah 13 in the IRVM
Jeremiah 13 in the IRVM2
Jeremiah 13 in the IRVO
Jeremiah 13 in the IRVP
Jeremiah 13 in the IRVT
Jeremiah 13 in the IRVT2
Jeremiah 13 in the IRVU
Jeremiah 13 in the ISVN
Jeremiah 13 in the JSNT
Jeremiah 13 in the KAPI
Jeremiah 13 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 13 in the KBV
Jeremiah 13 in the KJV
Jeremiah 13 in the KNFD
Jeremiah 13 in the LBA
Jeremiah 13 in the LBLA
Jeremiah 13 in the LNT
Jeremiah 13 in the LSV
Jeremiah 13 in the MAAL
Jeremiah 13 in the MBV
Jeremiah 13 in the MBV2
Jeremiah 13 in the MHNT
Jeremiah 13 in the MKNFD
Jeremiah 13 in the MNG
Jeremiah 13 in the MNT
Jeremiah 13 in the MNT2
Jeremiah 13 in the MRS1T
Jeremiah 13 in the NAA
Jeremiah 13 in the NASB
Jeremiah 13 in the NBLA
Jeremiah 13 in the NBS
Jeremiah 13 in the NBVTP
Jeremiah 13 in the NET2
Jeremiah 13 in the NIV11
Jeremiah 13 in the NNT
Jeremiah 13 in the NNT2
Jeremiah 13 in the NNT3
Jeremiah 13 in the PDDPT
Jeremiah 13 in the PFNT
Jeremiah 13 in the RMNT
Jeremiah 13 in the SBIAS
Jeremiah 13 in the SBIBS
Jeremiah 13 in the SBIBS2
Jeremiah 13 in the SBICS
Jeremiah 13 in the SBIDS
Jeremiah 13 in the SBIGS
Jeremiah 13 in the SBIHS
Jeremiah 13 in the SBIIS
Jeremiah 13 in the SBIIS2
Jeremiah 13 in the SBIIS3
Jeremiah 13 in the SBIKS
Jeremiah 13 in the SBIKS2
Jeremiah 13 in the SBIMS
Jeremiah 13 in the SBIOS
Jeremiah 13 in the SBIPS
Jeremiah 13 in the SBISS
Jeremiah 13 in the SBITS
Jeremiah 13 in the SBITS2
Jeremiah 13 in the SBITS3
Jeremiah 13 in the SBITS4
Jeremiah 13 in the SBIUS
Jeremiah 13 in the SBIVS
Jeremiah 13 in the SBT
Jeremiah 13 in the SBT1E
Jeremiah 13 in the SCHL
Jeremiah 13 in the SNT
Jeremiah 13 in the SUSU
Jeremiah 13 in the SUSU2
Jeremiah 13 in the SYNO
Jeremiah 13 in the TBIAOTANT
Jeremiah 13 in the TBT1E
Jeremiah 13 in the TBT1E2
Jeremiah 13 in the TFTIP
Jeremiah 13 in the TFTU
Jeremiah 13 in the TGNTATF3T
Jeremiah 13 in the THAI
Jeremiah 13 in the TNFD
Jeremiah 13 in the TNT
Jeremiah 13 in the TNTIK
Jeremiah 13 in the TNTIL
Jeremiah 13 in the TNTIN
Jeremiah 13 in the TNTIP
Jeremiah 13 in the TNTIZ
Jeremiah 13 in the TOMA
Jeremiah 13 in the TTENT
Jeremiah 13 in the UBG
Jeremiah 13 in the UGV
Jeremiah 13 in the UGV2
Jeremiah 13 in the UGV3
Jeremiah 13 in the VBL
Jeremiah 13 in the VDCC
Jeremiah 13 in the YALU
Jeremiah 13 in the YAPE
Jeremiah 13 in the YBVTP
Jeremiah 13 in the ZBP