Jeremiah 17 (BOYCB)
1 “Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,sórí wàláà oókan àyà wọn,àti sórí ìwo pẹpẹ yín. 2 Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹàti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹàti àwọn òkè gíga. 3 Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹpẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ópọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín. 4 Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yinyóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrúní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀,nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi,èyí tí yóò sì wà títí ayé.” 5 Báyìí ni OLÚWA wí:“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ OLÚWA. 6 Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé. 7 “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrinnáà tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, tí ó sì fi OLÚWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. 8 Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadòtí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odòkò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutùkò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dábẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.” 9 Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,ó kọjá ohun tí a lè wòsàn.Ta ni èyí lè yé? 10 “Èmi OLÚWA ń wo ọkànàti èrò inú ọmọ ènìyàn,láti san èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” 11 Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yéni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo.Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀,àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè. 12 Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ní ibi ilé mímọ́ wa. 13 OLÚWA ìwọ ni ìrètí Israẹli;gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,nítorí wọ́n ti kọ OLÚWA,orísun omi ìyè sílẹ̀. 14 Wò mí sàn OLÚWA, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,nítorí ìwọ ni ìyìn mi. 15 Wọ́n sọ fún mi wí pé:“Níbo ni ọ̀rọ̀ OLÚWA wà?Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”Ni OLÚWA wí. 16 Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ. 17 Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú. 18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run. 19 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20 Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí. 21 Báyìí ni OLÚWA wí, “Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu. 22 Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.” 23 Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí. 24 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní OLÚWA wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà. 25 Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé. 26 Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé OLÚWA. 27 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”
In Other Versions
Jeremiah 17 in the ANGEFD
Jeremiah 17 in the ANTPNG2D
Jeremiah 17 in the AS21
Jeremiah 17 in the BAGH
Jeremiah 17 in the BBPNG
Jeremiah 17 in the BBT1E
Jeremiah 17 in the BDS
Jeremiah 17 in the BEV
Jeremiah 17 in the BHAD
Jeremiah 17 in the BIB
Jeremiah 17 in the BLPT
Jeremiah 17 in the BNT
Jeremiah 17 in the BNTABOOT
Jeremiah 17 in the BNTLV
Jeremiah 17 in the BOATCB
Jeremiah 17 in the BOATCB2
Jeremiah 17 in the BOBCV
Jeremiah 17 in the BOCNT
Jeremiah 17 in the BOECS
Jeremiah 17 in the BOGWICC
Jeremiah 17 in the BOHCB
Jeremiah 17 in the BOHCV
Jeremiah 17 in the BOHLNT
Jeremiah 17 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 17 in the BOICB
Jeremiah 17 in the BOILNTAP
Jeremiah 17 in the BOITCV
Jeremiah 17 in the BOKCV
Jeremiah 17 in the BOKCV2
Jeremiah 17 in the BOKHWOG
Jeremiah 17 in the BOKSSV
Jeremiah 17 in the BOLCB
Jeremiah 17 in the BOLCB2
Jeremiah 17 in the BOMCV
Jeremiah 17 in the BONAV
Jeremiah 17 in the BONCB
Jeremiah 17 in the BONLT
Jeremiah 17 in the BONUT2
Jeremiah 17 in the BOPLNT
Jeremiah 17 in the BOSCB
Jeremiah 17 in the BOSNC
Jeremiah 17 in the BOTLNT
Jeremiah 17 in the BOVCB
Jeremiah 17 in the BPBB
Jeremiah 17 in the BPH
Jeremiah 17 in the BSB
Jeremiah 17 in the CCB
Jeremiah 17 in the CUV
Jeremiah 17 in the CUVS
Jeremiah 17 in the DBT
Jeremiah 17 in the DGDNT
Jeremiah 17 in the DHNT
Jeremiah 17 in the DNT
Jeremiah 17 in the ELBE
Jeremiah 17 in the EMTV
Jeremiah 17 in the ESV
Jeremiah 17 in the FBV
Jeremiah 17 in the FEB
Jeremiah 17 in the GGMNT
Jeremiah 17 in the GNT
Jeremiah 17 in the HARY
Jeremiah 17 in the HNT
Jeremiah 17 in the IRVA
Jeremiah 17 in the IRVB
Jeremiah 17 in the IRVG
Jeremiah 17 in the IRVH
Jeremiah 17 in the IRVK
Jeremiah 17 in the IRVM
Jeremiah 17 in the IRVM2
Jeremiah 17 in the IRVO
Jeremiah 17 in the IRVP
Jeremiah 17 in the IRVT
Jeremiah 17 in the IRVT2
Jeremiah 17 in the IRVU
Jeremiah 17 in the ISVN
Jeremiah 17 in the JSNT
Jeremiah 17 in the KAPI
Jeremiah 17 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 17 in the KBV
Jeremiah 17 in the KJV
Jeremiah 17 in the KNFD
Jeremiah 17 in the LBA
Jeremiah 17 in the LBLA
Jeremiah 17 in the LNT
Jeremiah 17 in the LSV
Jeremiah 17 in the MAAL
Jeremiah 17 in the MBV
Jeremiah 17 in the MBV2
Jeremiah 17 in the MHNT
Jeremiah 17 in the MKNFD
Jeremiah 17 in the MNG
Jeremiah 17 in the MNT
Jeremiah 17 in the MNT2
Jeremiah 17 in the MRS1T
Jeremiah 17 in the NAA
Jeremiah 17 in the NASB
Jeremiah 17 in the NBLA
Jeremiah 17 in the NBS
Jeremiah 17 in the NBVTP
Jeremiah 17 in the NET2
Jeremiah 17 in the NIV11
Jeremiah 17 in the NNT
Jeremiah 17 in the NNT2
Jeremiah 17 in the NNT3
Jeremiah 17 in the PDDPT
Jeremiah 17 in the PFNT
Jeremiah 17 in the RMNT
Jeremiah 17 in the SBIAS
Jeremiah 17 in the SBIBS
Jeremiah 17 in the SBIBS2
Jeremiah 17 in the SBICS
Jeremiah 17 in the SBIDS
Jeremiah 17 in the SBIGS
Jeremiah 17 in the SBIHS
Jeremiah 17 in the SBIIS
Jeremiah 17 in the SBIIS2
Jeremiah 17 in the SBIIS3
Jeremiah 17 in the SBIKS
Jeremiah 17 in the SBIKS2
Jeremiah 17 in the SBIMS
Jeremiah 17 in the SBIOS
Jeremiah 17 in the SBIPS
Jeremiah 17 in the SBISS
Jeremiah 17 in the SBITS
Jeremiah 17 in the SBITS2
Jeremiah 17 in the SBITS3
Jeremiah 17 in the SBITS4
Jeremiah 17 in the SBIUS
Jeremiah 17 in the SBIVS
Jeremiah 17 in the SBT
Jeremiah 17 in the SBT1E
Jeremiah 17 in the SCHL
Jeremiah 17 in the SNT
Jeremiah 17 in the SUSU
Jeremiah 17 in the SUSU2
Jeremiah 17 in the SYNO
Jeremiah 17 in the TBIAOTANT
Jeremiah 17 in the TBT1E
Jeremiah 17 in the TBT1E2
Jeremiah 17 in the TFTIP
Jeremiah 17 in the TFTU
Jeremiah 17 in the TGNTATF3T
Jeremiah 17 in the THAI
Jeremiah 17 in the TNFD
Jeremiah 17 in the TNT
Jeremiah 17 in the TNTIK
Jeremiah 17 in the TNTIL
Jeremiah 17 in the TNTIN
Jeremiah 17 in the TNTIP
Jeremiah 17 in the TNTIZ
Jeremiah 17 in the TOMA
Jeremiah 17 in the TTENT
Jeremiah 17 in the UBG
Jeremiah 17 in the UGV
Jeremiah 17 in the UGV2
Jeremiah 17 in the UGV3
Jeremiah 17 in the VBL
Jeremiah 17 in the VDCC
Jeremiah 17 in the YALU
Jeremiah 17 in the YAPE
Jeremiah 17 in the YBVTP
Jeremiah 17 in the ZBP