John 16 (BOYCB)

1 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má ba à mú yín yapa kúrò. 2 Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sinagọgu: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run. 3 Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí. 4 Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín. Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín. 5 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’ 6 Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín. 7 Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ, nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín. 8 Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́, 9 ní ti ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́; 10 ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí. 11 Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ ọmọ-aládé ayé yìí. 12 “Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsin yìí. 13 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo, nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ, yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín. 14 Òun ó máa yìn mí lógo, nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín. 15 Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni, nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín. 16 “Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi, àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.” 17 Nítorí náà díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bá ara wọn sọ pé, “Kín ni èyí tí o wí fún wa yìí, ‘Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin ó sì rí mi, àti nígbà díẹ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin kì yóò rí mi, àti, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba’?” 18 Nítorí náà wọ́n wí pé, kín ni, nígbà díẹ̀? Àwa kò mọ̀ ohun tí ó wí. 19 Jesu sá à ti mọ̀ pé, wọ́n ń fẹ́ láti bi òun léèrè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè ní ti èyí tí mo wí pé, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi, àti nígbà díẹ̀ si, ẹ̀yin ó sì rí mi? 20 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ẹ̀yin yóò máa sọkún ẹ ó sì máa pohùnréré ẹkún, ṣùgbọ́n àwọn aráyé yóò máa yọ̀: ṣùgbọ́n, ìbànújẹ́ yín yóò di ayọ̀. 21 Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti bí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé. 22 Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsin yìí, ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín. 23 Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín. 24 Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún. 25 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba. 26 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi, èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín. 27 Nítorí tí Baba tìkára rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá. 28 Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé, àti nísinsin yìí mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.” 29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Wò ó, nígbà yìí ni ìwọ ń sọ̀rọ̀ gbangba, ìwọ kò sì sọ ohunkóhun ní òwe. 30 Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé, ìwọ mọ̀ ohun gbogbo, ìwọ kò ní kí a bi ọ́ léèrè: nípa èyí ni àwa gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ ti jáde wá.” 31 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ wàyí? 32 Kíyèsi i, wákàtí ń bọ̀, àní ó dé tan nísinsin yìí, tí a ó fọ́n yín ká kiri, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀; ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò sì ṣe èmi nìkan, nítorí tí Baba ń bẹ pẹ̀lú mi. 33 “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”

In Other Versions

John 16 in the ANGEFD

John 16 in the ANTPNG2D

John 16 in the AS21

John 16 in the BAGH

John 16 in the BBPNG

John 16 in the BBT1E

John 16 in the BDS

John 16 in the BEV

John 16 in the BHAD

John 16 in the BIB

John 16 in the BLPT

John 16 in the BNT

John 16 in the BNTABOOT

John 16 in the BNTLV

John 16 in the BOATCB

John 16 in the BOATCB2

John 16 in the BOBCV

John 16 in the BOCNT

John 16 in the BOECS

John 16 in the BOGWICC

John 16 in the BOHCB

John 16 in the BOHCV

John 16 in the BOHLNT

John 16 in the BOHNTLTAL

John 16 in the BOICB

John 16 in the BOILNTAP

John 16 in the BOITCV

John 16 in the BOKCV

John 16 in the BOKCV2

John 16 in the BOKHWOG

John 16 in the BOKSSV

John 16 in the BOLCB

John 16 in the BOLCB2

John 16 in the BOMCV

John 16 in the BONAV

John 16 in the BONCB

John 16 in the BONLT

John 16 in the BONUT2

John 16 in the BOPLNT

John 16 in the BOSCB

John 16 in the BOSNC

John 16 in the BOTLNT

John 16 in the BOVCB

John 16 in the BPBB

John 16 in the BPH

John 16 in the BSB

John 16 in the CCB

John 16 in the CUV

John 16 in the CUVS

John 16 in the DBT

John 16 in the DGDNT

John 16 in the DHNT

John 16 in the DNT

John 16 in the ELBE

John 16 in the EMTV

John 16 in the ESV

John 16 in the FBV

John 16 in the FEB

John 16 in the GGMNT

John 16 in the GNT

John 16 in the HARY

John 16 in the HNT

John 16 in the IRVA

John 16 in the IRVB

John 16 in the IRVG

John 16 in the IRVH

John 16 in the IRVK

John 16 in the IRVM

John 16 in the IRVM2

John 16 in the IRVO

John 16 in the IRVP

John 16 in the IRVT

John 16 in the IRVT2

John 16 in the IRVU

John 16 in the ISVN

John 16 in the JSNT

John 16 in the KAPI

John 16 in the KBT1ETNIK

John 16 in the KBV

John 16 in the KJV

John 16 in the KNFD

John 16 in the LBA

John 16 in the LBLA

John 16 in the LNT

John 16 in the LSV

John 16 in the MAAL

John 16 in the MBV

John 16 in the MBV2

John 16 in the MHNT

John 16 in the MKNFD

John 16 in the MNG

John 16 in the MNT

John 16 in the MNT2

John 16 in the MRS1T

John 16 in the NAA

John 16 in the NASB

John 16 in the NBLA

John 16 in the NBS

John 16 in the NBVTP

John 16 in the NET2

John 16 in the NIV11

John 16 in the NNT

John 16 in the NNT2

John 16 in the NNT3

John 16 in the PDDPT

John 16 in the PFNT

John 16 in the RMNT

John 16 in the SBIAS

John 16 in the SBIBS

John 16 in the SBIBS2

John 16 in the SBICS

John 16 in the SBIDS

John 16 in the SBIGS

John 16 in the SBIHS

John 16 in the SBIIS

John 16 in the SBIIS2

John 16 in the SBIIS3

John 16 in the SBIKS

John 16 in the SBIKS2

John 16 in the SBIMS

John 16 in the SBIOS

John 16 in the SBIPS

John 16 in the SBISS

John 16 in the SBITS

John 16 in the SBITS2

John 16 in the SBITS3

John 16 in the SBITS4

John 16 in the SBIUS

John 16 in the SBIVS

John 16 in the SBT

John 16 in the SBT1E

John 16 in the SCHL

John 16 in the SNT

John 16 in the SUSU

John 16 in the SUSU2

John 16 in the SYNO

John 16 in the TBIAOTANT

John 16 in the TBT1E

John 16 in the TBT1E2

John 16 in the TFTIP

John 16 in the TFTU

John 16 in the TGNTATF3T

John 16 in the THAI

John 16 in the TNFD

John 16 in the TNT

John 16 in the TNTIK

John 16 in the TNTIL

John 16 in the TNTIN

John 16 in the TNTIP

John 16 in the TNTIZ

John 16 in the TOMA

John 16 in the TTENT

John 16 in the UBG

John 16 in the UGV

John 16 in the UGV2

John 16 in the UGV3

John 16 in the VBL

John 16 in the VDCC

John 16 in the YALU

John 16 in the YAPE

John 16 in the YBVTP

John 16 in the ZBP