Job 39 (BOYCB)

1 “Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ? 2 Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé,ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ. 3 Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ,wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde. 4 Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn;wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn. 5 “Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́?Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó, 6 èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún,àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀. 7 Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú,bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran. 8 Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀,òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí. 9 “Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí?Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru? 10 Ìwọ le fi òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo?Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn? 11 Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀?Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́? 12 Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé,àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ? 13 “Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí,tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò? 14 Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀,a sì mú wọn gbóná nínú ekuru; 15 tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́,tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́. 16 Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀;asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù; 17 nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n,bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un. 18 Nígbà tí ó gbé ara sókè,ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin. 19 “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí,tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ? 20 Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà?Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá. 21 Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀;ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun. 22 Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó;bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà. 23 Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ,àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta. 24 Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi,bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni. 25 Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré,igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn. 26 “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè,tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù? 27 Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè,kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga? 28 Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta,lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè. 29 Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri,ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré. 30 Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀,níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”

In Other Versions

Job 39 in the ANGEFD

Job 39 in the ANTPNG2D

Job 39 in the AS21

Job 39 in the BAGH

Job 39 in the BBPNG

Job 39 in the BBT1E

Job 39 in the BDS

Job 39 in the BEV

Job 39 in the BHAD

Job 39 in the BIB

Job 39 in the BLPT

Job 39 in the BNT

Job 39 in the BNTABOOT

Job 39 in the BNTLV

Job 39 in the BOATCB

Job 39 in the BOATCB2

Job 39 in the BOBCV

Job 39 in the BOCNT

Job 39 in the BOECS

Job 39 in the BOGWICC

Job 39 in the BOHCB

Job 39 in the BOHCV

Job 39 in the BOHLNT

Job 39 in the BOHNTLTAL

Job 39 in the BOICB

Job 39 in the BOILNTAP

Job 39 in the BOITCV

Job 39 in the BOKCV

Job 39 in the BOKCV2

Job 39 in the BOKHWOG

Job 39 in the BOKSSV

Job 39 in the BOLCB

Job 39 in the BOLCB2

Job 39 in the BOMCV

Job 39 in the BONAV

Job 39 in the BONCB

Job 39 in the BONLT

Job 39 in the BONUT2

Job 39 in the BOPLNT

Job 39 in the BOSCB

Job 39 in the BOSNC

Job 39 in the BOTLNT

Job 39 in the BOVCB

Job 39 in the BPBB

Job 39 in the BPH

Job 39 in the BSB

Job 39 in the CCB

Job 39 in the CUV

Job 39 in the CUVS

Job 39 in the DBT

Job 39 in the DGDNT

Job 39 in the DHNT

Job 39 in the DNT

Job 39 in the ELBE

Job 39 in the EMTV

Job 39 in the ESV

Job 39 in the FBV

Job 39 in the FEB

Job 39 in the GGMNT

Job 39 in the GNT

Job 39 in the HARY

Job 39 in the HNT

Job 39 in the IRVA

Job 39 in the IRVB

Job 39 in the IRVG

Job 39 in the IRVH

Job 39 in the IRVK

Job 39 in the IRVM

Job 39 in the IRVM2

Job 39 in the IRVO

Job 39 in the IRVP

Job 39 in the IRVT

Job 39 in the IRVT2

Job 39 in the IRVU

Job 39 in the ISVN

Job 39 in the JSNT

Job 39 in the KAPI

Job 39 in the KBT1ETNIK

Job 39 in the KBV

Job 39 in the KJV

Job 39 in the KNFD

Job 39 in the LBA

Job 39 in the LBLA

Job 39 in the LNT

Job 39 in the LSV

Job 39 in the MAAL

Job 39 in the MBV

Job 39 in the MBV2

Job 39 in the MHNT

Job 39 in the MKNFD

Job 39 in the MNG

Job 39 in the MNT

Job 39 in the MNT2

Job 39 in the MRS1T

Job 39 in the NAA

Job 39 in the NASB

Job 39 in the NBLA

Job 39 in the NBS

Job 39 in the NBVTP

Job 39 in the NET2

Job 39 in the NIV11

Job 39 in the NNT

Job 39 in the NNT2

Job 39 in the NNT3

Job 39 in the PDDPT

Job 39 in the PFNT

Job 39 in the RMNT

Job 39 in the SBIAS

Job 39 in the SBIBS

Job 39 in the SBIBS2

Job 39 in the SBICS

Job 39 in the SBIDS

Job 39 in the SBIGS

Job 39 in the SBIHS

Job 39 in the SBIIS

Job 39 in the SBIIS2

Job 39 in the SBIIS3

Job 39 in the SBIKS

Job 39 in the SBIKS2

Job 39 in the SBIMS

Job 39 in the SBIOS

Job 39 in the SBIPS

Job 39 in the SBISS

Job 39 in the SBITS

Job 39 in the SBITS2

Job 39 in the SBITS3

Job 39 in the SBITS4

Job 39 in the SBIUS

Job 39 in the SBIVS

Job 39 in the SBT

Job 39 in the SBT1E

Job 39 in the SCHL

Job 39 in the SNT

Job 39 in the SUSU

Job 39 in the SUSU2

Job 39 in the SYNO

Job 39 in the TBIAOTANT

Job 39 in the TBT1E

Job 39 in the TBT1E2

Job 39 in the TFTIP

Job 39 in the TFTU

Job 39 in the TGNTATF3T

Job 39 in the THAI

Job 39 in the TNFD

Job 39 in the TNT

Job 39 in the TNTIK

Job 39 in the TNTIL

Job 39 in the TNTIN

Job 39 in the TNTIP

Job 39 in the TNTIZ

Job 39 in the TOMA

Job 39 in the TTENT

Job 39 in the UBG

Job 39 in the UGV

Job 39 in the UGV2

Job 39 in the UGV3

Job 39 in the VBL

Job 39 in the VDCC

Job 39 in the YALU

Job 39 in the YAPE

Job 39 in the YBVTP

Job 39 in the ZBP