Proverbs 1 (BOYCB)
1 Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. 2 Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́,láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀. 3 Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo,àti ìdájọ́, àti àìṣègbè; 4 láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀,ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe. 5 Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀,sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà. 6 Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe,àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n. 7 Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́. 8 Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ,má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀. 9 Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹàti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká. 10 Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,má ṣe gbà fún wọn. 11 Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa;jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan,jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí; 12 jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú,àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò; 13 a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lóría ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa, 14 da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa,a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,” 15 ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn. 16 Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. 17 Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀,ní ojú ẹyẹ! 18 Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.Ara wọn ni wọ́n ń dá lọ́nà. 19 Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ. 20 Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópóó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà; 21 láàrín ọjà ni ó ti kígbe jádení ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀: 22 “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó?Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó?Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀? 23 Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni,ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yínkí n sì fi inú mi hàn sí i yín. 24 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pèkò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn, 25 níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi,tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi, 26 Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín;èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín. 27 Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle,nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà,nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀. 28 “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn;wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi. 29 Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù OLÚWA. 30 Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mití wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi, 31 wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọnwọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún. 32 Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́nìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run; 33 ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwuyóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”
In Other Versions
Proverbs 1 in the ANGEFD
Proverbs 1 in the ANTPNG2D
Proverbs 1 in the AS21
Proverbs 1 in the BAGH
Proverbs 1 in the BBPNG
Proverbs 1 in the BBT1E
Proverbs 1 in the BDS
Proverbs 1 in the BEV
Proverbs 1 in the BHAD
Proverbs 1 in the BIB
Proverbs 1 in the BLPT
Proverbs 1 in the BNT
Proverbs 1 in the BNTABOOT
Proverbs 1 in the BNTLV
Proverbs 1 in the BOATCB
Proverbs 1 in the BOATCB2
Proverbs 1 in the BOBCV
Proverbs 1 in the BOCNT
Proverbs 1 in the BOECS
Proverbs 1 in the BOGWICC
Proverbs 1 in the BOHCB
Proverbs 1 in the BOHCV
Proverbs 1 in the BOHLNT
Proverbs 1 in the BOHNTLTAL
Proverbs 1 in the BOICB
Proverbs 1 in the BOILNTAP
Proverbs 1 in the BOITCV
Proverbs 1 in the BOKCV
Proverbs 1 in the BOKCV2
Proverbs 1 in the BOKHWOG
Proverbs 1 in the BOKSSV
Proverbs 1 in the BOLCB
Proverbs 1 in the BOLCB2
Proverbs 1 in the BOMCV
Proverbs 1 in the BONAV
Proverbs 1 in the BONCB
Proverbs 1 in the BONLT
Proverbs 1 in the BONUT2
Proverbs 1 in the BOPLNT
Proverbs 1 in the BOSCB
Proverbs 1 in the BOSNC
Proverbs 1 in the BOTLNT
Proverbs 1 in the BOVCB
Proverbs 1 in the BPBB
Proverbs 1 in the BPH
Proverbs 1 in the BSB
Proverbs 1 in the CCB
Proverbs 1 in the CUV
Proverbs 1 in the CUVS
Proverbs 1 in the DBT
Proverbs 1 in the DGDNT
Proverbs 1 in the DHNT
Proverbs 1 in the DNT
Proverbs 1 in the ELBE
Proverbs 1 in the EMTV
Proverbs 1 in the ESV
Proverbs 1 in the FBV
Proverbs 1 in the FEB
Proverbs 1 in the GGMNT
Proverbs 1 in the GNT
Proverbs 1 in the HARY
Proverbs 1 in the HNT
Proverbs 1 in the IRVA
Proverbs 1 in the IRVB
Proverbs 1 in the IRVG
Proverbs 1 in the IRVH
Proverbs 1 in the IRVK
Proverbs 1 in the IRVM
Proverbs 1 in the IRVM2
Proverbs 1 in the IRVO
Proverbs 1 in the IRVP
Proverbs 1 in the IRVT
Proverbs 1 in the IRVT2
Proverbs 1 in the IRVU
Proverbs 1 in the ISVN
Proverbs 1 in the JSNT
Proverbs 1 in the KAPI
Proverbs 1 in the KBT1ETNIK
Proverbs 1 in the KBV
Proverbs 1 in the KJV
Proverbs 1 in the KNFD
Proverbs 1 in the LBA
Proverbs 1 in the LBLA
Proverbs 1 in the LNT
Proverbs 1 in the LSV
Proverbs 1 in the MAAL
Proverbs 1 in the MBV
Proverbs 1 in the MBV2
Proverbs 1 in the MHNT
Proverbs 1 in the MKNFD
Proverbs 1 in the MNG
Proverbs 1 in the MNT
Proverbs 1 in the MNT2
Proverbs 1 in the MRS1T
Proverbs 1 in the NAA
Proverbs 1 in the NASB
Proverbs 1 in the NBLA
Proverbs 1 in the NBS
Proverbs 1 in the NBVTP
Proverbs 1 in the NET2
Proverbs 1 in the NIV11
Proverbs 1 in the NNT
Proverbs 1 in the NNT2
Proverbs 1 in the NNT3
Proverbs 1 in the PDDPT
Proverbs 1 in the PFNT
Proverbs 1 in the RMNT
Proverbs 1 in the SBIAS
Proverbs 1 in the SBIBS
Proverbs 1 in the SBIBS2
Proverbs 1 in the SBICS
Proverbs 1 in the SBIDS
Proverbs 1 in the SBIGS
Proverbs 1 in the SBIHS
Proverbs 1 in the SBIIS
Proverbs 1 in the SBIIS2
Proverbs 1 in the SBIIS3
Proverbs 1 in the SBIKS
Proverbs 1 in the SBIKS2
Proverbs 1 in the SBIMS
Proverbs 1 in the SBIOS
Proverbs 1 in the SBIPS
Proverbs 1 in the SBISS
Proverbs 1 in the SBITS
Proverbs 1 in the SBITS2
Proverbs 1 in the SBITS3
Proverbs 1 in the SBITS4
Proverbs 1 in the SBIUS
Proverbs 1 in the SBIVS
Proverbs 1 in the SBT
Proverbs 1 in the SBT1E
Proverbs 1 in the SCHL
Proverbs 1 in the SNT
Proverbs 1 in the SUSU
Proverbs 1 in the SUSU2
Proverbs 1 in the SYNO
Proverbs 1 in the TBIAOTANT
Proverbs 1 in the TBT1E
Proverbs 1 in the TBT1E2
Proverbs 1 in the TFTIP
Proverbs 1 in the TFTU
Proverbs 1 in the TGNTATF3T
Proverbs 1 in the THAI
Proverbs 1 in the TNFD
Proverbs 1 in the TNT
Proverbs 1 in the TNTIK
Proverbs 1 in the TNTIL
Proverbs 1 in the TNTIN
Proverbs 1 in the TNTIP
Proverbs 1 in the TNTIZ
Proverbs 1 in the TOMA
Proverbs 1 in the TTENT
Proverbs 1 in the UBG
Proverbs 1 in the UGV
Proverbs 1 in the UGV2
Proverbs 1 in the UGV3
Proverbs 1 in the VBL
Proverbs 1 in the VDCC
Proverbs 1 in the YALU
Proverbs 1 in the YAPE
Proverbs 1 in the YBVTP
Proverbs 1 in the ZBP