Psalms 11 (BOYCB)
undefined Fún adarí orin. Ti Dafidi. 1 Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú OLÚWA.Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé,“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ. 2 Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùnláti tafà níbi òjìjisí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin. 3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́kí ni olódodo yóò ṣe?” 4 OLÚWA ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; OLÚWA ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò. 5 OLÚWA ń yẹ olódodo wò,ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipáni ọkàn rẹ̀ kórìíra. 6 Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jòẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn. 7 Nítorí, olódodo ní OLÚWA,o fẹ́ràn òdodo;ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.