Psalms 127 (BOYCB)
undefined Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni. 1 Bí kò ṣe pé OLÚWA bá kọ́ ilé náààwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;bí kò ṣe pé OLÚWA bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán. 2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtùláti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run. 3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní OLÚWA:ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀. 4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe. 5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;ojú kì yóò tì wọ́n,ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.