Revelation 3 (BOYCB)

1 “Àti sí angẹli ìjọ ni Sardi kọ̀wé: Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé. Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ní orúkọ pé ìwọ ń bẹ láààyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú. 2 Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tàbí tí ó ṣetán láti kú, nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run. 3 Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ. 4 Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sardi, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ. 5 Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀. 6 Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. 7 “Àti sí angẹli Ìjọ ni Filadelfia kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòtítọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dafidi, ẹni tí ó ṣí, tí kò sí ẹni tí yóò tì; ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i. 8 Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, kíyèsi i, mo gbe ìlẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í; pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi. 9 Kíyèsi i, èmi ó mú àwọn ti Sinagọgu Satani, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké; kíyèsi i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ. 10 Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò. 11 Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán, di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ. 12 Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́, èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi. 13 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. 14 “Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. 15 Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná. 16 Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi. 17 Nítorí tí ìwọ wí pé, èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: 18 Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran. 19 Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà: nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà. 20 Kíyèsi i, èmi dúró ni ẹnu ìlẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohun mi, tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi. 21 Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”

In Other Versions

Revelation 3 in the ANGEFD

Revelation 3 in the ANTPNG2D

Revelation 3 in the AS21

Revelation 3 in the BAGH

Revelation 3 in the BBPNG

Revelation 3 in the BBT1E

Revelation 3 in the BDS

Revelation 3 in the BEV

Revelation 3 in the BHAD

Revelation 3 in the BIB

Revelation 3 in the BLPT

Revelation 3 in the BNT

Revelation 3 in the BNTABOOT

Revelation 3 in the BNTLV

Revelation 3 in the BOATCB

Revelation 3 in the BOATCB2

Revelation 3 in the BOBCV

Revelation 3 in the BOCNT

Revelation 3 in the BOECS

Revelation 3 in the BOGWICC

Revelation 3 in the BOHCB

Revelation 3 in the BOHCV

Revelation 3 in the BOHLNT

Revelation 3 in the BOHNTLTAL

Revelation 3 in the BOICB

Revelation 3 in the BOILNTAP

Revelation 3 in the BOITCV

Revelation 3 in the BOKCV

Revelation 3 in the BOKCV2

Revelation 3 in the BOKHWOG

Revelation 3 in the BOKSSV

Revelation 3 in the BOLCB

Revelation 3 in the BOLCB2

Revelation 3 in the BOMCV

Revelation 3 in the BONAV

Revelation 3 in the BONCB

Revelation 3 in the BONLT

Revelation 3 in the BONUT2

Revelation 3 in the BOPLNT

Revelation 3 in the BOSCB

Revelation 3 in the BOSNC

Revelation 3 in the BOTLNT

Revelation 3 in the BOVCB

Revelation 3 in the BPBB

Revelation 3 in the BPH

Revelation 3 in the BSB

Revelation 3 in the CCB

Revelation 3 in the CUV

Revelation 3 in the CUVS

Revelation 3 in the DBT

Revelation 3 in the DGDNT

Revelation 3 in the DHNT

Revelation 3 in the DNT

Revelation 3 in the ELBE

Revelation 3 in the EMTV

Revelation 3 in the ESV

Revelation 3 in the FBV

Revelation 3 in the FEB

Revelation 3 in the GGMNT

Revelation 3 in the GNT

Revelation 3 in the HARY

Revelation 3 in the HNT

Revelation 3 in the IRVA

Revelation 3 in the IRVB

Revelation 3 in the IRVG

Revelation 3 in the IRVH

Revelation 3 in the IRVK

Revelation 3 in the IRVM

Revelation 3 in the IRVM2

Revelation 3 in the IRVO

Revelation 3 in the IRVP

Revelation 3 in the IRVT

Revelation 3 in the IRVT2

Revelation 3 in the IRVU

Revelation 3 in the ISVN

Revelation 3 in the JSNT

Revelation 3 in the KAPI

Revelation 3 in the KBT1ETNIK

Revelation 3 in the KBV

Revelation 3 in the KJV

Revelation 3 in the KNFD

Revelation 3 in the LBA

Revelation 3 in the LBLA

Revelation 3 in the LNT

Revelation 3 in the LSV

Revelation 3 in the MAAL

Revelation 3 in the MBV

Revelation 3 in the MBV2

Revelation 3 in the MHNT

Revelation 3 in the MKNFD

Revelation 3 in the MNG

Revelation 3 in the MNT

Revelation 3 in the MNT2

Revelation 3 in the MRS1T

Revelation 3 in the NAA

Revelation 3 in the NASB

Revelation 3 in the NBLA

Revelation 3 in the NBS

Revelation 3 in the NBVTP

Revelation 3 in the NET2

Revelation 3 in the NIV11

Revelation 3 in the NNT

Revelation 3 in the NNT2

Revelation 3 in the NNT3

Revelation 3 in the PDDPT

Revelation 3 in the PFNT

Revelation 3 in the RMNT

Revelation 3 in the SBIAS

Revelation 3 in the SBIBS

Revelation 3 in the SBIBS2

Revelation 3 in the SBICS

Revelation 3 in the SBIDS

Revelation 3 in the SBIGS

Revelation 3 in the SBIHS

Revelation 3 in the SBIIS

Revelation 3 in the SBIIS2

Revelation 3 in the SBIIS3

Revelation 3 in the SBIKS

Revelation 3 in the SBIKS2

Revelation 3 in the SBIMS

Revelation 3 in the SBIOS

Revelation 3 in the SBIPS

Revelation 3 in the SBISS

Revelation 3 in the SBITS

Revelation 3 in the SBITS2

Revelation 3 in the SBITS3

Revelation 3 in the SBITS4

Revelation 3 in the SBIUS

Revelation 3 in the SBIVS

Revelation 3 in the SBT

Revelation 3 in the SBT1E

Revelation 3 in the SCHL

Revelation 3 in the SNT

Revelation 3 in the SUSU

Revelation 3 in the SUSU2

Revelation 3 in the SYNO

Revelation 3 in the TBIAOTANT

Revelation 3 in the TBT1E

Revelation 3 in the TBT1E2

Revelation 3 in the TFTIP

Revelation 3 in the TFTU

Revelation 3 in the TGNTATF3T

Revelation 3 in the THAI

Revelation 3 in the TNFD

Revelation 3 in the TNT

Revelation 3 in the TNTIK

Revelation 3 in the TNTIL

Revelation 3 in the TNTIN

Revelation 3 in the TNTIP

Revelation 3 in the TNTIZ

Revelation 3 in the TOMA

Revelation 3 in the TTENT

Revelation 3 in the UBG

Revelation 3 in the UGV

Revelation 3 in the UGV2

Revelation 3 in the UGV3

Revelation 3 in the VBL

Revelation 3 in the VDCC

Revelation 3 in the YALU

Revelation 3 in the YAPE

Revelation 3 in the YBVTP

Revelation 3 in the ZBP