Revelation 9 (BOYCB)

1 Angẹli karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀, mo sì rí, ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá, a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un. 2 Ó sì ṣí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn àti ojú sánmọ̀ sì ṣókùnkùn nítorí èéfín ihò náà. 3 Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀, a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀. 4 A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn. 5 A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù márùn-ún, oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn. 6 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i; wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn. 7 Ìrísí àwọn eṣú náà sì dàbí àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí o dàbí àwọn adé wúrà wà, ojú wọn sì dàbí ojú ènìyàn; 8 wọ́n sì ní irun bí obìnrin, eyín wọn sì dàbí ti kìnnìún. 9 Wọ́n sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin; ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́-ẹṣin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun. 10 Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún. 11 Wọ́n ní angẹli ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ní Abaddoni, àti ni èdè Giriki orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Apollioni (èyí ni Apanirun). 12 Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí. 13 Angẹli kẹfà si fọn ìpè rẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run. 14 Òun wí fún angẹli kẹfà náà tí o ni ìpè náà pé, “Tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Eufurate!” 15 A sì tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèsè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àti oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ́ta ènìyàn. 16 Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba, mo sì gbọ́ iye wọn. 17 Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jakinti, àti ti sulfuru, orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìnnìún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti sulfuru tí ń jáde. 18 Nípa ìyọnu mẹ́ta wọ̀nyí ni a tí pa ìdámẹ́ta ènìyàn, nípa iná, àti nípa èéfín, àti nípa sulfuru tí o ń tí ẹnu wọn jáde. 19 Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pa ni lára. 20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe sin àwọn ẹ̀mí èṣù àti ère wúrà, àti ti fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́rọ̀, tàbí kí wọn rìn. 21 Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbèrè wọn, tàbí olè wọn.

In Other Versions

Revelation 9 in the ANGEFD

Revelation 9 in the ANTPNG2D

Revelation 9 in the AS21

Revelation 9 in the BAGH

Revelation 9 in the BBPNG

Revelation 9 in the BBT1E

Revelation 9 in the BDS

Revelation 9 in the BEV

Revelation 9 in the BHAD

Revelation 9 in the BIB

Revelation 9 in the BLPT

Revelation 9 in the BNT

Revelation 9 in the BNTABOOT

Revelation 9 in the BNTLV

Revelation 9 in the BOATCB

Revelation 9 in the BOATCB2

Revelation 9 in the BOBCV

Revelation 9 in the BOCNT

Revelation 9 in the BOECS

Revelation 9 in the BOGWICC

Revelation 9 in the BOHCB

Revelation 9 in the BOHCV

Revelation 9 in the BOHLNT

Revelation 9 in the BOHNTLTAL

Revelation 9 in the BOICB

Revelation 9 in the BOILNTAP

Revelation 9 in the BOITCV

Revelation 9 in the BOKCV

Revelation 9 in the BOKCV2

Revelation 9 in the BOKHWOG

Revelation 9 in the BOKSSV

Revelation 9 in the BOLCB

Revelation 9 in the BOLCB2

Revelation 9 in the BOMCV

Revelation 9 in the BONAV

Revelation 9 in the BONCB

Revelation 9 in the BONLT

Revelation 9 in the BONUT2

Revelation 9 in the BOPLNT

Revelation 9 in the BOSCB

Revelation 9 in the BOSNC

Revelation 9 in the BOTLNT

Revelation 9 in the BOVCB

Revelation 9 in the BPBB

Revelation 9 in the BPH

Revelation 9 in the BSB

Revelation 9 in the CCB

Revelation 9 in the CUV

Revelation 9 in the CUVS

Revelation 9 in the DBT

Revelation 9 in the DGDNT

Revelation 9 in the DHNT

Revelation 9 in the DNT

Revelation 9 in the ELBE

Revelation 9 in the EMTV

Revelation 9 in the ESV

Revelation 9 in the FBV

Revelation 9 in the FEB

Revelation 9 in the GGMNT

Revelation 9 in the GNT

Revelation 9 in the HARY

Revelation 9 in the HNT

Revelation 9 in the IRVA

Revelation 9 in the IRVB

Revelation 9 in the IRVG

Revelation 9 in the IRVH

Revelation 9 in the IRVK

Revelation 9 in the IRVM

Revelation 9 in the IRVM2

Revelation 9 in the IRVO

Revelation 9 in the IRVP

Revelation 9 in the IRVT

Revelation 9 in the IRVT2

Revelation 9 in the IRVU

Revelation 9 in the ISVN

Revelation 9 in the JSNT

Revelation 9 in the KAPI

Revelation 9 in the KBT1ETNIK

Revelation 9 in the KBV

Revelation 9 in the KJV

Revelation 9 in the KNFD

Revelation 9 in the LBA

Revelation 9 in the LBLA

Revelation 9 in the LNT

Revelation 9 in the LSV

Revelation 9 in the MAAL

Revelation 9 in the MBV

Revelation 9 in the MBV2

Revelation 9 in the MHNT

Revelation 9 in the MKNFD

Revelation 9 in the MNG

Revelation 9 in the MNT

Revelation 9 in the MNT2

Revelation 9 in the MRS1T

Revelation 9 in the NAA

Revelation 9 in the NASB

Revelation 9 in the NBLA

Revelation 9 in the NBS

Revelation 9 in the NBVTP

Revelation 9 in the NET2

Revelation 9 in the NIV11

Revelation 9 in the NNT

Revelation 9 in the NNT2

Revelation 9 in the NNT3

Revelation 9 in the PDDPT

Revelation 9 in the PFNT

Revelation 9 in the RMNT

Revelation 9 in the SBIAS

Revelation 9 in the SBIBS

Revelation 9 in the SBIBS2

Revelation 9 in the SBICS

Revelation 9 in the SBIDS

Revelation 9 in the SBIGS

Revelation 9 in the SBIHS

Revelation 9 in the SBIIS

Revelation 9 in the SBIIS2

Revelation 9 in the SBIIS3

Revelation 9 in the SBIKS

Revelation 9 in the SBIKS2

Revelation 9 in the SBIMS

Revelation 9 in the SBIOS

Revelation 9 in the SBIPS

Revelation 9 in the SBISS

Revelation 9 in the SBITS

Revelation 9 in the SBITS2

Revelation 9 in the SBITS3

Revelation 9 in the SBITS4

Revelation 9 in the SBIUS

Revelation 9 in the SBIVS

Revelation 9 in the SBT

Revelation 9 in the SBT1E

Revelation 9 in the SCHL

Revelation 9 in the SNT

Revelation 9 in the SUSU

Revelation 9 in the SUSU2

Revelation 9 in the SYNO

Revelation 9 in the TBIAOTANT

Revelation 9 in the TBT1E

Revelation 9 in the TBT1E2

Revelation 9 in the TFTIP

Revelation 9 in the TFTU

Revelation 9 in the TGNTATF3T

Revelation 9 in the THAI

Revelation 9 in the TNFD

Revelation 9 in the TNT

Revelation 9 in the TNTIK

Revelation 9 in the TNTIL

Revelation 9 in the TNTIN

Revelation 9 in the TNTIP

Revelation 9 in the TNTIZ

Revelation 9 in the TOMA

Revelation 9 in the TTENT

Revelation 9 in the UBG

Revelation 9 in the UGV

Revelation 9 in the UGV2

Revelation 9 in the UGV3

Revelation 9 in the VBL

Revelation 9 in the VDCC

Revelation 9 in the YALU

Revelation 9 in the YAPE

Revelation 9 in the YBVTP

Revelation 9 in the ZBP