Romans 2 (BOYCB)
1 Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́, nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́. 2 Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí. 3 Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tìkára rẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí? 4 Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà? 5 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. 6 Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. 7 Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún. 8 Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrunú àti ìbínú rẹ̀. 9 Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn Helleni pẹ̀lú; 10 ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 11 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 12 Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin, àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́. 13 Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre. 14 Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin. 15 Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. 16 Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi. 17 Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, 18 tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; 19 tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, 20 Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́. 21 Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? 22 Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? 23 Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin? 24 Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Orúkọ Ọlọ́run sá à di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrín àwọn aláìkọlà nítorí yín.” 25 Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà. 26 Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí a kọ nílà bí? 27 Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà. 28 Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà. 29 Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
In Other Versions
Romans 2 in the ANGEFD
Romans 2 in the ANTPNG2D
Romans 2 in the AS21
Romans 2 in the BAGH
Romans 2 in the BBPNG
Romans 2 in the BBT1E
Romans 2 in the BDS
Romans 2 in the BEV
Romans 2 in the BHAD
Romans 2 in the BIB
Romans 2 in the BLPT
Romans 2 in the BNT
Romans 2 in the BNTABOOT
Romans 2 in the BNTLV
Romans 2 in the BOATCB
Romans 2 in the BOATCB2
Romans 2 in the BOBCV
Romans 2 in the BOCNT
Romans 2 in the BOECS
Romans 2 in the BOGWICC
Romans 2 in the BOHCB
Romans 2 in the BOHCV
Romans 2 in the BOHLNT
Romans 2 in the BOHNTLTAL
Romans 2 in the BOICB
Romans 2 in the BOILNTAP
Romans 2 in the BOITCV
Romans 2 in the BOKCV
Romans 2 in the BOKCV2
Romans 2 in the BOKHWOG
Romans 2 in the BOKSSV
Romans 2 in the BOLCB
Romans 2 in the BOLCB2
Romans 2 in the BOMCV
Romans 2 in the BONAV
Romans 2 in the BONCB
Romans 2 in the BONLT
Romans 2 in the BONUT2
Romans 2 in the BOPLNT
Romans 2 in the BOSCB
Romans 2 in the BOSNC
Romans 2 in the BOTLNT
Romans 2 in the BOVCB
Romans 2 in the BPBB
Romans 2 in the BPH
Romans 2 in the BSB
Romans 2 in the CCB
Romans 2 in the CUV
Romans 2 in the CUVS
Romans 2 in the DBT
Romans 2 in the DGDNT
Romans 2 in the DHNT
Romans 2 in the DNT
Romans 2 in the ELBE
Romans 2 in the EMTV
Romans 2 in the ESV
Romans 2 in the FBV
Romans 2 in the FEB
Romans 2 in the GGMNT
Romans 2 in the GNT
Romans 2 in the HARY
Romans 2 in the HNT
Romans 2 in the IRVA
Romans 2 in the IRVB
Romans 2 in the IRVG
Romans 2 in the IRVH
Romans 2 in the IRVK
Romans 2 in the IRVM
Romans 2 in the IRVM2
Romans 2 in the IRVO
Romans 2 in the IRVP
Romans 2 in the IRVT
Romans 2 in the IRVT2
Romans 2 in the IRVU
Romans 2 in the ISVN
Romans 2 in the JSNT
Romans 2 in the KAPI
Romans 2 in the KBT1ETNIK
Romans 2 in the KBV
Romans 2 in the KJV
Romans 2 in the KNFD
Romans 2 in the LBA
Romans 2 in the LBLA
Romans 2 in the LNT
Romans 2 in the LSV
Romans 2 in the MAAL
Romans 2 in the MBV
Romans 2 in the MBV2
Romans 2 in the MHNT
Romans 2 in the MKNFD
Romans 2 in the MNG
Romans 2 in the MNT
Romans 2 in the MNT2
Romans 2 in the MRS1T
Romans 2 in the NAA
Romans 2 in the NASB
Romans 2 in the NBLA
Romans 2 in the NBS
Romans 2 in the NBVTP
Romans 2 in the NET2
Romans 2 in the NIV11
Romans 2 in the NNT
Romans 2 in the NNT2
Romans 2 in the NNT3
Romans 2 in the PDDPT
Romans 2 in the PFNT
Romans 2 in the RMNT
Romans 2 in the SBIAS
Romans 2 in the SBIBS
Romans 2 in the SBIBS2
Romans 2 in the SBICS
Romans 2 in the SBIDS
Romans 2 in the SBIGS
Romans 2 in the SBIHS
Romans 2 in the SBIIS
Romans 2 in the SBIIS2
Romans 2 in the SBIIS3
Romans 2 in the SBIKS
Romans 2 in the SBIKS2
Romans 2 in the SBIMS
Romans 2 in the SBIOS
Romans 2 in the SBIPS
Romans 2 in the SBISS
Romans 2 in the SBITS
Romans 2 in the SBITS2
Romans 2 in the SBITS3
Romans 2 in the SBITS4
Romans 2 in the SBIUS
Romans 2 in the SBIVS
Romans 2 in the SBT
Romans 2 in the SBT1E
Romans 2 in the SCHL
Romans 2 in the SNT
Romans 2 in the SUSU
Romans 2 in the SUSU2
Romans 2 in the SYNO
Romans 2 in the TBIAOTANT
Romans 2 in the TBT1E
Romans 2 in the TBT1E2
Romans 2 in the TFTIP
Romans 2 in the TFTU
Romans 2 in the TGNTATF3T
Romans 2 in the THAI
Romans 2 in the TNFD
Romans 2 in the TNT
Romans 2 in the TNTIK
Romans 2 in the TNTIL
Romans 2 in the TNTIN
Romans 2 in the TNTIP
Romans 2 in the TNTIZ
Romans 2 in the TOMA
Romans 2 in the TTENT
Romans 2 in the UBG
Romans 2 in the UGV
Romans 2 in the UGV2
Romans 2 in the UGV3
Romans 2 in the VBL
Romans 2 in the VDCC
Romans 2 in the YALU
Romans 2 in the YAPE
Romans 2 in the YBVTP
Romans 2 in the ZBP