Zephaniah 1 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda. 2 “Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúròlórí ilẹ̀ náà pátápátá,”ni OLÚWA wí. 3 “Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò;èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò, àti ẹja inú Òkun,àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú;èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,”ni OLÚWA wí. 4 “Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Judaàti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu.Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣàpẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà, 5 àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé,àwọn tí ń sin ogun ọ̀run,àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi OLÚWA búra,tí wọ́n sì ń fi Moleki búra. 6 Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ OLÚWA;àti àwọn tí kò tí wá OLÚWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.” 7 Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLÚWA Olódùmarè,nítorí tí ọjọ́ OLÚWA kù sí dẹ̀dẹ̀. OLÚWA ti pèsè ẹbọ kan sílẹ̀,ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́. 8 “Ní ọjọ́ ẹbọ OLÚWA,Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò,àti àwọn ọmọ ọba ọkùnrin,pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ. 9 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹgbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu-ọ̀nà,tí wọ́n sì kún tẹmpili àwọn ọlọ́run wọnpẹ̀lú ìwà ipá àti ẹ̀tàn. 10 “Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí,“Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà ibodè ẹja,híhu láti ìhà kejì wá àtiariwo ńlá láti òkè kékeré wá. 11 Ẹ hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà,gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò,gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun. 12 Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jerusalẹmu kiri pẹ̀lú fìtílà,èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn,tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘OLÚWA kì yóò ṣe nǹkan kantí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’ 13 Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógun,àti ilé wọn yóò sì run.Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú,ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà,wọn yóò gbin ọgbà àjàrà,ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtíwáìnì láti inú rẹ̀.” 14 “Ọjọ́ ńlá OLÚWA kù sí dẹ̀dẹ̀,ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán.Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára;ní ọjọ́ OLÚWA yóò korò púpọ̀, 15 ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú,ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú,ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoroọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba,ọjọ́ kurukuru àti òkùnkùn biribiri, 16 ọjọ́ ìpè àti ìpè ogunsí àwọn ìlú olódiàti sí àwọn ilé ìṣọ́ gíga. 17 “Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí ènìyàn,wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú,nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLÚWA.Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí erukuàti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́. 18 Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọnkì yóò sì le gbà wọ́n làní ọjọ́ ìbínú OLÚWA.” Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi ináìjowú rẹ̀ parun,nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sígbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ayé.
In Other Versions
Zephaniah 1 in the ANGEFD
Zephaniah 1 in the ANTPNG2D
Zephaniah 1 in the AS21
Zephaniah 1 in the BAGH
Zephaniah 1 in the BBPNG
Zephaniah 1 in the BBT1E
Zephaniah 1 in the BDS
Zephaniah 1 in the BEV
Zephaniah 1 in the BHAD
Zephaniah 1 in the BIB
Zephaniah 1 in the BLPT
Zephaniah 1 in the BNT
Zephaniah 1 in the BNTABOOT
Zephaniah 1 in the BNTLV
Zephaniah 1 in the BOATCB
Zephaniah 1 in the BOATCB2
Zephaniah 1 in the BOBCV
Zephaniah 1 in the BOCNT
Zephaniah 1 in the BOECS
Zephaniah 1 in the BOGWICC
Zephaniah 1 in the BOHCB
Zephaniah 1 in the BOHCV
Zephaniah 1 in the BOHLNT
Zephaniah 1 in the BOHNTLTAL
Zephaniah 1 in the BOICB
Zephaniah 1 in the BOILNTAP
Zephaniah 1 in the BOITCV
Zephaniah 1 in the BOKCV
Zephaniah 1 in the BOKCV2
Zephaniah 1 in the BOKHWOG
Zephaniah 1 in the BOKSSV
Zephaniah 1 in the BOLCB
Zephaniah 1 in the BOLCB2
Zephaniah 1 in the BOMCV
Zephaniah 1 in the BONAV
Zephaniah 1 in the BONCB
Zephaniah 1 in the BONLT
Zephaniah 1 in the BONUT2
Zephaniah 1 in the BOPLNT
Zephaniah 1 in the BOSCB
Zephaniah 1 in the BOSNC
Zephaniah 1 in the BOTLNT
Zephaniah 1 in the BOVCB
Zephaniah 1 in the BPBB
Zephaniah 1 in the BPH
Zephaniah 1 in the BSB
Zephaniah 1 in the CCB
Zephaniah 1 in the CUV
Zephaniah 1 in the CUVS
Zephaniah 1 in the DBT
Zephaniah 1 in the DGDNT
Zephaniah 1 in the DHNT
Zephaniah 1 in the DNT
Zephaniah 1 in the ELBE
Zephaniah 1 in the EMTV
Zephaniah 1 in the ESV
Zephaniah 1 in the FBV
Zephaniah 1 in the FEB
Zephaniah 1 in the GGMNT
Zephaniah 1 in the GNT
Zephaniah 1 in the HARY
Zephaniah 1 in the HNT
Zephaniah 1 in the IRVA
Zephaniah 1 in the IRVB
Zephaniah 1 in the IRVG
Zephaniah 1 in the IRVH
Zephaniah 1 in the IRVK
Zephaniah 1 in the IRVM
Zephaniah 1 in the IRVM2
Zephaniah 1 in the IRVO
Zephaniah 1 in the IRVP
Zephaniah 1 in the IRVT
Zephaniah 1 in the IRVT2
Zephaniah 1 in the IRVU
Zephaniah 1 in the ISVN
Zephaniah 1 in the JSNT
Zephaniah 1 in the KAPI
Zephaniah 1 in the KBT1ETNIK
Zephaniah 1 in the KBV
Zephaniah 1 in the KJV
Zephaniah 1 in the KNFD
Zephaniah 1 in the LBA
Zephaniah 1 in the LBLA
Zephaniah 1 in the LNT
Zephaniah 1 in the LSV
Zephaniah 1 in the MAAL
Zephaniah 1 in the MBV
Zephaniah 1 in the MBV2
Zephaniah 1 in the MHNT
Zephaniah 1 in the MKNFD
Zephaniah 1 in the MNG
Zephaniah 1 in the MNT
Zephaniah 1 in the MNT2
Zephaniah 1 in the MRS1T
Zephaniah 1 in the NAA
Zephaniah 1 in the NASB
Zephaniah 1 in the NBLA
Zephaniah 1 in the NBS
Zephaniah 1 in the NBVTP
Zephaniah 1 in the NET2
Zephaniah 1 in the NIV11
Zephaniah 1 in the NNT
Zephaniah 1 in the NNT2
Zephaniah 1 in the NNT3
Zephaniah 1 in the PDDPT
Zephaniah 1 in the PFNT
Zephaniah 1 in the RMNT
Zephaniah 1 in the SBIAS
Zephaniah 1 in the SBIBS
Zephaniah 1 in the SBIBS2
Zephaniah 1 in the SBICS
Zephaniah 1 in the SBIDS
Zephaniah 1 in the SBIGS
Zephaniah 1 in the SBIHS
Zephaniah 1 in the SBIIS
Zephaniah 1 in the SBIIS2
Zephaniah 1 in the SBIIS3
Zephaniah 1 in the SBIKS
Zephaniah 1 in the SBIKS2
Zephaniah 1 in the SBIMS
Zephaniah 1 in the SBIOS
Zephaniah 1 in the SBIPS
Zephaniah 1 in the SBISS
Zephaniah 1 in the SBITS
Zephaniah 1 in the SBITS2
Zephaniah 1 in the SBITS3
Zephaniah 1 in the SBITS4
Zephaniah 1 in the SBIUS
Zephaniah 1 in the SBIVS
Zephaniah 1 in the SBT
Zephaniah 1 in the SBT1E
Zephaniah 1 in the SCHL
Zephaniah 1 in the SNT
Zephaniah 1 in the SUSU
Zephaniah 1 in the SUSU2
Zephaniah 1 in the SYNO
Zephaniah 1 in the TBIAOTANT
Zephaniah 1 in the TBT1E
Zephaniah 1 in the TBT1E2
Zephaniah 1 in the TFTIP
Zephaniah 1 in the TFTU
Zephaniah 1 in the TGNTATF3T
Zephaniah 1 in the THAI
Zephaniah 1 in the TNFD
Zephaniah 1 in the TNT
Zephaniah 1 in the TNTIK
Zephaniah 1 in the TNTIL
Zephaniah 1 in the TNTIN
Zephaniah 1 in the TNTIP
Zephaniah 1 in the TNTIZ
Zephaniah 1 in the TOMA
Zephaniah 1 in the TTENT
Zephaniah 1 in the UBG
Zephaniah 1 in the UGV
Zephaniah 1 in the UGV2
Zephaniah 1 in the UGV3
Zephaniah 1 in the VBL
Zephaniah 1 in the VDCC
Zephaniah 1 in the YALU
Zephaniah 1 in the YAPE
Zephaniah 1 in the YBVTP
Zephaniah 1 in the ZBP