2 Timothy 1 (BOYCB)

1 Paulu, aposteli ti Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kristi Jesu, 2 Sí Timotiu, ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kristi Jesu Olúwa wa. 3 Mo dá ọpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsimi lọ́sàn án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi. 4 Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀. 5 Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá ńlá rẹ, àti nínú Eunike ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó dá mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú. 6 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi. 7 Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro. 8 Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìyìnrere nípa agbára Ọlọ́run, 9 ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé, 10 ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìyìnrere. 11 Fún ti ìyìnrere tí a yàn mi láti jẹ oníwàásù àti aposteli àti olùkọ́. 12 Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí, nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà. 13 Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu. 14 Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa. 15 Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Asia ti fi mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Figeliu àti Hamogene gbé wà. 16 Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú. 17 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Romu, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi. 18 Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkára rẹ sá à mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà ràn mí lọ́wọ́ ni Efesu.

In Other Versions

2 Timothy 1 in the ANGEFD

2 Timothy 1 in the ANTPNG2D

2 Timothy 1 in the AS21

2 Timothy 1 in the BAGH

2 Timothy 1 in the BBPNG

2 Timothy 1 in the BBT1E

2 Timothy 1 in the BDS

2 Timothy 1 in the BEV

2 Timothy 1 in the BHAD

2 Timothy 1 in the BIB

2 Timothy 1 in the BLPT

2 Timothy 1 in the BNT

2 Timothy 1 in the BNTABOOT

2 Timothy 1 in the BNTLV

2 Timothy 1 in the BOATCB

2 Timothy 1 in the BOATCB2

2 Timothy 1 in the BOBCV

2 Timothy 1 in the BOCNT

2 Timothy 1 in the BOECS

2 Timothy 1 in the BOGWICC

2 Timothy 1 in the BOHCB

2 Timothy 1 in the BOHCV

2 Timothy 1 in the BOHLNT

2 Timothy 1 in the BOHNTLTAL

2 Timothy 1 in the BOICB

2 Timothy 1 in the BOILNTAP

2 Timothy 1 in the BOITCV

2 Timothy 1 in the BOKCV

2 Timothy 1 in the BOKCV2

2 Timothy 1 in the BOKHWOG

2 Timothy 1 in the BOKSSV

2 Timothy 1 in the BOLCB

2 Timothy 1 in the BOLCB2

2 Timothy 1 in the BOMCV

2 Timothy 1 in the BONAV

2 Timothy 1 in the BONCB

2 Timothy 1 in the BONLT

2 Timothy 1 in the BONUT2

2 Timothy 1 in the BOPLNT

2 Timothy 1 in the BOSCB

2 Timothy 1 in the BOSNC

2 Timothy 1 in the BOTLNT

2 Timothy 1 in the BOVCB

2 Timothy 1 in the BPBB

2 Timothy 1 in the BPH

2 Timothy 1 in the BSB

2 Timothy 1 in the CCB

2 Timothy 1 in the CUV

2 Timothy 1 in the CUVS

2 Timothy 1 in the DBT

2 Timothy 1 in the DGDNT

2 Timothy 1 in the DHNT

2 Timothy 1 in the DNT

2 Timothy 1 in the ELBE

2 Timothy 1 in the EMTV

2 Timothy 1 in the ESV

2 Timothy 1 in the FBV

2 Timothy 1 in the FEB

2 Timothy 1 in the GGMNT

2 Timothy 1 in the GNT

2 Timothy 1 in the HARY

2 Timothy 1 in the HNT

2 Timothy 1 in the IRVA

2 Timothy 1 in the IRVB

2 Timothy 1 in the IRVG

2 Timothy 1 in the IRVH

2 Timothy 1 in the IRVK

2 Timothy 1 in the IRVM

2 Timothy 1 in the IRVM2

2 Timothy 1 in the IRVO

2 Timothy 1 in the IRVP

2 Timothy 1 in the IRVT

2 Timothy 1 in the IRVT2

2 Timothy 1 in the IRVU

2 Timothy 1 in the ISVN

2 Timothy 1 in the JSNT

2 Timothy 1 in the KAPI

2 Timothy 1 in the KBT1ETNIK

2 Timothy 1 in the KBV

2 Timothy 1 in the KJV

2 Timothy 1 in the KNFD

2 Timothy 1 in the LBA

2 Timothy 1 in the LBLA

2 Timothy 1 in the LNT

2 Timothy 1 in the LSV

2 Timothy 1 in the MAAL

2 Timothy 1 in the MBV

2 Timothy 1 in the MBV2

2 Timothy 1 in the MHNT

2 Timothy 1 in the MKNFD

2 Timothy 1 in the MNG

2 Timothy 1 in the MNT

2 Timothy 1 in the MNT2

2 Timothy 1 in the MRS1T

2 Timothy 1 in the NAA

2 Timothy 1 in the NASB

2 Timothy 1 in the NBLA

2 Timothy 1 in the NBS

2 Timothy 1 in the NBVTP

2 Timothy 1 in the NET2

2 Timothy 1 in the NIV11

2 Timothy 1 in the NNT

2 Timothy 1 in the NNT2

2 Timothy 1 in the NNT3

2 Timothy 1 in the PDDPT

2 Timothy 1 in the PFNT

2 Timothy 1 in the RMNT

2 Timothy 1 in the SBIAS

2 Timothy 1 in the SBIBS

2 Timothy 1 in the SBIBS2

2 Timothy 1 in the SBICS

2 Timothy 1 in the SBIDS

2 Timothy 1 in the SBIGS

2 Timothy 1 in the SBIHS

2 Timothy 1 in the SBIIS

2 Timothy 1 in the SBIIS2

2 Timothy 1 in the SBIIS3

2 Timothy 1 in the SBIKS

2 Timothy 1 in the SBIKS2

2 Timothy 1 in the SBIMS

2 Timothy 1 in the SBIOS

2 Timothy 1 in the SBIPS

2 Timothy 1 in the SBISS

2 Timothy 1 in the SBITS

2 Timothy 1 in the SBITS2

2 Timothy 1 in the SBITS3

2 Timothy 1 in the SBITS4

2 Timothy 1 in the SBIUS

2 Timothy 1 in the SBIVS

2 Timothy 1 in the SBT

2 Timothy 1 in the SBT1E

2 Timothy 1 in the SCHL

2 Timothy 1 in the SNT

2 Timothy 1 in the SUSU

2 Timothy 1 in the SUSU2

2 Timothy 1 in the SYNO

2 Timothy 1 in the TBIAOTANT

2 Timothy 1 in the TBT1E

2 Timothy 1 in the TBT1E2

2 Timothy 1 in the TFTIP

2 Timothy 1 in the TFTU

2 Timothy 1 in the TGNTATF3T

2 Timothy 1 in the THAI

2 Timothy 1 in the TNFD

2 Timothy 1 in the TNT

2 Timothy 1 in the TNTIK

2 Timothy 1 in the TNTIL

2 Timothy 1 in the TNTIN

2 Timothy 1 in the TNTIP

2 Timothy 1 in the TNTIZ

2 Timothy 1 in the TOMA

2 Timothy 1 in the TTENT

2 Timothy 1 in the UBG

2 Timothy 1 in the UGV

2 Timothy 1 in the UGV2

2 Timothy 1 in the UGV3

2 Timothy 1 in the VBL

2 Timothy 1 in the VDCC

2 Timothy 1 in the YALU

2 Timothy 1 in the YAPE

2 Timothy 1 in the YBVTP

2 Timothy 1 in the ZBP