Acts 3 (BOYCB)

1 Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán. 2 Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ. 3 Nígbà tí ó rí Peteru àti Johanu bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹmpili, ó ṣagbe. 4 Peteru sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Johanu, ó ní “Wò wá!” 5 Ó sì fiyèsí wọn, ó ń retí láti rí nǹkan láti gbà lọ́wọ́ wọn. 6 Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.” 7 Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkan náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun. 8 Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹmpili lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run. 9 Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run, 10 Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe ní ẹnu-ọ̀nà Dáradára ti tẹmpili náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀. 11 Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Peteru àti Johanu mú, gbogbo ènìyàn jùmọ̀ súre tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Solomoni, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu ńlá. 12 Nígbà tí Peteru sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, èéṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí èéṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn? 13 Ọlọ́run Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jesu ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo; ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pilatu, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀. 14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣẹ́ Ẹni Mímọ́ àti Olóòótọ́ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín. 15 Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́. 16 Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jesu, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jesu àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín. 17 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe. 18 Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà. 19 Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, 20 àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu. 21 Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀. 22 Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín. 23 Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ 24 “Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Samuẹli wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú. 25 Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Abrahamu pé, ‘Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé.’ 26 Nígbà ti Ọlọ́run jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dìde, ó kọ́ rán an sí i yín láti bùkún fún un yín, nípa yíyí olúkúlùkù yín padà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.”

In Other Versions

Acts 3 in the ANGEFD

Acts 3 in the ANTPNG2D

Acts 3 in the AS21

Acts 3 in the BAGH

Acts 3 in the BBPNG

Acts 3 in the BBT1E

Acts 3 in the BDS

Acts 3 in the BEV

Acts 3 in the BHAD

Acts 3 in the BIB

Acts 3 in the BLPT

Acts 3 in the BNT

Acts 3 in the BNTABOOT

Acts 3 in the BNTLV

Acts 3 in the BOATCB

Acts 3 in the BOATCB2

Acts 3 in the BOBCV

Acts 3 in the BOCNT

Acts 3 in the BOECS

Acts 3 in the BOGWICC

Acts 3 in the BOHCB

Acts 3 in the BOHCV

Acts 3 in the BOHLNT

Acts 3 in the BOHNTLTAL

Acts 3 in the BOICB

Acts 3 in the BOILNTAP

Acts 3 in the BOITCV

Acts 3 in the BOKCV

Acts 3 in the BOKCV2

Acts 3 in the BOKHWOG

Acts 3 in the BOKSSV

Acts 3 in the BOLCB

Acts 3 in the BOLCB2

Acts 3 in the BOMCV

Acts 3 in the BONAV

Acts 3 in the BONCB

Acts 3 in the BONLT

Acts 3 in the BONUT2

Acts 3 in the BOPLNT

Acts 3 in the BOSCB

Acts 3 in the BOSNC

Acts 3 in the BOTLNT

Acts 3 in the BOVCB

Acts 3 in the BPBB

Acts 3 in the BPH

Acts 3 in the BSB

Acts 3 in the CCB

Acts 3 in the CUV

Acts 3 in the CUVS

Acts 3 in the DBT

Acts 3 in the DGDNT

Acts 3 in the DHNT

Acts 3 in the DNT

Acts 3 in the ELBE

Acts 3 in the EMTV

Acts 3 in the ESV

Acts 3 in the FBV

Acts 3 in the FEB

Acts 3 in the GGMNT

Acts 3 in the GNT

Acts 3 in the HARY

Acts 3 in the HNT

Acts 3 in the IRVA

Acts 3 in the IRVB

Acts 3 in the IRVG

Acts 3 in the IRVH

Acts 3 in the IRVK

Acts 3 in the IRVM

Acts 3 in the IRVM2

Acts 3 in the IRVO

Acts 3 in the IRVP

Acts 3 in the IRVT

Acts 3 in the IRVT2

Acts 3 in the IRVU

Acts 3 in the ISVN

Acts 3 in the JSNT

Acts 3 in the KAPI

Acts 3 in the KBT1ETNIK

Acts 3 in the KBV

Acts 3 in the KJV

Acts 3 in the KNFD

Acts 3 in the LBA

Acts 3 in the LBLA

Acts 3 in the LNT

Acts 3 in the LSV

Acts 3 in the MAAL

Acts 3 in the MBV

Acts 3 in the MBV2

Acts 3 in the MHNT

Acts 3 in the MKNFD

Acts 3 in the MNG

Acts 3 in the MNT

Acts 3 in the MNT2

Acts 3 in the MRS1T

Acts 3 in the NAA

Acts 3 in the NASB

Acts 3 in the NBLA

Acts 3 in the NBS

Acts 3 in the NBVTP

Acts 3 in the NET2

Acts 3 in the NIV11

Acts 3 in the NNT

Acts 3 in the NNT2

Acts 3 in the NNT3

Acts 3 in the PDDPT

Acts 3 in the PFNT

Acts 3 in the RMNT

Acts 3 in the SBIAS

Acts 3 in the SBIBS

Acts 3 in the SBIBS2

Acts 3 in the SBICS

Acts 3 in the SBIDS

Acts 3 in the SBIGS

Acts 3 in the SBIHS

Acts 3 in the SBIIS

Acts 3 in the SBIIS2

Acts 3 in the SBIIS3

Acts 3 in the SBIKS

Acts 3 in the SBIKS2

Acts 3 in the SBIMS

Acts 3 in the SBIOS

Acts 3 in the SBIPS

Acts 3 in the SBISS

Acts 3 in the SBITS

Acts 3 in the SBITS2

Acts 3 in the SBITS3

Acts 3 in the SBITS4

Acts 3 in the SBIUS

Acts 3 in the SBIVS

Acts 3 in the SBT

Acts 3 in the SBT1E

Acts 3 in the SCHL

Acts 3 in the SNT

Acts 3 in the SUSU

Acts 3 in the SUSU2

Acts 3 in the SYNO

Acts 3 in the TBIAOTANT

Acts 3 in the TBT1E

Acts 3 in the TBT1E2

Acts 3 in the TFTIP

Acts 3 in the TFTU

Acts 3 in the TGNTATF3T

Acts 3 in the THAI

Acts 3 in the TNFD

Acts 3 in the TNT

Acts 3 in the TNTIK

Acts 3 in the TNTIL

Acts 3 in the TNTIN

Acts 3 in the TNTIP

Acts 3 in the TNTIZ

Acts 3 in the TOMA

Acts 3 in the TTENT

Acts 3 in the UBG

Acts 3 in the UGV

Acts 3 in the UGV2

Acts 3 in the UGV3

Acts 3 in the VBL

Acts 3 in the VDCC

Acts 3 in the YALU

Acts 3 in the YAPE

Acts 3 in the YBVTP

Acts 3 in the ZBP