Ezekiel 27 (BOYCB)

1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tire. 3 Sọ fún Tire, tí a tẹ̀dó sí ẹnu-bodè Òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Ìwọ Tire wí pé,“Ẹwà mi pé.” 4 Ààlà rẹ wà ní àárín Òkun;àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé. 5 Wọn ṣe gbogbo pákó rẹní igi junifa láti Seniri;wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wáláti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ. 6 Nínú igi óákù ti Baṣaniní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀;ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lúigi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá. 7 Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wáni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ;aṣọ aláró àti elése àlùkòláti erékùṣù ti Eliṣani èyí tí a fi bò ó. 8 Àwọn ará ìlú Sidoni àti Arfadi ni àwọn atukọ̀ rẹ̀àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tire,ni àwọn atukọ̀ rẹ. 9 Àwọn àgbàgbà Gebali,àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,gbogbo ọkọ̀ ojú Òkunàti àwọn atukọ̀ Òkunwá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. 10 “ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Putiwà nínú jagunjagun rẹàwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ.Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn rósára ògiri rẹ,wọn fi ẹwà rẹ hàn. 11 Àwọn ènìyàn Arfadi àti Helekiwà lórí odi rẹ yíká;àti àwọn akọni Gamadi,wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;wọn ti mú ẹwà rẹ pé. 12 “ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀. 13 “ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ, wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ. 14 “ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ. 15 “ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ. 16 “ ‘Aramu ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elése àlùkò, aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ. 17 “ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ. 18 “ ‘Damasku ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari, 19 àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ. 20 “ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn. 21 “ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé ìlú Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ; ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ. 22 “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà. 23 “ ‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ. 24 Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ. 25 “ ‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èròní ọjà rẹa ti mú ọ gbilẹ̀a sì ti ṣe ọ́ lógoní àárín gbùngbùn Òkun. 26 Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọwá sínú omi ńlá.Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ní àárín gbùngbùn Òkun. 27 Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ,àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹtí ó wà ní àárín rẹyóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkunní ọjọ́ ìparun rẹ. 28 Ilẹ̀ etí Òkun yóò mìnítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ. 29 Gbogbo àwọn alájẹ̀,àwọn atukọ̀ Òkunàti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun;yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,wọn yóò dúró lórí ilẹ̀. 30 Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọwọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lóríwọn yóò ku eruku lé orí ara wọnwọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú. 31 Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹwọn yóò wọ aṣọ yíyawọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lúìkorò ọkàn nítorí rẹpẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò. 32 Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọwọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé:“Ta ni ó dàbí Tireèyí tí ó parun ní àárín Òkun?” 33 Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wáìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùnìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹsọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀. 34 Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúúnínú ibú omi;nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹní àárín rẹ,ni yóò ṣubú. 35 Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbéní erékùṣù náà sí ọjìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn,ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn. 36 Àwọn oníṣòwò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè dún bí ejò sí ọìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rùìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”

In Other Versions

Ezekiel 27 in the ANGEFD

Ezekiel 27 in the ANTPNG2D

Ezekiel 27 in the AS21

Ezekiel 27 in the BAGH

Ezekiel 27 in the BBPNG

Ezekiel 27 in the BBT1E

Ezekiel 27 in the BDS

Ezekiel 27 in the BEV

Ezekiel 27 in the BHAD

Ezekiel 27 in the BIB

Ezekiel 27 in the BLPT

Ezekiel 27 in the BNT

Ezekiel 27 in the BNTABOOT

Ezekiel 27 in the BNTLV

Ezekiel 27 in the BOATCB

Ezekiel 27 in the BOATCB2

Ezekiel 27 in the BOBCV

Ezekiel 27 in the BOCNT

Ezekiel 27 in the BOECS

Ezekiel 27 in the BOGWICC

Ezekiel 27 in the BOHCB

Ezekiel 27 in the BOHCV

Ezekiel 27 in the BOHLNT

Ezekiel 27 in the BOHNTLTAL

Ezekiel 27 in the BOICB

Ezekiel 27 in the BOILNTAP

Ezekiel 27 in the BOITCV

Ezekiel 27 in the BOKCV

Ezekiel 27 in the BOKCV2

Ezekiel 27 in the BOKHWOG

Ezekiel 27 in the BOKSSV

Ezekiel 27 in the BOLCB

Ezekiel 27 in the BOLCB2

Ezekiel 27 in the BOMCV

Ezekiel 27 in the BONAV

Ezekiel 27 in the BONCB

Ezekiel 27 in the BONLT

Ezekiel 27 in the BONUT2

Ezekiel 27 in the BOPLNT

Ezekiel 27 in the BOSCB

Ezekiel 27 in the BOSNC

Ezekiel 27 in the BOTLNT

Ezekiel 27 in the BOVCB

Ezekiel 27 in the BPBB

Ezekiel 27 in the BPH

Ezekiel 27 in the BSB

Ezekiel 27 in the CCB

Ezekiel 27 in the CUV

Ezekiel 27 in the CUVS

Ezekiel 27 in the DBT

Ezekiel 27 in the DGDNT

Ezekiel 27 in the DHNT

Ezekiel 27 in the DNT

Ezekiel 27 in the ELBE

Ezekiel 27 in the EMTV

Ezekiel 27 in the ESV

Ezekiel 27 in the FBV

Ezekiel 27 in the FEB

Ezekiel 27 in the GGMNT

Ezekiel 27 in the GNT

Ezekiel 27 in the HARY

Ezekiel 27 in the HNT

Ezekiel 27 in the IRVA

Ezekiel 27 in the IRVB

Ezekiel 27 in the IRVG

Ezekiel 27 in the IRVH

Ezekiel 27 in the IRVK

Ezekiel 27 in the IRVM

Ezekiel 27 in the IRVM2

Ezekiel 27 in the IRVO

Ezekiel 27 in the IRVP

Ezekiel 27 in the IRVT

Ezekiel 27 in the IRVT2

Ezekiel 27 in the IRVU

Ezekiel 27 in the ISVN

Ezekiel 27 in the JSNT

Ezekiel 27 in the KAPI

Ezekiel 27 in the KBT1ETNIK

Ezekiel 27 in the KBV

Ezekiel 27 in the KJV

Ezekiel 27 in the KNFD

Ezekiel 27 in the LBA

Ezekiel 27 in the LBLA

Ezekiel 27 in the LNT

Ezekiel 27 in the LSV

Ezekiel 27 in the MAAL

Ezekiel 27 in the MBV

Ezekiel 27 in the MBV2

Ezekiel 27 in the MHNT

Ezekiel 27 in the MKNFD

Ezekiel 27 in the MNG

Ezekiel 27 in the MNT

Ezekiel 27 in the MNT2

Ezekiel 27 in the MRS1T

Ezekiel 27 in the NAA

Ezekiel 27 in the NASB

Ezekiel 27 in the NBLA

Ezekiel 27 in the NBS

Ezekiel 27 in the NBVTP

Ezekiel 27 in the NET2

Ezekiel 27 in the NIV11

Ezekiel 27 in the NNT

Ezekiel 27 in the NNT2

Ezekiel 27 in the NNT3

Ezekiel 27 in the PDDPT

Ezekiel 27 in the PFNT

Ezekiel 27 in the RMNT

Ezekiel 27 in the SBIAS

Ezekiel 27 in the SBIBS

Ezekiel 27 in the SBIBS2

Ezekiel 27 in the SBICS

Ezekiel 27 in the SBIDS

Ezekiel 27 in the SBIGS

Ezekiel 27 in the SBIHS

Ezekiel 27 in the SBIIS

Ezekiel 27 in the SBIIS2

Ezekiel 27 in the SBIIS3

Ezekiel 27 in the SBIKS

Ezekiel 27 in the SBIKS2

Ezekiel 27 in the SBIMS

Ezekiel 27 in the SBIOS

Ezekiel 27 in the SBIPS

Ezekiel 27 in the SBISS

Ezekiel 27 in the SBITS

Ezekiel 27 in the SBITS2

Ezekiel 27 in the SBITS3

Ezekiel 27 in the SBITS4

Ezekiel 27 in the SBIUS

Ezekiel 27 in the SBIVS

Ezekiel 27 in the SBT

Ezekiel 27 in the SBT1E

Ezekiel 27 in the SCHL

Ezekiel 27 in the SNT

Ezekiel 27 in the SUSU

Ezekiel 27 in the SUSU2

Ezekiel 27 in the SYNO

Ezekiel 27 in the TBIAOTANT

Ezekiel 27 in the TBT1E

Ezekiel 27 in the TBT1E2

Ezekiel 27 in the TFTIP

Ezekiel 27 in the TFTU

Ezekiel 27 in the TGNTATF3T

Ezekiel 27 in the THAI

Ezekiel 27 in the TNFD

Ezekiel 27 in the TNT

Ezekiel 27 in the TNTIK

Ezekiel 27 in the TNTIL

Ezekiel 27 in the TNTIN

Ezekiel 27 in the TNTIP

Ezekiel 27 in the TNTIZ

Ezekiel 27 in the TOMA

Ezekiel 27 in the TTENT

Ezekiel 27 in the UBG

Ezekiel 27 in the UGV

Ezekiel 27 in the UGV2

Ezekiel 27 in the UGV3

Ezekiel 27 in the VBL

Ezekiel 27 in the VDCC

Ezekiel 27 in the YALU

Ezekiel 27 in the YAPE

Ezekiel 27 in the YBVTP

Ezekiel 27 in the ZBP