Ezekiel 7 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá: 2 “Ọmọ ènìyàn, báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí sí ilé Israẹli:“ ‘Òpin! Òpin ti désí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà! 3 Òpin tí dé sí ọ báyìí,èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ,èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ,èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ. 4 Ojú mi kò ní i dá ọ sì,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú;ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹàti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ.Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.’ 5 “Èyí ni OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo.Kíyèsi, ó bọ̀ ní orí rẹ! 6 Òpin ti dé!Òpin ti dé!Ó ti dìde lòdì sí ọ.Kíyèsi, ó ti dé! 7 Ìparun ti dé sórí rẹ,ìwọ tó ń gbé ní ilẹ̀ náà.Àkókò náà dé! Ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé!Kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè. 8 Mo ṣetán láti tú ìbínú gbígbóná mi lé ọ lóríàti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ,èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹàti gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra rẹ ni èmi yóò sì san án fún ọ. 9 Ojú mi kò ní i dá ọ sí,Èmi kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú;èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹàti fún gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrín rẹ. “ ‘Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé Èmi OLÚWA lo kọlù yín. 10 “ ‘Ọjọ́ náà dé!Kíyèsi ó ti dé!Ìparun ti bú jáde,ọ̀pá ti tanná,ìgbéraga ti rúdí! 11 Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú;ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà.Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù,tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn,kò sí nínú ọrọ̀ wọn,kò sí ohun tí ó ní iye. 12 Àkókò náà dé!Ọjọ́ náà ti dé!Kí òǹrajà má ṣe yọ̀,bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀;nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn. 13 Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padàdúkìá èyí tó tàníwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè.Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìíkò ní yí padà.Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọntí yóò gba ara rẹ̀ là. 14 “ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun,tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀,ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun,nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn. 15 Idà wà ní ìta,àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé,idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè,àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú. 16 Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà,wọn yóò sì wà lórí òkè.Bí i àdàbà inú àfonífojì,gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀,olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀. 17 Gbogbo ọwọ́ yóò rọ,gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi. 18 Wọn yóò wọ aṣọ ọ̀fọ̀,ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,ìtìjú yóò mù wọn,wọn yóò sì fá irun wọn. 19 “ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó,wúrà wọn yóò sì dàbí èérífàdákà àti wúrà wọnkò ní le gbà wọ́nní ọjọ́ ìbínú gbígbóná OLÚWA.Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùntàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹnítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn. 20 Wọ́n ń ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí ó lẹ́wà,wọn sì ti fi ṣe òrìṣà,wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀.Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí di aláìmọ́ fún wọn. 21 Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjìàti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé,wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́. 22 Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn,àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́;àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀,wọn yóò sì bà á jẹ́. 23 “ ‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin!Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀,ìlú náà sí kún fún ìwà ipá. 24 Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọláti jogún ilé wọn.Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára,ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́. 25 Nígbà tí ìpayà bá dé,wọn yóò wá àlàáfíà, lórí asán. 26 Wàhálà lórí wàhálà yóò dé,ìdágìrì lórí ìdágìrì.Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì,ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà,bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà. 27 Ọba yóò ṣọ̀fọ̀,ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí,ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì.Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn,èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn.Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní OLÚWA.’ ”
In Other Versions
Ezekiel 7 in the ANGEFD
Ezekiel 7 in the ANTPNG2D
Ezekiel 7 in the AS21
Ezekiel 7 in the BAGH
Ezekiel 7 in the BBPNG
Ezekiel 7 in the BBT1E
Ezekiel 7 in the BDS
Ezekiel 7 in the BEV
Ezekiel 7 in the BHAD
Ezekiel 7 in the BIB
Ezekiel 7 in the BLPT
Ezekiel 7 in the BNT
Ezekiel 7 in the BNTABOOT
Ezekiel 7 in the BNTLV
Ezekiel 7 in the BOATCB
Ezekiel 7 in the BOATCB2
Ezekiel 7 in the BOBCV
Ezekiel 7 in the BOCNT
Ezekiel 7 in the BOECS
Ezekiel 7 in the BOGWICC
Ezekiel 7 in the BOHCB
Ezekiel 7 in the BOHCV
Ezekiel 7 in the BOHLNT
Ezekiel 7 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 7 in the BOICB
Ezekiel 7 in the BOILNTAP
Ezekiel 7 in the BOITCV
Ezekiel 7 in the BOKCV
Ezekiel 7 in the BOKCV2
Ezekiel 7 in the BOKHWOG
Ezekiel 7 in the BOKSSV
Ezekiel 7 in the BOLCB
Ezekiel 7 in the BOLCB2
Ezekiel 7 in the BOMCV
Ezekiel 7 in the BONAV
Ezekiel 7 in the BONCB
Ezekiel 7 in the BONLT
Ezekiel 7 in the BONUT2
Ezekiel 7 in the BOPLNT
Ezekiel 7 in the BOSCB
Ezekiel 7 in the BOSNC
Ezekiel 7 in the BOTLNT
Ezekiel 7 in the BOVCB
Ezekiel 7 in the BPBB
Ezekiel 7 in the BPH
Ezekiel 7 in the BSB
Ezekiel 7 in the CCB
Ezekiel 7 in the CUV
Ezekiel 7 in the CUVS
Ezekiel 7 in the DBT
Ezekiel 7 in the DGDNT
Ezekiel 7 in the DHNT
Ezekiel 7 in the DNT
Ezekiel 7 in the ELBE
Ezekiel 7 in the EMTV
Ezekiel 7 in the ESV
Ezekiel 7 in the FBV
Ezekiel 7 in the FEB
Ezekiel 7 in the GGMNT
Ezekiel 7 in the GNT
Ezekiel 7 in the HARY
Ezekiel 7 in the HNT
Ezekiel 7 in the IRVA
Ezekiel 7 in the IRVB
Ezekiel 7 in the IRVG
Ezekiel 7 in the IRVH
Ezekiel 7 in the IRVK
Ezekiel 7 in the IRVM
Ezekiel 7 in the IRVM2
Ezekiel 7 in the IRVO
Ezekiel 7 in the IRVP
Ezekiel 7 in the IRVT
Ezekiel 7 in the IRVT2
Ezekiel 7 in the IRVU
Ezekiel 7 in the ISVN
Ezekiel 7 in the JSNT
Ezekiel 7 in the KAPI
Ezekiel 7 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 7 in the KBV
Ezekiel 7 in the KJV
Ezekiel 7 in the KNFD
Ezekiel 7 in the LBA
Ezekiel 7 in the LBLA
Ezekiel 7 in the LNT
Ezekiel 7 in the LSV
Ezekiel 7 in the MAAL
Ezekiel 7 in the MBV
Ezekiel 7 in the MBV2
Ezekiel 7 in the MHNT
Ezekiel 7 in the MKNFD
Ezekiel 7 in the MNG
Ezekiel 7 in the MNT
Ezekiel 7 in the MNT2
Ezekiel 7 in the MRS1T
Ezekiel 7 in the NAA
Ezekiel 7 in the NASB
Ezekiel 7 in the NBLA
Ezekiel 7 in the NBS
Ezekiel 7 in the NBVTP
Ezekiel 7 in the NET2
Ezekiel 7 in the NIV11
Ezekiel 7 in the NNT
Ezekiel 7 in the NNT2
Ezekiel 7 in the NNT3
Ezekiel 7 in the PDDPT
Ezekiel 7 in the PFNT
Ezekiel 7 in the RMNT
Ezekiel 7 in the SBIAS
Ezekiel 7 in the SBIBS
Ezekiel 7 in the SBIBS2
Ezekiel 7 in the SBICS
Ezekiel 7 in the SBIDS
Ezekiel 7 in the SBIGS
Ezekiel 7 in the SBIHS
Ezekiel 7 in the SBIIS
Ezekiel 7 in the SBIIS2
Ezekiel 7 in the SBIIS3
Ezekiel 7 in the SBIKS
Ezekiel 7 in the SBIKS2
Ezekiel 7 in the SBIMS
Ezekiel 7 in the SBIOS
Ezekiel 7 in the SBIPS
Ezekiel 7 in the SBISS
Ezekiel 7 in the SBITS
Ezekiel 7 in the SBITS2
Ezekiel 7 in the SBITS3
Ezekiel 7 in the SBITS4
Ezekiel 7 in the SBIUS
Ezekiel 7 in the SBIVS
Ezekiel 7 in the SBT
Ezekiel 7 in the SBT1E
Ezekiel 7 in the SCHL
Ezekiel 7 in the SNT
Ezekiel 7 in the SUSU
Ezekiel 7 in the SUSU2
Ezekiel 7 in the SYNO
Ezekiel 7 in the TBIAOTANT
Ezekiel 7 in the TBT1E
Ezekiel 7 in the TBT1E2
Ezekiel 7 in the TFTIP
Ezekiel 7 in the TFTU
Ezekiel 7 in the TGNTATF3T
Ezekiel 7 in the THAI
Ezekiel 7 in the TNFD
Ezekiel 7 in the TNT
Ezekiel 7 in the TNTIK
Ezekiel 7 in the TNTIL
Ezekiel 7 in the TNTIN
Ezekiel 7 in the TNTIP
Ezekiel 7 in the TNTIZ
Ezekiel 7 in the TOMA
Ezekiel 7 in the TTENT
Ezekiel 7 in the UBG
Ezekiel 7 in the UGV
Ezekiel 7 in the UGV2
Ezekiel 7 in the UGV3
Ezekiel 7 in the VBL
Ezekiel 7 in the VDCC
Ezekiel 7 in the YALU
Ezekiel 7 in the YAPE
Ezekiel 7 in the YBVTP
Ezekiel 7 in the ZBP