Isaiah 23 (BOYCB)

1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire.Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi!Nítorí a ti pa Tire runláìsí ilé tàbí èbúté.Láti ilẹ̀ Saipurọsi niọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn. 2 Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣùàti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni,ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀. 3 Láti orí àwọn omi ńláni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá;ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire,òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè. 4 Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọàní ìwọ ilé ààbò ti Òkun,nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀.“Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ ríÈmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrintàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.” 5 Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti,wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípaìròyìn láti Tire. 6 Kọjá wá sí Tarṣiṣi;pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù. 7 Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,ògbólógbòó ìlú náà,èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọláti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré. 8 Ta ló gbèrò èyí sí Tire,ìlú aládé,àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládétí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míkání orílẹ̀ ayé? 9 OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ baàti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́láilé ayé sílẹ̀. 10 Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti,ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi,nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́. 11 OLÚWA ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkunó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaanipé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run. 12 Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́,ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí! “Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi,níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.” 13 Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí.Àwọn Asiria ti sọ ọ́ diibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhòwọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn. 14 Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;wọ́n ti pa odi rẹ̀ run! 15 Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè: 16 “Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú,ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin,kí a lè ba à rántí rẹ.” 17 Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, OLÚWA yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé. 18 Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún OLÚWA; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú OLÚWA, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.

In Other Versions

Isaiah 23 in the ANGEFD

Isaiah 23 in the ANTPNG2D

Isaiah 23 in the AS21

Isaiah 23 in the BAGH

Isaiah 23 in the BBPNG

Isaiah 23 in the BBT1E

Isaiah 23 in the BDS

Isaiah 23 in the BEV

Isaiah 23 in the BHAD

Isaiah 23 in the BIB

Isaiah 23 in the BLPT

Isaiah 23 in the BNT

Isaiah 23 in the BNTABOOT

Isaiah 23 in the BNTLV

Isaiah 23 in the BOATCB

Isaiah 23 in the BOATCB2

Isaiah 23 in the BOBCV

Isaiah 23 in the BOCNT

Isaiah 23 in the BOECS

Isaiah 23 in the BOGWICC

Isaiah 23 in the BOHCB

Isaiah 23 in the BOHCV

Isaiah 23 in the BOHLNT

Isaiah 23 in the BOHNTLTAL

Isaiah 23 in the BOICB

Isaiah 23 in the BOILNTAP

Isaiah 23 in the BOITCV

Isaiah 23 in the BOKCV

Isaiah 23 in the BOKCV2

Isaiah 23 in the BOKHWOG

Isaiah 23 in the BOKSSV

Isaiah 23 in the BOLCB

Isaiah 23 in the BOLCB2

Isaiah 23 in the BOMCV

Isaiah 23 in the BONAV

Isaiah 23 in the BONCB

Isaiah 23 in the BONLT

Isaiah 23 in the BONUT2

Isaiah 23 in the BOPLNT

Isaiah 23 in the BOSCB

Isaiah 23 in the BOSNC

Isaiah 23 in the BOTLNT

Isaiah 23 in the BOVCB

Isaiah 23 in the BPBB

Isaiah 23 in the BPH

Isaiah 23 in the BSB

Isaiah 23 in the CCB

Isaiah 23 in the CUV

Isaiah 23 in the CUVS

Isaiah 23 in the DBT

Isaiah 23 in the DGDNT

Isaiah 23 in the DHNT

Isaiah 23 in the DNT

Isaiah 23 in the ELBE

Isaiah 23 in the EMTV

Isaiah 23 in the ESV

Isaiah 23 in the FBV

Isaiah 23 in the FEB

Isaiah 23 in the GGMNT

Isaiah 23 in the GNT

Isaiah 23 in the HARY

Isaiah 23 in the HNT

Isaiah 23 in the IRVA

Isaiah 23 in the IRVB

Isaiah 23 in the IRVG

Isaiah 23 in the IRVH

Isaiah 23 in the IRVK

Isaiah 23 in the IRVM

Isaiah 23 in the IRVM2

Isaiah 23 in the IRVO

Isaiah 23 in the IRVP

Isaiah 23 in the IRVT

Isaiah 23 in the IRVT2

Isaiah 23 in the IRVU

Isaiah 23 in the ISVN

Isaiah 23 in the JSNT

Isaiah 23 in the KAPI

Isaiah 23 in the KBT1ETNIK

Isaiah 23 in the KBV

Isaiah 23 in the KJV

Isaiah 23 in the KNFD

Isaiah 23 in the LBA

Isaiah 23 in the LBLA

Isaiah 23 in the LNT

Isaiah 23 in the LSV

Isaiah 23 in the MAAL

Isaiah 23 in the MBV

Isaiah 23 in the MBV2

Isaiah 23 in the MHNT

Isaiah 23 in the MKNFD

Isaiah 23 in the MNG

Isaiah 23 in the MNT

Isaiah 23 in the MNT2

Isaiah 23 in the MRS1T

Isaiah 23 in the NAA

Isaiah 23 in the NASB

Isaiah 23 in the NBLA

Isaiah 23 in the NBS

Isaiah 23 in the NBVTP

Isaiah 23 in the NET2

Isaiah 23 in the NIV11

Isaiah 23 in the NNT

Isaiah 23 in the NNT2

Isaiah 23 in the NNT3

Isaiah 23 in the PDDPT

Isaiah 23 in the PFNT

Isaiah 23 in the RMNT

Isaiah 23 in the SBIAS

Isaiah 23 in the SBIBS

Isaiah 23 in the SBIBS2

Isaiah 23 in the SBICS

Isaiah 23 in the SBIDS

Isaiah 23 in the SBIGS

Isaiah 23 in the SBIHS

Isaiah 23 in the SBIIS

Isaiah 23 in the SBIIS2

Isaiah 23 in the SBIIS3

Isaiah 23 in the SBIKS

Isaiah 23 in the SBIKS2

Isaiah 23 in the SBIMS

Isaiah 23 in the SBIOS

Isaiah 23 in the SBIPS

Isaiah 23 in the SBISS

Isaiah 23 in the SBITS

Isaiah 23 in the SBITS2

Isaiah 23 in the SBITS3

Isaiah 23 in the SBITS4

Isaiah 23 in the SBIUS

Isaiah 23 in the SBIVS

Isaiah 23 in the SBT

Isaiah 23 in the SBT1E

Isaiah 23 in the SCHL

Isaiah 23 in the SNT

Isaiah 23 in the SUSU

Isaiah 23 in the SUSU2

Isaiah 23 in the SYNO

Isaiah 23 in the TBIAOTANT

Isaiah 23 in the TBT1E

Isaiah 23 in the TBT1E2

Isaiah 23 in the TFTIP

Isaiah 23 in the TFTU

Isaiah 23 in the TGNTATF3T

Isaiah 23 in the THAI

Isaiah 23 in the TNFD

Isaiah 23 in the TNT

Isaiah 23 in the TNTIK

Isaiah 23 in the TNTIL

Isaiah 23 in the TNTIN

Isaiah 23 in the TNTIP

Isaiah 23 in the TNTIZ

Isaiah 23 in the TOMA

Isaiah 23 in the TTENT

Isaiah 23 in the UBG

Isaiah 23 in the UGV

Isaiah 23 in the UGV2

Isaiah 23 in the UGV3

Isaiah 23 in the VBL

Isaiah 23 in the VDCC

Isaiah 23 in the YALU

Isaiah 23 in the YAPE

Isaiah 23 in the YBVTP

Isaiah 23 in the ZBP