Isaiah 63 (BOYCB)
1 Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá,ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá?Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀,tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀? “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodotí ó ní ipa láti gbàlà.” 2 Èéṣe tí aṣọ yín fi pupagẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí? 3 “Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì;láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi.Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mimo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú miẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi,mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi. 4 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn miàti pé ọdún ìràpadà mi ti dé. 5 Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún miàti ìrunú mi ni ó gbé mi ró. 6 Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mumo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.” 7 Èmi yóò sọ nípa àánú OLÚWA,ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún,gẹ́gẹ́ bí ohun tí OLÚWA ti ṣe fún wa,bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbotí ó ti ṣe fún ilé Israẹli,gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀. 8 Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n,àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”;bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn. 9 Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là.Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà;ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́nní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì. 10 Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́.Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọnòun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà. 11 Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì,àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já,pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?Níbo ni ẹni náà wà tí ó ránẸ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn, 12 ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀láti wà ní apá ọ̀tún Mose,ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn,láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀, 13 ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já?Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀; 14 gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko,a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí OLÚWA.Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yínláti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo. 15 Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí iláti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà?Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni ati mú kúrò níwájú wa. 16 Ṣùgbọ́n ìwọ ni baba wa,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abrahamu kò mọ̀ wátàbí Israẹli mọ ẹni tí à á ṣe;ìwọ, OLÚWA ni Baba wa,Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ. 17 Èéṣe OLÚWA tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹtí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ?Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,àwọn ẹ̀yà tí ṣe ogún ìní rẹ. 18 Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ fi gba ibi mímọ́ rẹ,ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀. 19 Àwa jẹ́ tìrẹ láti ìgbà n nì;ṣùgbọ́n ìwọ kò tí ì jẹ ọba lé wọn lórí,a kò sì tí ì pè wọ́n mọ́ orúkọ rẹ.
In Other Versions
Isaiah 63 in the ANGEFD
Isaiah 63 in the ANTPNG2D
Isaiah 63 in the AS21
Isaiah 63 in the BAGH
Isaiah 63 in the BBPNG
Isaiah 63 in the BBT1E
Isaiah 63 in the BDS
Isaiah 63 in the BEV
Isaiah 63 in the BHAD
Isaiah 63 in the BIB
Isaiah 63 in the BLPT
Isaiah 63 in the BNT
Isaiah 63 in the BNTABOOT
Isaiah 63 in the BNTLV
Isaiah 63 in the BOATCB
Isaiah 63 in the BOATCB2
Isaiah 63 in the BOBCV
Isaiah 63 in the BOCNT
Isaiah 63 in the BOECS
Isaiah 63 in the BOGWICC
Isaiah 63 in the BOHCB
Isaiah 63 in the BOHCV
Isaiah 63 in the BOHLNT
Isaiah 63 in the BOHNTLTAL
Isaiah 63 in the BOICB
Isaiah 63 in the BOILNTAP
Isaiah 63 in the BOITCV
Isaiah 63 in the BOKCV
Isaiah 63 in the BOKCV2
Isaiah 63 in the BOKHWOG
Isaiah 63 in the BOKSSV
Isaiah 63 in the BOLCB
Isaiah 63 in the BOLCB2
Isaiah 63 in the BOMCV
Isaiah 63 in the BONAV
Isaiah 63 in the BONCB
Isaiah 63 in the BONLT
Isaiah 63 in the BONUT2
Isaiah 63 in the BOPLNT
Isaiah 63 in the BOSCB
Isaiah 63 in the BOSNC
Isaiah 63 in the BOTLNT
Isaiah 63 in the BOVCB
Isaiah 63 in the BPBB
Isaiah 63 in the BPH
Isaiah 63 in the BSB
Isaiah 63 in the CCB
Isaiah 63 in the CUV
Isaiah 63 in the CUVS
Isaiah 63 in the DBT
Isaiah 63 in the DGDNT
Isaiah 63 in the DHNT
Isaiah 63 in the DNT
Isaiah 63 in the ELBE
Isaiah 63 in the EMTV
Isaiah 63 in the ESV
Isaiah 63 in the FBV
Isaiah 63 in the FEB
Isaiah 63 in the GGMNT
Isaiah 63 in the GNT
Isaiah 63 in the HARY
Isaiah 63 in the HNT
Isaiah 63 in the IRVA
Isaiah 63 in the IRVB
Isaiah 63 in the IRVG
Isaiah 63 in the IRVH
Isaiah 63 in the IRVK
Isaiah 63 in the IRVM
Isaiah 63 in the IRVM2
Isaiah 63 in the IRVO
Isaiah 63 in the IRVP
Isaiah 63 in the IRVT
Isaiah 63 in the IRVT2
Isaiah 63 in the IRVU
Isaiah 63 in the ISVN
Isaiah 63 in the JSNT
Isaiah 63 in the KAPI
Isaiah 63 in the KBT1ETNIK
Isaiah 63 in the KBV
Isaiah 63 in the KJV
Isaiah 63 in the KNFD
Isaiah 63 in the LBA
Isaiah 63 in the LBLA
Isaiah 63 in the LNT
Isaiah 63 in the LSV
Isaiah 63 in the MAAL
Isaiah 63 in the MBV
Isaiah 63 in the MBV2
Isaiah 63 in the MHNT
Isaiah 63 in the MKNFD
Isaiah 63 in the MNG
Isaiah 63 in the MNT
Isaiah 63 in the MNT2
Isaiah 63 in the MRS1T
Isaiah 63 in the NAA
Isaiah 63 in the NASB
Isaiah 63 in the NBLA
Isaiah 63 in the NBS
Isaiah 63 in the NBVTP
Isaiah 63 in the NET2
Isaiah 63 in the NIV11
Isaiah 63 in the NNT
Isaiah 63 in the NNT2
Isaiah 63 in the NNT3
Isaiah 63 in the PDDPT
Isaiah 63 in the PFNT
Isaiah 63 in the RMNT
Isaiah 63 in the SBIAS
Isaiah 63 in the SBIBS
Isaiah 63 in the SBIBS2
Isaiah 63 in the SBICS
Isaiah 63 in the SBIDS
Isaiah 63 in the SBIGS
Isaiah 63 in the SBIHS
Isaiah 63 in the SBIIS
Isaiah 63 in the SBIIS2
Isaiah 63 in the SBIIS3
Isaiah 63 in the SBIKS
Isaiah 63 in the SBIKS2
Isaiah 63 in the SBIMS
Isaiah 63 in the SBIOS
Isaiah 63 in the SBIPS
Isaiah 63 in the SBISS
Isaiah 63 in the SBITS
Isaiah 63 in the SBITS2
Isaiah 63 in the SBITS3
Isaiah 63 in the SBITS4
Isaiah 63 in the SBIUS
Isaiah 63 in the SBIVS
Isaiah 63 in the SBT
Isaiah 63 in the SBT1E
Isaiah 63 in the SCHL
Isaiah 63 in the SNT
Isaiah 63 in the SUSU
Isaiah 63 in the SUSU2
Isaiah 63 in the SYNO
Isaiah 63 in the TBIAOTANT
Isaiah 63 in the TBT1E
Isaiah 63 in the TBT1E2
Isaiah 63 in the TFTIP
Isaiah 63 in the TFTU
Isaiah 63 in the TGNTATF3T
Isaiah 63 in the THAI
Isaiah 63 in the TNFD
Isaiah 63 in the TNT
Isaiah 63 in the TNTIK
Isaiah 63 in the TNTIL
Isaiah 63 in the TNTIN
Isaiah 63 in the TNTIP
Isaiah 63 in the TNTIZ
Isaiah 63 in the TOMA
Isaiah 63 in the TTENT
Isaiah 63 in the UBG
Isaiah 63 in the UGV
Isaiah 63 in the UGV2
Isaiah 63 in the UGV3
Isaiah 63 in the VBL
Isaiah 63 in the VDCC
Isaiah 63 in the YALU
Isaiah 63 in the YAPE
Isaiah 63 in the YBVTP
Isaiah 63 in the ZBP