Jeremiah 10 (BOYCB)
1 Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLÚWA sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli. 2 Báyìí ni OLÚWA wí:“Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí,kí àmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín,nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè. 3 Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn,wọ́n gé igi láti inú igbó,oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀. 4 Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.Wọ́n fi òòlù kàn án àti ìṣókí ó má ba à ṣubú. 5 Wọ́n wé mọ́ igi bí ẹ̀gúnsí inú oko,òrìṣà wọn kò le è fọhùn.Wọ́n gbọdọ̀ máa gbéwọn nítorí pé wọn kò lè rìn.Má ṣe bẹ̀rù wọn;wọn kò le è ṣe ibi kankanbẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.” 6 Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ OLÚWA;o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára. 7 Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ?Ọba àwọn orílẹ̀-èdè?Nítorí tìrẹ ni.Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdèàti gbogbo ìjọba wọn,kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ. 8 Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè,wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí. 9 Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi,àti wúrà láti Upasi.Èyí tí àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́nkùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò,èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà. 10 Ṣùgbọ́n OLÚWA ni Ọlọ́run tòótọ́,òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé.Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀. 11 “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ” 12 Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀. 13 Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo;ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé.Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀. 14 Gbogbo ènìyàn jẹ́ aṣiwèrè àti aláìnímọ̀,ojú ti gbogbo alágbẹ̀dẹ níwájú ère rẹ̀,nítorí ère dídá rẹ̀ èké ni,kò sì ṣí ẹ̀mí nínú rẹ̀. 15 Asán ni wọ́n, iṣẹ́ ìṣìnà;nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn yóò ṣègbé. 16 Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí,nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogboàti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀. OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 17 Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì. 18 Nítorí èyí ni OLÚWA wí:“Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọnàwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde.Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn,kí wọn kí ó lè rí wọn mú.” 19 Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi!Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn,bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi,“Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.” 20 Àgọ́ mi bàjẹ́,gbogbo okùn rẹ̀ sì já.Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́,kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́,tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi. 21 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè,wọn kò sì wá OLÚWA:nítorí náà wọn kì yóò ṣe rereàti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká. 22 Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀,àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá!Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro,àti ihò ọ̀wàwà. 23 Èmi mọ̀ OLÚWA wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀,kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀. 24 Tún mi ṣe OLÚWA, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkankí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ,kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo. 25 Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdètí kò mọ̀ ọ́n,sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ.Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run,wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá,wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.
In Other Versions
Jeremiah 10 in the ANGEFD
Jeremiah 10 in the ANTPNG2D
Jeremiah 10 in the AS21
Jeremiah 10 in the BAGH
Jeremiah 10 in the BBPNG
Jeremiah 10 in the BBT1E
Jeremiah 10 in the BDS
Jeremiah 10 in the BEV
Jeremiah 10 in the BHAD
Jeremiah 10 in the BIB
Jeremiah 10 in the BLPT
Jeremiah 10 in the BNT
Jeremiah 10 in the BNTABOOT
Jeremiah 10 in the BNTLV
Jeremiah 10 in the BOATCB
Jeremiah 10 in the BOATCB2
Jeremiah 10 in the BOBCV
Jeremiah 10 in the BOCNT
Jeremiah 10 in the BOECS
Jeremiah 10 in the BOGWICC
Jeremiah 10 in the BOHCB
Jeremiah 10 in the BOHCV
Jeremiah 10 in the BOHLNT
Jeremiah 10 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 10 in the BOICB
Jeremiah 10 in the BOILNTAP
Jeremiah 10 in the BOITCV
Jeremiah 10 in the BOKCV
Jeremiah 10 in the BOKCV2
Jeremiah 10 in the BOKHWOG
Jeremiah 10 in the BOKSSV
Jeremiah 10 in the BOLCB
Jeremiah 10 in the BOLCB2
Jeremiah 10 in the BOMCV
Jeremiah 10 in the BONAV
Jeremiah 10 in the BONCB
Jeremiah 10 in the BONLT
Jeremiah 10 in the BONUT2
Jeremiah 10 in the BOPLNT
Jeremiah 10 in the BOSCB
Jeremiah 10 in the BOSNC
Jeremiah 10 in the BOTLNT
Jeremiah 10 in the BOVCB
Jeremiah 10 in the BPBB
Jeremiah 10 in the BPH
Jeremiah 10 in the BSB
Jeremiah 10 in the CCB
Jeremiah 10 in the CUV
Jeremiah 10 in the CUVS
Jeremiah 10 in the DBT
Jeremiah 10 in the DGDNT
Jeremiah 10 in the DHNT
Jeremiah 10 in the DNT
Jeremiah 10 in the ELBE
Jeremiah 10 in the EMTV
Jeremiah 10 in the ESV
Jeremiah 10 in the FBV
Jeremiah 10 in the FEB
Jeremiah 10 in the GGMNT
Jeremiah 10 in the GNT
Jeremiah 10 in the HARY
Jeremiah 10 in the HNT
Jeremiah 10 in the IRVA
Jeremiah 10 in the IRVB
Jeremiah 10 in the IRVG
Jeremiah 10 in the IRVH
Jeremiah 10 in the IRVK
Jeremiah 10 in the IRVM
Jeremiah 10 in the IRVM2
Jeremiah 10 in the IRVO
Jeremiah 10 in the IRVP
Jeremiah 10 in the IRVT
Jeremiah 10 in the IRVT2
Jeremiah 10 in the IRVU
Jeremiah 10 in the ISVN
Jeremiah 10 in the JSNT
Jeremiah 10 in the KAPI
Jeremiah 10 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 10 in the KBV
Jeremiah 10 in the KJV
Jeremiah 10 in the KNFD
Jeremiah 10 in the LBA
Jeremiah 10 in the LBLA
Jeremiah 10 in the LNT
Jeremiah 10 in the LSV
Jeremiah 10 in the MAAL
Jeremiah 10 in the MBV
Jeremiah 10 in the MBV2
Jeremiah 10 in the MHNT
Jeremiah 10 in the MKNFD
Jeremiah 10 in the MNG
Jeremiah 10 in the MNT
Jeremiah 10 in the MNT2
Jeremiah 10 in the MRS1T
Jeremiah 10 in the NAA
Jeremiah 10 in the NASB
Jeremiah 10 in the NBLA
Jeremiah 10 in the NBS
Jeremiah 10 in the NBVTP
Jeremiah 10 in the NET2
Jeremiah 10 in the NIV11
Jeremiah 10 in the NNT
Jeremiah 10 in the NNT2
Jeremiah 10 in the NNT3
Jeremiah 10 in the PDDPT
Jeremiah 10 in the PFNT
Jeremiah 10 in the RMNT
Jeremiah 10 in the SBIAS
Jeremiah 10 in the SBIBS
Jeremiah 10 in the SBIBS2
Jeremiah 10 in the SBICS
Jeremiah 10 in the SBIDS
Jeremiah 10 in the SBIGS
Jeremiah 10 in the SBIHS
Jeremiah 10 in the SBIIS
Jeremiah 10 in the SBIIS2
Jeremiah 10 in the SBIIS3
Jeremiah 10 in the SBIKS
Jeremiah 10 in the SBIKS2
Jeremiah 10 in the SBIMS
Jeremiah 10 in the SBIOS
Jeremiah 10 in the SBIPS
Jeremiah 10 in the SBISS
Jeremiah 10 in the SBITS
Jeremiah 10 in the SBITS2
Jeremiah 10 in the SBITS3
Jeremiah 10 in the SBITS4
Jeremiah 10 in the SBIUS
Jeremiah 10 in the SBIVS
Jeremiah 10 in the SBT
Jeremiah 10 in the SBT1E
Jeremiah 10 in the SCHL
Jeremiah 10 in the SNT
Jeremiah 10 in the SUSU
Jeremiah 10 in the SUSU2
Jeremiah 10 in the SYNO
Jeremiah 10 in the TBIAOTANT
Jeremiah 10 in the TBT1E
Jeremiah 10 in the TBT1E2
Jeremiah 10 in the TFTIP
Jeremiah 10 in the TFTU
Jeremiah 10 in the TGNTATF3T
Jeremiah 10 in the THAI
Jeremiah 10 in the TNFD
Jeremiah 10 in the TNT
Jeremiah 10 in the TNTIK
Jeremiah 10 in the TNTIL
Jeremiah 10 in the TNTIN
Jeremiah 10 in the TNTIP
Jeremiah 10 in the TNTIZ
Jeremiah 10 in the TOMA
Jeremiah 10 in the TTENT
Jeremiah 10 in the UBG
Jeremiah 10 in the UGV
Jeremiah 10 in the UGV2
Jeremiah 10 in the UGV3
Jeremiah 10 in the VBL
Jeremiah 10 in the VDCC
Jeremiah 10 in the YALU
Jeremiah 10 in the YAPE
Jeremiah 10 in the YBVTP
Jeremiah 10 in the ZBP