Jeremiah 3 (BOYCB)

1 “Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn,ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá?Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí?Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́,ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?”ni OLÚWA wí. 2 “Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì,kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́?Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́,bí i ará Arabia kan nínú aginjù,ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ. 3 Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn,kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò.Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà,ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú. 4 Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé,‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi. 5 Ìwọ yóò ha máa bínú títí?Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.” 6 Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, OLÚWA wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀. 7 Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Juda aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i. 8 Mo fún Israẹli aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Síbẹ̀ mo rí pé Juda tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè. 9 Nítorí ìwà èérí Israẹli kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi. 10 Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Juda arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olóòtítọ́,” ni OLÚWA wí. 11 OLÚWA wí fún mi pé, “Israẹli aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Juda tí ó ní ìgbàgbọ́ lọ. 12 Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá:“ ‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni OLÚWA wí.‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́,nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni OLÚWA wí.Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé. 13 Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ,ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjìlábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀,ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ”ni OLÚWA wí. 14 “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni OLÚWA wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni. 15 Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀. 16 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni OLÚWA wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí OLÚWA.’ Kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́. 17 Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jerusalẹmu ní ìtẹ́ OLÚWA gbogbo orílẹ̀-èdè yóò péjọ sí Jerusalẹmu láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ OLÚWA, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle búburú wọn mọ́. 18 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní. 19 “Èmi fúnra mi sọ wí pé,“ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó,kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrinkí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn. 20 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi. Ìwọ ilé Israẹli,”ni OLÚWA wí. 21 A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga,ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli,nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po,wọ́n sì ti gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run wọn. 22 “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.” “Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹnítorí ìwọ ni OLÚWA Ọlọ́run wa. 23 Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkèkéékèèké àti àwọn òkè gíga,nítòótọ́, nínú OLÚWA Ọlọ́runwa ni ìgbàlà Israẹli wà. 24 Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú tijẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run,ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn,ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. 25 Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀.A ti ṣẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run wa,àwa àti àwọn baba wa,láti ìgbà èwe wa títí di ònía kò gbọ́rọ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run wa.”

In Other Versions

Jeremiah 3 in the ANGEFD

Jeremiah 3 in the ANTPNG2D

Jeremiah 3 in the AS21

Jeremiah 3 in the BAGH

Jeremiah 3 in the BBPNG

Jeremiah 3 in the BBT1E

Jeremiah 3 in the BDS

Jeremiah 3 in the BEV

Jeremiah 3 in the BHAD

Jeremiah 3 in the BIB

Jeremiah 3 in the BLPT

Jeremiah 3 in the BNT

Jeremiah 3 in the BNTABOOT

Jeremiah 3 in the BNTLV

Jeremiah 3 in the BOATCB

Jeremiah 3 in the BOATCB2

Jeremiah 3 in the BOBCV

Jeremiah 3 in the BOCNT

Jeremiah 3 in the BOECS

Jeremiah 3 in the BOGWICC

Jeremiah 3 in the BOHCB

Jeremiah 3 in the BOHCV

Jeremiah 3 in the BOHLNT

Jeremiah 3 in the BOHNTLTAL

Jeremiah 3 in the BOICB

Jeremiah 3 in the BOILNTAP

Jeremiah 3 in the BOITCV

Jeremiah 3 in the BOKCV

Jeremiah 3 in the BOKCV2

Jeremiah 3 in the BOKHWOG

Jeremiah 3 in the BOKSSV

Jeremiah 3 in the BOLCB

Jeremiah 3 in the BOLCB2

Jeremiah 3 in the BOMCV

Jeremiah 3 in the BONAV

Jeremiah 3 in the BONCB

Jeremiah 3 in the BONLT

Jeremiah 3 in the BONUT2

Jeremiah 3 in the BOPLNT

Jeremiah 3 in the BOSCB

Jeremiah 3 in the BOSNC

Jeremiah 3 in the BOTLNT

Jeremiah 3 in the BOVCB

Jeremiah 3 in the BPBB

Jeremiah 3 in the BPH

Jeremiah 3 in the BSB

Jeremiah 3 in the CCB

Jeremiah 3 in the CUV

Jeremiah 3 in the CUVS

Jeremiah 3 in the DBT

Jeremiah 3 in the DGDNT

Jeremiah 3 in the DHNT

Jeremiah 3 in the DNT

Jeremiah 3 in the ELBE

Jeremiah 3 in the EMTV

Jeremiah 3 in the ESV

Jeremiah 3 in the FBV

Jeremiah 3 in the FEB

Jeremiah 3 in the GGMNT

Jeremiah 3 in the GNT

Jeremiah 3 in the HARY

Jeremiah 3 in the HNT

Jeremiah 3 in the IRVA

Jeremiah 3 in the IRVB

Jeremiah 3 in the IRVG

Jeremiah 3 in the IRVH

Jeremiah 3 in the IRVK

Jeremiah 3 in the IRVM

Jeremiah 3 in the IRVM2

Jeremiah 3 in the IRVO

Jeremiah 3 in the IRVP

Jeremiah 3 in the IRVT

Jeremiah 3 in the IRVT2

Jeremiah 3 in the IRVU

Jeremiah 3 in the ISVN

Jeremiah 3 in the JSNT

Jeremiah 3 in the KAPI

Jeremiah 3 in the KBT1ETNIK

Jeremiah 3 in the KBV

Jeremiah 3 in the KJV

Jeremiah 3 in the KNFD

Jeremiah 3 in the LBA

Jeremiah 3 in the LBLA

Jeremiah 3 in the LNT

Jeremiah 3 in the LSV

Jeremiah 3 in the MAAL

Jeremiah 3 in the MBV

Jeremiah 3 in the MBV2

Jeremiah 3 in the MHNT

Jeremiah 3 in the MKNFD

Jeremiah 3 in the MNG

Jeremiah 3 in the MNT

Jeremiah 3 in the MNT2

Jeremiah 3 in the MRS1T

Jeremiah 3 in the NAA

Jeremiah 3 in the NASB

Jeremiah 3 in the NBLA

Jeremiah 3 in the NBS

Jeremiah 3 in the NBVTP

Jeremiah 3 in the NET2

Jeremiah 3 in the NIV11

Jeremiah 3 in the NNT

Jeremiah 3 in the NNT2

Jeremiah 3 in the NNT3

Jeremiah 3 in the PDDPT

Jeremiah 3 in the PFNT

Jeremiah 3 in the RMNT

Jeremiah 3 in the SBIAS

Jeremiah 3 in the SBIBS

Jeremiah 3 in the SBIBS2

Jeremiah 3 in the SBICS

Jeremiah 3 in the SBIDS

Jeremiah 3 in the SBIGS

Jeremiah 3 in the SBIHS

Jeremiah 3 in the SBIIS

Jeremiah 3 in the SBIIS2

Jeremiah 3 in the SBIIS3

Jeremiah 3 in the SBIKS

Jeremiah 3 in the SBIKS2

Jeremiah 3 in the SBIMS

Jeremiah 3 in the SBIOS

Jeremiah 3 in the SBIPS

Jeremiah 3 in the SBISS

Jeremiah 3 in the SBITS

Jeremiah 3 in the SBITS2

Jeremiah 3 in the SBITS3

Jeremiah 3 in the SBITS4

Jeremiah 3 in the SBIUS

Jeremiah 3 in the SBIVS

Jeremiah 3 in the SBT

Jeremiah 3 in the SBT1E

Jeremiah 3 in the SCHL

Jeremiah 3 in the SNT

Jeremiah 3 in the SUSU

Jeremiah 3 in the SUSU2

Jeremiah 3 in the SYNO

Jeremiah 3 in the TBIAOTANT

Jeremiah 3 in the TBT1E

Jeremiah 3 in the TBT1E2

Jeremiah 3 in the TFTIP

Jeremiah 3 in the TFTU

Jeremiah 3 in the TGNTATF3T

Jeremiah 3 in the THAI

Jeremiah 3 in the TNFD

Jeremiah 3 in the TNT

Jeremiah 3 in the TNTIK

Jeremiah 3 in the TNTIL

Jeremiah 3 in the TNTIN

Jeremiah 3 in the TNTIP

Jeremiah 3 in the TNTIZ

Jeremiah 3 in the TOMA

Jeremiah 3 in the TTENT

Jeremiah 3 in the UBG

Jeremiah 3 in the UGV

Jeremiah 3 in the UGV2

Jeremiah 3 in the UGV3

Jeremiah 3 in the VBL

Jeremiah 3 in the VDCC

Jeremiah 3 in the YALU

Jeremiah 3 in the YAPE

Jeremiah 3 in the YBVTP

Jeremiah 3 in the ZBP