Jeremiah 31 (BOYCB)
1 “Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni OLÚWA wí. 2 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idàyóò rí ojúrere OLÚWA ní aṣálẹ̀,Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.” 3 OLÚWA ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín, 4 Èmi yóò tún gbé e yín sókè,àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli.Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀. 5 Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàràní orí òkè Samaria;àwọn àgbẹ̀ yóò sì máagbádùn èso oko wọn. 6 Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jádelórí òkè Efraimu wí pé,‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni,ní ọ̀dọ̀ OLÚWA Ọlọ́run wa.’ ” 7 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA sọ wí pé:“Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu;ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo.Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,‘OLÚWA, gba àwọn ènìyàn rẹ là;àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’ 8 Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá. 9 Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún,wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà.Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi;ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú,nítorí èmi ni baba Israẹli,Efraimu sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi. 10 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin orílẹ̀-èdèẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn;‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ,yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’ 11 Nítorí OLÚWA ti tú Jakọbu sílẹ̀, o sì rà á padàní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ. 12 Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Sioni;wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore OLÚWA.Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróróọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,ìkorò kò ní bá wọn mọ́. 13 Àwọn wúńdíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin.Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú.Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀. 14 Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀;àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,”ni OLÚWA wí. 15 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“A gbọ́ ohùn kan ní Ramatí ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò.Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀;kò gbà kí wọ́n tu òun nínú,nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.” 16 Báyìí ni OLÚWA wí:“Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkúnàti ojú rẹ nínú omijé;nítorí a ó fi èrè sí iṣẹ́ rẹ,”ni OLÚWA wí.“Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá. 17 Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,”ni OLÚWA wí.“Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn. 18 “Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé,‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́èmi sì ti gbọ́ ìbáwí.Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà,nítorí ìwọ ni OLÚWA Ọlọ́run mi. 19 Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà,mo ronúpìwàdà,lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀,èmi lu àyà mi.Ojú tì mí, mo sì dààmú;nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’ 20 Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradáratí inú mi dùn sí bí?Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó,síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀.Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un,èmi káàánú gidigidi fún un,”ni OLÚWA wí. 21 “Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde,ṣe atọ́nà àmì,kíyèsi òpópó ọ̀nà geereojú ọ̀nà tí ó ń gbà.Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli,padà sí àwọn ìlú rẹ. 22 Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó,ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin; OLÚWA yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀,ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.” 23 Báyìí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Juda àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan sí i; wí pé, ‘Kí OLÚWA kí ó bùkún fún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’ 24 Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Juda àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká. 25 Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.” 26 Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi. 27 “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Israẹli àti ilé Juda pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko. 28 Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni OLÚWA wí. 29 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé:“ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà àìpọ́nàti pé eyín kan àwọn ọmọdé.’ 30 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èso kíkan ni eyín yóò kan. 31 “Ìgbà kan ń bọ̀,” ni OLÚWA wí,“tí Èmi yóò bá ilé Israẹliàti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun. 32 Kò ní dàbí májẹ̀mútí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́,tí mo mú wọn jáde ní Ejibitinítorí wọ́n da májẹ̀mú mi.Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,”ni OLÚWA wí. 33 “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dálẹ́yìn ìgbà náà,” ni OLÚWA wí pé:“Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn,èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn.Èmi ó jẹ́ OLÚWA wọn;àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi. 34 Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ OLÚWA,’nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ míláti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,”ni OLÚWA wí.“Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì,èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” 35 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:ẹni tí ó mú oòrùntan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ràn ní òru;tí ó rú omi Òkun sókètó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 36 “Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,”ni OLÚWA wí.“Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kunláti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.” 37 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókètí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀,ni èmi yóò kọ àwọn Israẹlinítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,”ni OLÚWA wí. 38 “Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé igun ẹnu ibodè. 39 Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Garebu yóò sì lọ sí Goa. 40 Gbogbo àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo àfonífojì Kidironi ní ìhà ìlà-oòrùn títí dé igun ẹnu ibodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí OLÚWA. A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀.”