Jeremiah 8 (BOYCB)
1 “ ‘Ní ìgbà náà ni OLÚWA wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda àti egungun àwọn ìjòyè, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerusalẹmu kúrò nínú ibojì. 2 A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀. 3 Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.’ 4 “Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀, wọn kì í padà dìde bí?Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí? 5 Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀?Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn;wọ́n kọ̀ láti yípadà. 6 Mo ti fetísílẹ̀ dáradára,wọn kò sọ ohun tí ó tọ́.Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?”Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun. 7 Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀runmọ ìgbà tirẹ̀,àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèémọ àkókò ìṣípò padà wọn.Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọohun tí OLÚWA wọn fẹ́. 8 “ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,nítorí a ní òfin OLÚWA,”nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wéti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn. 9 Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n,a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLÚWA,irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní? 10 Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìírànàti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn.Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù,gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún;àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáàpẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn. 11 Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn migẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀.“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,nígbà tí kò sí àlàáfíà. 12 Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn?Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá;wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú.Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò,ni OLÚWA wí. 13 “ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò,ni OLÚWA wí.Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà.Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi,ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.Ohun tí mo ti fi fún wọnni à ó gbà kúrò.’ ” 14 “Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí?A kó ara wa jọ!Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódikí a sì ṣègbé síbẹ̀.Nítorí tí OLÚWA Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé.Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu,nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i. 15 Àwa ń retí àlàáfíàkò sí ìre kan,tí ó wá ní ìgbà ìmúláradábí kò ṣe ìpayà nìkan. 16 Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀là ń gbọ́ láti Dani,yíyan àwọn akọ ẹṣinmú gbogbo ilẹ̀ wárìrì.Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run,gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀. 17 “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín,paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn,yóò sì bù yín jẹ,”ni OLÚWA wí. 18 Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi,rẹ̀wẹ̀sì nínú mi. 19 Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn miláti ilẹ̀ jíjìnnà wá:“OLÚWA kò ha sí ní Sioni bí?Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?” “Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn,pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?” 20 “Ìkórè ti rékọjá,ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí,síbẹ̀ a kò gbà wá là.” 21 Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú,èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká. 22 Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí?Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀?Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsànfún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?
In Other Versions
Jeremiah 8 in the ANGEFD
Jeremiah 8 in the ANTPNG2D
Jeremiah 8 in the AS21
Jeremiah 8 in the BAGH
Jeremiah 8 in the BBPNG
Jeremiah 8 in the BBT1E
Jeremiah 8 in the BDS
Jeremiah 8 in the BEV
Jeremiah 8 in the BHAD
Jeremiah 8 in the BIB
Jeremiah 8 in the BLPT
Jeremiah 8 in the BNT
Jeremiah 8 in the BNTABOOT
Jeremiah 8 in the BNTLV
Jeremiah 8 in the BOATCB
Jeremiah 8 in the BOATCB2
Jeremiah 8 in the BOBCV
Jeremiah 8 in the BOCNT
Jeremiah 8 in the BOECS
Jeremiah 8 in the BOGWICC
Jeremiah 8 in the BOHCB
Jeremiah 8 in the BOHCV
Jeremiah 8 in the BOHLNT
Jeremiah 8 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 8 in the BOICB
Jeremiah 8 in the BOILNTAP
Jeremiah 8 in the BOITCV
Jeremiah 8 in the BOKCV
Jeremiah 8 in the BOKCV2
Jeremiah 8 in the BOKHWOG
Jeremiah 8 in the BOKSSV
Jeremiah 8 in the BOLCB
Jeremiah 8 in the BOLCB2
Jeremiah 8 in the BOMCV
Jeremiah 8 in the BONAV
Jeremiah 8 in the BONCB
Jeremiah 8 in the BONLT
Jeremiah 8 in the BONUT2
Jeremiah 8 in the BOPLNT
Jeremiah 8 in the BOSCB
Jeremiah 8 in the BOSNC
Jeremiah 8 in the BOTLNT
Jeremiah 8 in the BOVCB
Jeremiah 8 in the BPBB
Jeremiah 8 in the BPH
Jeremiah 8 in the BSB
Jeremiah 8 in the CCB
Jeremiah 8 in the CUV
Jeremiah 8 in the CUVS
Jeremiah 8 in the DBT
Jeremiah 8 in the DGDNT
Jeremiah 8 in the DHNT
Jeremiah 8 in the DNT
Jeremiah 8 in the ELBE
Jeremiah 8 in the EMTV
Jeremiah 8 in the ESV
Jeremiah 8 in the FBV
Jeremiah 8 in the FEB
Jeremiah 8 in the GGMNT
Jeremiah 8 in the GNT
Jeremiah 8 in the HARY
Jeremiah 8 in the HNT
Jeremiah 8 in the IRVA
Jeremiah 8 in the IRVB
Jeremiah 8 in the IRVG
Jeremiah 8 in the IRVH
Jeremiah 8 in the IRVK
Jeremiah 8 in the IRVM
Jeremiah 8 in the IRVM2
Jeremiah 8 in the IRVO
Jeremiah 8 in the IRVP
Jeremiah 8 in the IRVT
Jeremiah 8 in the IRVT2
Jeremiah 8 in the IRVU
Jeremiah 8 in the ISVN
Jeremiah 8 in the JSNT
Jeremiah 8 in the KAPI
Jeremiah 8 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 8 in the KBV
Jeremiah 8 in the KJV
Jeremiah 8 in the KNFD
Jeremiah 8 in the LBA
Jeremiah 8 in the LBLA
Jeremiah 8 in the LNT
Jeremiah 8 in the LSV
Jeremiah 8 in the MAAL
Jeremiah 8 in the MBV
Jeremiah 8 in the MBV2
Jeremiah 8 in the MHNT
Jeremiah 8 in the MKNFD
Jeremiah 8 in the MNG
Jeremiah 8 in the MNT
Jeremiah 8 in the MNT2
Jeremiah 8 in the MRS1T
Jeremiah 8 in the NAA
Jeremiah 8 in the NASB
Jeremiah 8 in the NBLA
Jeremiah 8 in the NBS
Jeremiah 8 in the NBVTP
Jeremiah 8 in the NET2
Jeremiah 8 in the NIV11
Jeremiah 8 in the NNT
Jeremiah 8 in the NNT2
Jeremiah 8 in the NNT3
Jeremiah 8 in the PDDPT
Jeremiah 8 in the PFNT
Jeremiah 8 in the RMNT
Jeremiah 8 in the SBIAS
Jeremiah 8 in the SBIBS
Jeremiah 8 in the SBIBS2
Jeremiah 8 in the SBICS
Jeremiah 8 in the SBIDS
Jeremiah 8 in the SBIGS
Jeremiah 8 in the SBIHS
Jeremiah 8 in the SBIIS
Jeremiah 8 in the SBIIS2
Jeremiah 8 in the SBIIS3
Jeremiah 8 in the SBIKS
Jeremiah 8 in the SBIKS2
Jeremiah 8 in the SBIMS
Jeremiah 8 in the SBIOS
Jeremiah 8 in the SBIPS
Jeremiah 8 in the SBISS
Jeremiah 8 in the SBITS
Jeremiah 8 in the SBITS2
Jeremiah 8 in the SBITS3
Jeremiah 8 in the SBITS4
Jeremiah 8 in the SBIUS
Jeremiah 8 in the SBIVS
Jeremiah 8 in the SBT
Jeremiah 8 in the SBT1E
Jeremiah 8 in the SCHL
Jeremiah 8 in the SNT
Jeremiah 8 in the SUSU
Jeremiah 8 in the SUSU2
Jeremiah 8 in the SYNO
Jeremiah 8 in the TBIAOTANT
Jeremiah 8 in the TBT1E
Jeremiah 8 in the TBT1E2
Jeremiah 8 in the TFTIP
Jeremiah 8 in the TFTU
Jeremiah 8 in the TGNTATF3T
Jeremiah 8 in the THAI
Jeremiah 8 in the TNFD
Jeremiah 8 in the TNT
Jeremiah 8 in the TNTIK
Jeremiah 8 in the TNTIL
Jeremiah 8 in the TNTIN
Jeremiah 8 in the TNTIP
Jeremiah 8 in the TNTIZ
Jeremiah 8 in the TOMA
Jeremiah 8 in the TTENT
Jeremiah 8 in the UBG
Jeremiah 8 in the UGV
Jeremiah 8 in the UGV2
Jeremiah 8 in the UGV3
Jeremiah 8 in the VBL
Jeremiah 8 in the VDCC
Jeremiah 8 in the YALU
Jeremiah 8 in the YAPE
Jeremiah 8 in the YBVTP
Jeremiah 8 in the ZBP