John 17 (BOYCB)

1 Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé, “Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú. 2 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní àṣẹ lórí ènìyàn gbogbo, kí ó lè fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó fi fún un. 3 Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán. 4 Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé: èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe. 5 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Baba, ṣe mí lógo pẹ̀lú ara rẹ, ògo tí mo ti ní pẹ̀lú rẹ kí ayé kí ó tó wà. 6 “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá, tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. 7 Nísinsin yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni. 8 Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi. 9 Èmi ń gbàdúrà fún wọn, èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n í ṣe. 10 Tìrẹ sá à ni gbogbo ohun tí í ṣe tèmi, àti tèmi sì ni gbogbo ohun tí í ṣe tìrẹ, a sì ti ṣe mí lógo nínú wọn. 11 Èmi kò sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa. 12 Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ. 13 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn. 14 Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. 15 Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi. 16 Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. 17 Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. 18 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú. 19 Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́. 20 “Kì sì í ṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ń gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yóò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn. 21 Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa, kí ayé kí ó lè gbàgbọ́ pé, ìwọ ni ó rán mi. 22 Ògo tí ìwọ ti fi fún mi ni èmi sì ti fi fún wọn; kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan. 23 Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan; kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi. 24 “Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi, nítorí ìwọ sá à fẹ́ràn mi síwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. 25 “Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́n; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi. 26 Mo ti sọ orúkọ rẹ di mí mọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mí mọ̀: kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn, àti èmi nínú wọn.”

In Other Versions

John 17 in the ANGEFD

John 17 in the ANTPNG2D

John 17 in the AS21

John 17 in the BAGH

John 17 in the BBPNG

John 17 in the BBT1E

John 17 in the BDS

John 17 in the BEV

John 17 in the BHAD

John 17 in the BIB

John 17 in the BLPT

John 17 in the BNT

John 17 in the BNTABOOT

John 17 in the BNTLV

John 17 in the BOATCB

John 17 in the BOATCB2

John 17 in the BOBCV

John 17 in the BOCNT

John 17 in the BOECS

John 17 in the BOGWICC

John 17 in the BOHCB

John 17 in the BOHCV

John 17 in the BOHLNT

John 17 in the BOHNTLTAL

John 17 in the BOICB

John 17 in the BOILNTAP

John 17 in the BOITCV

John 17 in the BOKCV

John 17 in the BOKCV2

John 17 in the BOKHWOG

John 17 in the BOKSSV

John 17 in the BOLCB

John 17 in the BOLCB2

John 17 in the BOMCV

John 17 in the BONAV

John 17 in the BONCB

John 17 in the BONLT

John 17 in the BONUT2

John 17 in the BOPLNT

John 17 in the BOSCB

John 17 in the BOSNC

John 17 in the BOTLNT

John 17 in the BOVCB

John 17 in the BPBB

John 17 in the BPH

John 17 in the BSB

John 17 in the CCB

John 17 in the CUV

John 17 in the CUVS

John 17 in the DBT

John 17 in the DGDNT

John 17 in the DHNT

John 17 in the DNT

John 17 in the ELBE

John 17 in the EMTV

John 17 in the ESV

John 17 in the FBV

John 17 in the FEB

John 17 in the GGMNT

John 17 in the GNT

John 17 in the HARY

John 17 in the HNT

John 17 in the IRVA

John 17 in the IRVB

John 17 in the IRVG

John 17 in the IRVH

John 17 in the IRVK

John 17 in the IRVM

John 17 in the IRVM2

John 17 in the IRVO

John 17 in the IRVP

John 17 in the IRVT

John 17 in the IRVT2

John 17 in the IRVU

John 17 in the ISVN

John 17 in the JSNT

John 17 in the KAPI

John 17 in the KBT1ETNIK

John 17 in the KBV

John 17 in the KJV

John 17 in the KNFD

John 17 in the LBA

John 17 in the LBLA

John 17 in the LNT

John 17 in the LSV

John 17 in the MAAL

John 17 in the MBV

John 17 in the MBV2

John 17 in the MHNT

John 17 in the MKNFD

John 17 in the MNG

John 17 in the MNT

John 17 in the MNT2

John 17 in the MRS1T

John 17 in the NAA

John 17 in the NASB

John 17 in the NBLA

John 17 in the NBS

John 17 in the NBVTP

John 17 in the NET2

John 17 in the NIV11

John 17 in the NNT

John 17 in the NNT2

John 17 in the NNT3

John 17 in the PDDPT

John 17 in the PFNT

John 17 in the RMNT

John 17 in the SBIAS

John 17 in the SBIBS

John 17 in the SBIBS2

John 17 in the SBICS

John 17 in the SBIDS

John 17 in the SBIGS

John 17 in the SBIHS

John 17 in the SBIIS

John 17 in the SBIIS2

John 17 in the SBIIS3

John 17 in the SBIKS

John 17 in the SBIKS2

John 17 in the SBIMS

John 17 in the SBIOS

John 17 in the SBIPS

John 17 in the SBISS

John 17 in the SBITS

John 17 in the SBITS2

John 17 in the SBITS3

John 17 in the SBITS4

John 17 in the SBIUS

John 17 in the SBIVS

John 17 in the SBT

John 17 in the SBT1E

John 17 in the SCHL

John 17 in the SNT

John 17 in the SUSU

John 17 in the SUSU2

John 17 in the SYNO

John 17 in the TBIAOTANT

John 17 in the TBT1E

John 17 in the TBT1E2

John 17 in the TFTIP

John 17 in the TFTU

John 17 in the TGNTATF3T

John 17 in the THAI

John 17 in the TNFD

John 17 in the TNT

John 17 in the TNTIK

John 17 in the TNTIL

John 17 in the TNTIN

John 17 in the TNTIP

John 17 in the TNTIZ

John 17 in the TOMA

John 17 in the TTENT

John 17 in the UBG

John 17 in the UGV

John 17 in the UGV2

John 17 in the UGV3

John 17 in the VBL

John 17 in the VDCC

John 17 in the YALU

John 17 in the YAPE

John 17 in the YBVTP

John 17 in the ZBP