Matthew 22 (BOYCB)

1 Jesu tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé: 2 “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àsè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. 3 Ó rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ pe àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ sí ibi àsè ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ wá. 4 “Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti ṣe àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyàwó.’ 5 “Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kà á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.” 6 Àwọn ìyókù sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àbùkù sí wọn, wọ́n lù wọ́n pa. 7 Ọba yìí bínú gidigidi, ó sì rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn apànìyàn náà run, ó sì jó ìlú wọn. 8 “Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó ti ṣe tàn, ṣùgbọ́n àwọn tí a pè kò yẹ fún ọlá náà. 9 Ẹ lọ sí ìgboro àti òpópónà kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè rí wá àsè ìgbéyàwó náà.’ 10 Nítorí náà, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì jáde lọ sí òpópónà. Wọ́n sì mú oríṣìíríṣìí ènìyàn tí wọ́n lè rí wá, àwọn tí ò dára àti àwọn tí kò dára, ilé àsè ìyàwó sì kún fún àlejò. 11 “Ṣùgbọ́n nígbà tí ọba sì wọlé wá láti wo àwọn àlejò tí a pè, ó sì rí ọkùnrin kan nínú wọn tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. 12 Ọba sì bi í pé, ‘Ọ̀rẹ́, báwo ni ìwọ ṣe wà níhìn-ín yìí láìní aṣọ ìgbéyàwó?’ Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kò ní ìdáhùn kankan. 13 “Nígbà náà ni ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì sọ ọ́ sínú òkùnkùn lóde níbi tí ẹkún àti ìpayínkeke wà.’ 14 “Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.” 15 Nígbà náà ni àwọn Farisi péjọpọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un. 16 Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olóòtítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 17 Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?” 18 Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò? 19 Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un, 20 ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?” 21 Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.” “Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” 22 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ. 23 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusi tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jesu wá láti bi í ní ìbéèrè, 24 wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mose wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un. 25 Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrín wa níhìn-ín yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú ní àìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì. 26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ. A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e. Bẹ́ẹ̀ sì ni títí tí òun fi di ìyàwó ẹni keje. 27 Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú. 28 Nítorí tí ó ti ṣe ìyàwó àwọn arákùnrin méjèèje, ìyàwó ta ni yóò jẹ́ ní àjíǹde òkú?” 29 Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ Ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run. 30 Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn angẹli ní ọ̀run. 31 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé: 32 ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.” 33 Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ. 34 Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, àwọn Farisi pé ara wọn jọ. 35 Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí. 36 Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?” 37 Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’ 38 Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ. 39 Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ 40 Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.” 41 Bí àwọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, 42 “Kí ni ẹ rò nípa Kristi? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?”Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dafidi.” 43 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí lo dé tí Dafidi, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé, 44 “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’ 45 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?” 46 Kò sí ẹnìkan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́.

In Other Versions

Matthew 22 in the ANGEFD

Matthew 22 in the ANTPNG2D

Matthew 22 in the AS21

Matthew 22 in the BAGH

Matthew 22 in the BBPNG

Matthew 22 in the BBT1E

Matthew 22 in the BDS

Matthew 22 in the BEV

Matthew 22 in the BHAD

Matthew 22 in the BIB

Matthew 22 in the BLPT

Matthew 22 in the BNT

Matthew 22 in the BNTABOOT

Matthew 22 in the BNTLV

Matthew 22 in the BOATCB

Matthew 22 in the BOATCB2

Matthew 22 in the BOBCV

Matthew 22 in the BOCNT

Matthew 22 in the BOECS

Matthew 22 in the BOGWICC

Matthew 22 in the BOHCB

Matthew 22 in the BOHCV

Matthew 22 in the BOHLNT

Matthew 22 in the BOHNTLTAL

Matthew 22 in the BOICB

Matthew 22 in the BOILNTAP

Matthew 22 in the BOITCV

Matthew 22 in the BOKCV

Matthew 22 in the BOKCV2

Matthew 22 in the BOKHWOG

Matthew 22 in the BOKSSV

Matthew 22 in the BOLCB

Matthew 22 in the BOLCB2

Matthew 22 in the BOMCV

Matthew 22 in the BONAV

Matthew 22 in the BONCB

Matthew 22 in the BONLT

Matthew 22 in the BONUT2

Matthew 22 in the BOPLNT

Matthew 22 in the BOSCB

Matthew 22 in the BOSNC

Matthew 22 in the BOTLNT

Matthew 22 in the BOVCB

Matthew 22 in the BPBB

Matthew 22 in the BPH

Matthew 22 in the BSB

Matthew 22 in the CCB

Matthew 22 in the CUV

Matthew 22 in the CUVS

Matthew 22 in the DBT

Matthew 22 in the DGDNT

Matthew 22 in the DHNT

Matthew 22 in the DNT

Matthew 22 in the ELBE

Matthew 22 in the EMTV

Matthew 22 in the ESV

Matthew 22 in the FBV

Matthew 22 in the FEB

Matthew 22 in the GGMNT

Matthew 22 in the GNT

Matthew 22 in the HARY

Matthew 22 in the HNT

Matthew 22 in the IRVA

Matthew 22 in the IRVB

Matthew 22 in the IRVG

Matthew 22 in the IRVH

Matthew 22 in the IRVK

Matthew 22 in the IRVM

Matthew 22 in the IRVM2

Matthew 22 in the IRVO

Matthew 22 in the IRVP

Matthew 22 in the IRVT

Matthew 22 in the IRVT2

Matthew 22 in the IRVU

Matthew 22 in the ISVN

Matthew 22 in the JSNT

Matthew 22 in the KAPI

Matthew 22 in the KBT1ETNIK

Matthew 22 in the KBV

Matthew 22 in the KJV

Matthew 22 in the KNFD

Matthew 22 in the LBA

Matthew 22 in the LBLA

Matthew 22 in the LNT

Matthew 22 in the LSV

Matthew 22 in the MAAL

Matthew 22 in the MBV

Matthew 22 in the MBV2

Matthew 22 in the MHNT

Matthew 22 in the MKNFD

Matthew 22 in the MNG

Matthew 22 in the MNT

Matthew 22 in the MNT2

Matthew 22 in the MRS1T

Matthew 22 in the NAA

Matthew 22 in the NASB

Matthew 22 in the NBLA

Matthew 22 in the NBS

Matthew 22 in the NBVTP

Matthew 22 in the NET2

Matthew 22 in the NIV11

Matthew 22 in the NNT

Matthew 22 in the NNT2

Matthew 22 in the NNT3

Matthew 22 in the PDDPT

Matthew 22 in the PFNT

Matthew 22 in the RMNT

Matthew 22 in the SBIAS

Matthew 22 in the SBIBS

Matthew 22 in the SBIBS2

Matthew 22 in the SBICS

Matthew 22 in the SBIDS

Matthew 22 in the SBIGS

Matthew 22 in the SBIHS

Matthew 22 in the SBIIS

Matthew 22 in the SBIIS2

Matthew 22 in the SBIIS3

Matthew 22 in the SBIKS

Matthew 22 in the SBIKS2

Matthew 22 in the SBIMS

Matthew 22 in the SBIOS

Matthew 22 in the SBIPS

Matthew 22 in the SBISS

Matthew 22 in the SBITS

Matthew 22 in the SBITS2

Matthew 22 in the SBITS3

Matthew 22 in the SBITS4

Matthew 22 in the SBIUS

Matthew 22 in the SBIVS

Matthew 22 in the SBT

Matthew 22 in the SBT1E

Matthew 22 in the SCHL

Matthew 22 in the SNT

Matthew 22 in the SUSU

Matthew 22 in the SUSU2

Matthew 22 in the SYNO

Matthew 22 in the TBIAOTANT

Matthew 22 in the TBT1E

Matthew 22 in the TBT1E2

Matthew 22 in the TFTIP

Matthew 22 in the TFTU

Matthew 22 in the TGNTATF3T

Matthew 22 in the THAI

Matthew 22 in the TNFD

Matthew 22 in the TNT

Matthew 22 in the TNTIK

Matthew 22 in the TNTIL

Matthew 22 in the TNTIN

Matthew 22 in the TNTIP

Matthew 22 in the TNTIZ

Matthew 22 in the TOMA

Matthew 22 in the TTENT

Matthew 22 in the UBG

Matthew 22 in the UGV

Matthew 22 in the UGV2

Matthew 22 in the UGV3

Matthew 22 in the VBL

Matthew 22 in the VDCC

Matthew 22 in the YALU

Matthew 22 in the YAPE

Matthew 22 in the YBVTP

Matthew 22 in the ZBP