Psalms 68 (BOYCB)
undefined Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin. 1 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀. 2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,kí ó fẹ́ wọn lọ;bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run. 3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùnkí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀. 4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,ẹ kọrin ìyìn sí i,ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù. OLÚWA ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀. 5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbérẹ̀ mímọ́ 6 Ọlọ́run gbé aláìlerakalẹ̀ nínú ìdílé,ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ. 7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela. 8 Ilẹ̀ mì títí,àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,níwájú Ọlọ́run,ẹni Sinai,níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli. 9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan. 10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní. 11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀. 12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà. 13 Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.” 14 Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,ó dàbí òjò dídi ní Salmoni. 15 Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani. 16 Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọbaníbi tí OLÚWA fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé? 17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́runẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀. 18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gígaìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,kí OLÚWA Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé. 19 Olùbùkún ni OLÚWA,Ọlọ́run Olùgbàlà wa,ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela. 20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlààti sí OLÚWA Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú. 21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn 22 Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun, 23 kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.” 24 Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀. 25 Àwọn akọrin wà ní iwájú, àwọn olórin wà lẹ́yìn;àwọn ọmọbìnrin tí ń lu ṣaworo sì wà pẹ̀lú wọn. 26 Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA ní ẹgbẹgbẹ́;àní fún OLÚWA ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá. 27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali. 28 Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú. 29 Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmuàwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ. 30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,tí ń gbé láàrín eèsúnọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúùpẹ̀lú àwọn ọmọ màlúùtítí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká. 31 Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run. 32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,kọrin ìyìn sí OLÚWA, Sela. 33 Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá. 34 Kéde agbára Ọlọ́run,ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run. 35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ. Olùbùkún ní Ọlọ́run!
In Other Versions
Psalms 68 in the ANGEFD
Psalms 68 in the ANTPNG2D
Psalms 68 in the AS21
Psalms 68 in the BAGH
Psalms 68 in the BBPNG
Psalms 68 in the BBT1E
Psalms 68 in the BDS
Psalms 68 in the BEV
Psalms 68 in the BHAD
Psalms 68 in the BIB
Psalms 68 in the BLPT
Psalms 68 in the BNT
Psalms 68 in the BNTABOOT
Psalms 68 in the BNTLV
Psalms 68 in the BOATCB
Psalms 68 in the BOATCB2
Psalms 68 in the BOBCV
Psalms 68 in the BOCNT
Psalms 68 in the BOECS
Psalms 68 in the BOGWICC
Psalms 68 in the BOHCB
Psalms 68 in the BOHCV
Psalms 68 in the BOHLNT
Psalms 68 in the BOHNTLTAL
Psalms 68 in the BOICB
Psalms 68 in the BOILNTAP
Psalms 68 in the BOITCV
Psalms 68 in the BOKCV
Psalms 68 in the BOKCV2
Psalms 68 in the BOKHWOG
Psalms 68 in the BOKSSV
Psalms 68 in the BOLCB
Psalms 68 in the BOLCB2
Psalms 68 in the BOMCV
Psalms 68 in the BONAV
Psalms 68 in the BONCB
Psalms 68 in the BONLT
Psalms 68 in the BONUT2
Psalms 68 in the BOPLNT
Psalms 68 in the BOSCB
Psalms 68 in the BOSNC
Psalms 68 in the BOTLNT
Psalms 68 in the BOVCB
Psalms 68 in the BPBB
Psalms 68 in the BPH
Psalms 68 in the BSB
Psalms 68 in the CCB
Psalms 68 in the CUV
Psalms 68 in the CUVS
Psalms 68 in the DBT
Psalms 68 in the DGDNT
Psalms 68 in the DHNT
Psalms 68 in the DNT
Psalms 68 in the ELBE
Psalms 68 in the EMTV
Psalms 68 in the ESV
Psalms 68 in the FBV
Psalms 68 in the FEB
Psalms 68 in the GGMNT
Psalms 68 in the GNT
Psalms 68 in the HARY
Psalms 68 in the HNT
Psalms 68 in the IRVA
Psalms 68 in the IRVB
Psalms 68 in the IRVG
Psalms 68 in the IRVH
Psalms 68 in the IRVK
Psalms 68 in the IRVM
Psalms 68 in the IRVM2
Psalms 68 in the IRVO
Psalms 68 in the IRVP
Psalms 68 in the IRVT
Psalms 68 in the IRVT2
Psalms 68 in the IRVU
Psalms 68 in the ISVN
Psalms 68 in the JSNT
Psalms 68 in the KAPI
Psalms 68 in the KBT1ETNIK
Psalms 68 in the KBV
Psalms 68 in the KJV
Psalms 68 in the KNFD
Psalms 68 in the LBA
Psalms 68 in the LBLA
Psalms 68 in the LNT
Psalms 68 in the LSV
Psalms 68 in the MAAL
Psalms 68 in the MBV
Psalms 68 in the MBV2
Psalms 68 in the MHNT
Psalms 68 in the MKNFD
Psalms 68 in the MNG
Psalms 68 in the MNT
Psalms 68 in the MNT2
Psalms 68 in the MRS1T
Psalms 68 in the NAA
Psalms 68 in the NASB
Psalms 68 in the NBLA
Psalms 68 in the NBS
Psalms 68 in the NBVTP
Psalms 68 in the NET2
Psalms 68 in the NIV11
Psalms 68 in the NNT
Psalms 68 in the NNT2
Psalms 68 in the NNT3
Psalms 68 in the PDDPT
Psalms 68 in the PFNT
Psalms 68 in the RMNT
Psalms 68 in the SBIAS
Psalms 68 in the SBIBS
Psalms 68 in the SBIBS2
Psalms 68 in the SBICS
Psalms 68 in the SBIDS
Psalms 68 in the SBIGS
Psalms 68 in the SBIHS
Psalms 68 in the SBIIS
Psalms 68 in the SBIIS2
Psalms 68 in the SBIIS3
Psalms 68 in the SBIKS
Psalms 68 in the SBIKS2
Psalms 68 in the SBIMS
Psalms 68 in the SBIOS
Psalms 68 in the SBIPS
Psalms 68 in the SBISS
Psalms 68 in the SBITS
Psalms 68 in the SBITS2
Psalms 68 in the SBITS3
Psalms 68 in the SBITS4
Psalms 68 in the SBIUS
Psalms 68 in the SBIVS
Psalms 68 in the SBT
Psalms 68 in the SBT1E
Psalms 68 in the SCHL
Psalms 68 in the SNT
Psalms 68 in the SUSU
Psalms 68 in the SUSU2
Psalms 68 in the SYNO
Psalms 68 in the TBIAOTANT
Psalms 68 in the TBT1E
Psalms 68 in the TBT1E2
Psalms 68 in the TFTIP
Psalms 68 in the TFTU
Psalms 68 in the TGNTATF3T
Psalms 68 in the THAI
Psalms 68 in the TNFD
Psalms 68 in the TNT
Psalms 68 in the TNTIK
Psalms 68 in the TNTIL
Psalms 68 in the TNTIN
Psalms 68 in the TNTIP
Psalms 68 in the TNTIZ
Psalms 68 in the TOMA
Psalms 68 in the TTENT
Psalms 68 in the UBG
Psalms 68 in the UGV
Psalms 68 in the UGV2
Psalms 68 in the UGV3
Psalms 68 in the VBL
Psalms 68 in the VDCC
Psalms 68 in the YALU
Psalms 68 in the YAPE
Psalms 68 in the YBVTP
Psalms 68 in the ZBP