Romans 6 (BOYCB)
1 Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí? Ṣé kí àwa ó jókòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i? 2 Kí a má ri! Àwa ẹni tí ó ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, àwa ó ha ṣe wà láààyè nínú rẹ̀ mọ́? 3 Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. 4 Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun. 5 Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. 6 Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 7 Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́. 8 Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. 9 Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́. 10 Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. 11 Nítorí náà, ẹ ka ara yín bí òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n bí alààyè sí Ọlọ́run nínú Kristi Jesu. 12 Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 13 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ohun búburú, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ fi wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára. 14 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́. 15 Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsin yìí, a lè tẹ̀síwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láìbìkítà, nítorí ìgbàlà wa kò dúró nípa òfin mọ́, bí kò ṣe nípa gbígba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run! 16 Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ ti o yọrí si ikú tàbí ìgbọ́ràn ti o yọrí sí ìdáláre. Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fi ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀. 17 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ rí, ẹ̀yin jẹ́ olùgbọ́ran láti ọkàn wá sí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́. 18 Nísinsin yìí, ẹ ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo. 19 Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn nítorí àìlera yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yín ti jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ bí ẹrú fún ìwà èérí àti ẹ̀ṣẹ̀ dé inú ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin kí ó jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ nísinsin yìí bí ẹrú fún òdodo sí ìwà mímọ́. 20 Nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin wà ní òmìnira sí òdodo. 21 Àti pé, kín ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ́n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsin yìí láti ronú nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń ṣe nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé. 22 Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun. 23 Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi Jesu Olúwa wa.
In Other Versions
Romans 6 in the ANGEFD
Romans 6 in the ANTPNG2D
Romans 6 in the AS21
Romans 6 in the BAGH
Romans 6 in the BBPNG
Romans 6 in the BBT1E
Romans 6 in the BDS
Romans 6 in the BEV
Romans 6 in the BHAD
Romans 6 in the BIB
Romans 6 in the BLPT
Romans 6 in the BNT
Romans 6 in the BNTABOOT
Romans 6 in the BNTLV
Romans 6 in the BOATCB
Romans 6 in the BOATCB2
Romans 6 in the BOBCV
Romans 6 in the BOCNT
Romans 6 in the BOECS
Romans 6 in the BOGWICC
Romans 6 in the BOHCB
Romans 6 in the BOHCV
Romans 6 in the BOHLNT
Romans 6 in the BOHNTLTAL
Romans 6 in the BOICB
Romans 6 in the BOILNTAP
Romans 6 in the BOITCV
Romans 6 in the BOKCV
Romans 6 in the BOKCV2
Romans 6 in the BOKHWOG
Romans 6 in the BOKSSV
Romans 6 in the BOLCB
Romans 6 in the BOLCB2
Romans 6 in the BOMCV
Romans 6 in the BONAV
Romans 6 in the BONCB
Romans 6 in the BONLT
Romans 6 in the BONUT2
Romans 6 in the BOPLNT
Romans 6 in the BOSCB
Romans 6 in the BOSNC
Romans 6 in the BOTLNT
Romans 6 in the BOVCB
Romans 6 in the BPBB
Romans 6 in the BPH
Romans 6 in the BSB
Romans 6 in the CCB
Romans 6 in the CUV
Romans 6 in the CUVS
Romans 6 in the DBT
Romans 6 in the DGDNT
Romans 6 in the DHNT
Romans 6 in the DNT
Romans 6 in the ELBE
Romans 6 in the EMTV
Romans 6 in the ESV
Romans 6 in the FBV
Romans 6 in the FEB
Romans 6 in the GGMNT
Romans 6 in the GNT
Romans 6 in the HARY
Romans 6 in the HNT
Romans 6 in the IRVA
Romans 6 in the IRVB
Romans 6 in the IRVG
Romans 6 in the IRVH
Romans 6 in the IRVK
Romans 6 in the IRVM
Romans 6 in the IRVM2
Romans 6 in the IRVO
Romans 6 in the IRVP
Romans 6 in the IRVT
Romans 6 in the IRVT2
Romans 6 in the IRVU
Romans 6 in the ISVN
Romans 6 in the JSNT
Romans 6 in the KAPI
Romans 6 in the KBT1ETNIK
Romans 6 in the KBV
Romans 6 in the KJV
Romans 6 in the KNFD
Romans 6 in the LBA
Romans 6 in the LBLA
Romans 6 in the LNT
Romans 6 in the LSV
Romans 6 in the MAAL
Romans 6 in the MBV
Romans 6 in the MBV2
Romans 6 in the MHNT
Romans 6 in the MKNFD
Romans 6 in the MNG
Romans 6 in the MNT
Romans 6 in the MNT2
Romans 6 in the MRS1T
Romans 6 in the NAA
Romans 6 in the NASB
Romans 6 in the NBLA
Romans 6 in the NBS
Romans 6 in the NBVTP
Romans 6 in the NET2
Romans 6 in the NIV11
Romans 6 in the NNT
Romans 6 in the NNT2
Romans 6 in the NNT3
Romans 6 in the PDDPT
Romans 6 in the PFNT
Romans 6 in the RMNT
Romans 6 in the SBIAS
Romans 6 in the SBIBS
Romans 6 in the SBIBS2
Romans 6 in the SBICS
Romans 6 in the SBIDS
Romans 6 in the SBIGS
Romans 6 in the SBIHS
Romans 6 in the SBIIS
Romans 6 in the SBIIS2
Romans 6 in the SBIIS3
Romans 6 in the SBIKS
Romans 6 in the SBIKS2
Romans 6 in the SBIMS
Romans 6 in the SBIOS
Romans 6 in the SBIPS
Romans 6 in the SBISS
Romans 6 in the SBITS
Romans 6 in the SBITS2
Romans 6 in the SBITS3
Romans 6 in the SBITS4
Romans 6 in the SBIUS
Romans 6 in the SBIVS
Romans 6 in the SBT
Romans 6 in the SBT1E
Romans 6 in the SCHL
Romans 6 in the SNT
Romans 6 in the SUSU
Romans 6 in the SUSU2
Romans 6 in the SYNO
Romans 6 in the TBIAOTANT
Romans 6 in the TBT1E
Romans 6 in the TBT1E2
Romans 6 in the TFTIP
Romans 6 in the TFTU
Romans 6 in the TGNTATF3T
Romans 6 in the THAI
Romans 6 in the TNFD
Romans 6 in the TNT
Romans 6 in the TNTIK
Romans 6 in the TNTIL
Romans 6 in the TNTIN
Romans 6 in the TNTIP
Romans 6 in the TNTIZ
Romans 6 in the TOMA
Romans 6 in the TTENT
Romans 6 in the UBG
Romans 6 in the UGV
Romans 6 in the UGV2
Romans 6 in the UGV3
Romans 6 in the VBL
Romans 6 in the VDCC
Romans 6 in the YALU
Romans 6 in the YAPE
Romans 6 in the YBVTP
Romans 6 in the ZBP