Isaiah 22 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ìran.Kí ni ó ń dààmú yín báyìí,tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ? 2 Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàna kò fi idà pa àwọn òkú rẹ,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun. 3 Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà.Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wàlọ́nà jíjìn réré. 4 Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:jẹ́ kí n sọkún kíkorò.Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínúnítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.” 5 Olúwa, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kantí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ní àfonífojì ìmọ̀,ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè. 6 Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta. 7 Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú. 8 Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náàsí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù. 9 Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidiní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,ìwọ ti tọ́jú omisínú adágún ti ìsàlẹ̀. 10 Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmuó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára. 11 Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjìfún omi inú adágún àtijọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ógbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. 12 OLÚWA, àní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun,pè ọ́ ní ọjọ́ náàláti sọkún kí o sì pohùnréré,kí o tu irun rẹ dànù kí o sìda aṣọ ọ̀fọ̀ bora. 13 Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà;màlúù pípa àti àgùntàn pípa,ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,nítorí pé lọ́la àwa ó kú!” 14 OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. 15 Èyí ni ohun tí OLÚWA, àní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí,“Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. 16 Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti péta ni ó sì fún ọ ní àṣẹláti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí,tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gígatí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta? 17 “Kíyèsára, OLÚWA fẹ́ gbá ọ mú gírígíríkí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára. 18 Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtìyóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú síàti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogunàràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ! 19 Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ. 20 “Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah. 21 Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda. 22 Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí. 23 Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀. 24 Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí. 25 “Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” OLÚWA ni ó ti sọ ọ́.
In Other Versions
Isaiah 22 in the ANGEFD
Isaiah 22 in the ANTPNG2D
Isaiah 22 in the AS21
Isaiah 22 in the BAGH
Isaiah 22 in the BBPNG
Isaiah 22 in the BBT1E
Isaiah 22 in the BDS
Isaiah 22 in the BEV
Isaiah 22 in the BHAD
Isaiah 22 in the BIB
Isaiah 22 in the BLPT
Isaiah 22 in the BNT
Isaiah 22 in the BNTABOOT
Isaiah 22 in the BNTLV
Isaiah 22 in the BOATCB
Isaiah 22 in the BOATCB2
Isaiah 22 in the BOBCV
Isaiah 22 in the BOCNT
Isaiah 22 in the BOECS
Isaiah 22 in the BOGWICC
Isaiah 22 in the BOHCB
Isaiah 22 in the BOHCV
Isaiah 22 in the BOHLNT
Isaiah 22 in the BOHNTLTAL
Isaiah 22 in the BOICB
Isaiah 22 in the BOILNTAP
Isaiah 22 in the BOITCV
Isaiah 22 in the BOKCV
Isaiah 22 in the BOKCV2
Isaiah 22 in the BOKHWOG
Isaiah 22 in the BOKSSV
Isaiah 22 in the BOLCB
Isaiah 22 in the BOLCB2
Isaiah 22 in the BOMCV
Isaiah 22 in the BONAV
Isaiah 22 in the BONCB
Isaiah 22 in the BONLT
Isaiah 22 in the BONUT2
Isaiah 22 in the BOPLNT
Isaiah 22 in the BOSCB
Isaiah 22 in the BOSNC
Isaiah 22 in the BOTLNT
Isaiah 22 in the BOVCB
Isaiah 22 in the BPBB
Isaiah 22 in the BPH
Isaiah 22 in the BSB
Isaiah 22 in the CCB
Isaiah 22 in the CUV
Isaiah 22 in the CUVS
Isaiah 22 in the DBT
Isaiah 22 in the DGDNT
Isaiah 22 in the DHNT
Isaiah 22 in the DNT
Isaiah 22 in the ELBE
Isaiah 22 in the EMTV
Isaiah 22 in the ESV
Isaiah 22 in the FBV
Isaiah 22 in the FEB
Isaiah 22 in the GGMNT
Isaiah 22 in the GNT
Isaiah 22 in the HARY
Isaiah 22 in the HNT
Isaiah 22 in the IRVA
Isaiah 22 in the IRVB
Isaiah 22 in the IRVG
Isaiah 22 in the IRVH
Isaiah 22 in the IRVK
Isaiah 22 in the IRVM
Isaiah 22 in the IRVM2
Isaiah 22 in the IRVO
Isaiah 22 in the IRVP
Isaiah 22 in the IRVT
Isaiah 22 in the IRVT2
Isaiah 22 in the IRVU
Isaiah 22 in the ISVN
Isaiah 22 in the JSNT
Isaiah 22 in the KAPI
Isaiah 22 in the KBT1ETNIK
Isaiah 22 in the KBV
Isaiah 22 in the KJV
Isaiah 22 in the KNFD
Isaiah 22 in the LBA
Isaiah 22 in the LBLA
Isaiah 22 in the LNT
Isaiah 22 in the LSV
Isaiah 22 in the MAAL
Isaiah 22 in the MBV
Isaiah 22 in the MBV2
Isaiah 22 in the MHNT
Isaiah 22 in the MKNFD
Isaiah 22 in the MNG
Isaiah 22 in the MNT
Isaiah 22 in the MNT2
Isaiah 22 in the MRS1T
Isaiah 22 in the NAA
Isaiah 22 in the NASB
Isaiah 22 in the NBLA
Isaiah 22 in the NBS
Isaiah 22 in the NBVTP
Isaiah 22 in the NET2
Isaiah 22 in the NIV11
Isaiah 22 in the NNT
Isaiah 22 in the NNT2
Isaiah 22 in the NNT3
Isaiah 22 in the PDDPT
Isaiah 22 in the PFNT
Isaiah 22 in the RMNT
Isaiah 22 in the SBIAS
Isaiah 22 in the SBIBS
Isaiah 22 in the SBIBS2
Isaiah 22 in the SBICS
Isaiah 22 in the SBIDS
Isaiah 22 in the SBIGS
Isaiah 22 in the SBIHS
Isaiah 22 in the SBIIS
Isaiah 22 in the SBIIS2
Isaiah 22 in the SBIIS3
Isaiah 22 in the SBIKS
Isaiah 22 in the SBIKS2
Isaiah 22 in the SBIMS
Isaiah 22 in the SBIOS
Isaiah 22 in the SBIPS
Isaiah 22 in the SBISS
Isaiah 22 in the SBITS
Isaiah 22 in the SBITS2
Isaiah 22 in the SBITS3
Isaiah 22 in the SBITS4
Isaiah 22 in the SBIUS
Isaiah 22 in the SBIVS
Isaiah 22 in the SBT
Isaiah 22 in the SBT1E
Isaiah 22 in the SCHL
Isaiah 22 in the SNT
Isaiah 22 in the SUSU
Isaiah 22 in the SUSU2
Isaiah 22 in the SYNO
Isaiah 22 in the TBIAOTANT
Isaiah 22 in the TBT1E
Isaiah 22 in the TBT1E2
Isaiah 22 in the TFTIP
Isaiah 22 in the TFTU
Isaiah 22 in the TGNTATF3T
Isaiah 22 in the THAI
Isaiah 22 in the TNFD
Isaiah 22 in the TNT
Isaiah 22 in the TNTIK
Isaiah 22 in the TNTIL
Isaiah 22 in the TNTIN
Isaiah 22 in the TNTIP
Isaiah 22 in the TNTIZ
Isaiah 22 in the TOMA
Isaiah 22 in the TTENT
Isaiah 22 in the UBG
Isaiah 22 in the UGV
Isaiah 22 in the UGV2
Isaiah 22 in the UGV3
Isaiah 22 in the VBL
Isaiah 22 in the VDCC
Isaiah 22 in the YALU
Isaiah 22 in the YAPE
Isaiah 22 in the YBVTP
Isaiah 22 in the ZBP